ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 6A
“Fá Orí Rẹ àti Irùngbọ̀n Rẹ”
Bíi Ti Orí Ìwé
	Ìsíkíẹ́lì ṣe àṣefihàn àwọn ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù
- ‘Fá Orí àti Irùngbọ̀n’ - Wọ́n máa gbógun ti àwọn Júù, wọ́n sì máa pa wọ́n rẹ́ 
- ‘Wọ̀n Ọ́n, Kí O sì Pín In’ - Ọlọ́run máa dìídì mú ìdájọ́ náà wá, ó sì máa délé dóko 
- ‘Sun Ún’ - Àwọn kan máa kú sínú ìlú náà 
- ‘Fi Idà Gé E’ - Wọ́n máa pa àwọn kan káàkiri ẹ̀yin odi ìlú náà 
- ‘Fọ́n Ọn Ká’ - Àwọn kan máa yè bọ́, àmọ́ ọkàn wọn ò ní balẹ̀ 
- “Wé E Mọ́ Aṣọ” - Àwọn kan máa pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti ìgbèkùn, ìjọsìn mímọ́ ò sì ní pa run