ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 9Ẹ
‘Àkókò Ìmúbọ̀sípò Ohun Gbogbo’
ÌṢE 3:21
Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ‘àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo,’ ṣe ló ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò gígùn kan tó máa bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí Kristi bá di Ọba títí dé ìparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.
- 1914—Jésù Kristi di Ọba ní ọ̀run. Àwọn èèyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí lọ́dún 1919 - Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn 
- AMÁGẸ́DỌ́NÌ—Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bẹ̀rẹ̀, ‘àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ sì tún máa mú kí àwọn olóòótọ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé gbádùn àwọn ìbùkún tara - Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso 
- ẸGBẸ̀RÚN ỌDÚN ÌṢÀKÓSO KRISTI PARÍ—Jésù parí iṣẹ́ rẹ̀ láti mú kí gbogbo nǹkan pa dà bọ̀ sípò, ó sì dá Ìjọba náà pa dà fún Bàbá rẹ̀ - Párádísè Títí Ayé 
ÌṢÀKÓSO JÉSÙ MÁA MÚ KÍ . . .
- orúkọ Ọlọ́run pa dà di ológo 
- ara àwọn aláìsàn yá 
- àwọn arúgbó pa dà di ọ̀dọ́ 
- àwọn òkú jíǹde 
- àwọn olóòótọ́ èèyàn pa dà di ẹni pípé 
- ayé pa dà di Párádísè