ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • scl ojú ìwé 57-58
  • Ìjákulẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjákulẹ̀
  • Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́
scl ojú ìwé 57-58

Ìjákulẹ̀

Táwọn èèyàn bá já wa kulẹ̀, tí wọ́n ṣe ohun tó dùn wá tàbí tí wọ́n dalẹ̀ wa

Sm 55:12-14; Lk 22:21, 48

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • 1Sa 8:1-6—Inú wòlíì Sámúẹ́lì bà jẹ́ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé ó gbọ́dọ̀ yan ọba fáwọn

    • 1Sa 20:30-34—Inú Jónátánì bà jẹ́ nígbà tí Ọba Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ bàbá rẹ̀ bínú sí i, tó sì kàn án lábùkù

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:

    • Sm 27:10; Ais 49:15; Ro 3:3, 4

    • Tún wo Owe 19:11; Flp 4:8

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:

    • Sm 55:12-14, 16-18, 22—Áhítófẹ́lì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Ọba Dáfídì dalẹ̀ rẹ̀, àmọ́ Dáfídì kó gbogbo ìṣòro rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, ara sì tù ú

    • 2Ti 4:16-18—Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù níṣòro, àwọn èèyàn pa á tì, àmọ́ ó ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún un, ìyẹn sì mú kó lókun

Tá a bá ń ronú nípa ibi tá a kù sí àti ẹ̀ṣẹ̀ tá a dá

Job 14:4; Ro 3:23; 5:12

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:

    • Sm 51:1-5—Inú Ọba Dáfídì bà jẹ́ gan-an torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó dá

    • Ro 7:19-24—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ò já mọ́ nǹkan kan nígbà tó ronú nípa bí èrò burúkú ṣe máa ń mú kó wu òun láti ṣe ohun tí kò dáa

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:

    • Sm 103:12; 130:3; Ais 43:25; 1Jo 1:9

  • Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:

    • 1Ọb 9:2-5—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, Jèhófà kà á sí adúróṣinṣin

    • 1Ti 1:12-16—Láìka bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dá sẹ́yìn ṣe pọ̀ tó, ó dá a lójú pé Jèhófà máa fàánú hàn sí òun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́