Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn onírẹ̀lẹ̀ àtàwọn agbéraga?
Sm 138:6; Owe 15:25; 16:18, 19; 22:4; 1Pe 5:5
Tún wo Owe 29:23; Ais 2:11, 12
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Kr 26:3-5, 16-21—Ọba Ùsáyà di agbéraga; ó rú Òfin Ọlọ́run, inú sì bí i nígbà tí wọ́n fún un nímọ̀ràn, torí náà Jèhófà fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú
Lk 18:9-14—Jésù sọ àpèjúwe kan láti fi ṣàlàyé ojú tí Jèhófà fi ń wo àdúrà àwọn agbéraga àtàwọn onírẹ̀lẹ̀
Kí ni Jèhófà máa ṣe tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, tó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
2Kr 12:5-7—Ọba Rèhóbóámù àtàwọn ìjòyè Júdà rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Jèhófà, torí náà Jèhófà ṣàánú wọn, kò sì pa wọ́n run mọ́
2Kr 32:24-26—Ọba rere ni Hẹsikáyà, àmọ́ ó di agbéraga nígbà tó yá, ṣùgbọ́n nígbà tó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, Jèhófà dárí jì í
Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn?
Ef 4:1, 2; Flp 2:3; Kol 3:12, 13
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 33:3, 4—Inú ń bí Ísọ̀ sí Jékọ́bù, àmọ́ Jékọ́bù fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà táwọn méjèèjì pàdé, ìyẹn sì mú kí àlàáfíà jọba láàárín wọn lẹ́ẹ̀kan sí i
Ond 8:1-3—Gídíónì fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ fáwọn ọkùnrin Éfúrémù pé wọ́n sàn ju òun lọ, ìyẹn sì mú kí ìbínú wọn rọlẹ̀
Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
Mt 18:1-5; 23:11, 12; Mk 10:41-45
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ais 53:7; Flp 2:7, 8—Níbàámu pẹ̀lú ohun táwọn wòlíì sọ, Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó gbà láti wá sáyé kó lè wá kú ikú oró, kí wọ́n sì pa á ní ìpa ìkà
Lk 14:7-11—Jésù sọ àpèjúwe kan nípa báwọn èèyàn ṣe ń jókòó níbi àsè kó lè jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀
Jo 13:3-17—Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà tó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ tó sì fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀