-
Ògo Ìtẹ́ Jèhófà ní Ọ̀runÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
Orí 14
Ògo Ìtẹ́ Jèhófà ní Ọ̀run
Ìran 2—Ìṣípayá 4:1–5:14
Ohun tó dá lé: Àwọn ohun àgbàyanu tó ń ṣẹlẹ̀ níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Ìran yìí gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ láti 1914 títí lọ dé òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìjọba Kristi àti ré kọjá rẹ̀ jáde lọ́nà àkànṣe, nígbà tí gbogbo ẹ̀dá tó wà ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé pátá yóò máa yin Jèhófà.—Ìṣípayá 5:13
1. Kí nìdí tí a fi ní láti fọkàn sí àwọn ìran tó tani jí tí Jòhánù ń sọ fún wa yìí gidigidi?
JÒHÁNÙ ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ nípa àwọn ìran tó tani jí tó ń sọ fún wa. Nípa ìmísí, ó ṣì wà ní ọjọ́ Olúwa. Nítorí náà, ohun tó ṣàpèjúwe ní ìtumọ̀ pàtàkì fún àwa tá à ń gbé ní ọjọ́ Olúwa yìí ní tòótọ́. Ńṣe ni Jèhófà ń lo àwọn ìran wọ̀nyí láti fi ṣí ìbòjú kúrò lórí àwọn ohun gidi ti ọ̀run tí a kò lè fojú rí, ó sì jẹ́ ká mọ èrò rẹ̀ nípa àwọn ìdájọ́ rẹ̀ tí ń bọ̀ wá sórí ayé. Síwájú sí i, ìṣípayá wọ̀nyí ń jẹ́ ká lè mọ ipò tí a wà nínú àwọn ohun tí Jèhófà pinnu láti ṣe, yálà a ní ìrètí ti ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, gbogbo wa ní láti máa bá a lọ láti fọkàn sí ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ yìí gidigidi, ìyẹn: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́.”—Ìṣípayá 1:3.
2. Ìrírí wo ni Jòhánù ní nísinsìnyí?
2 Ohun tí Jòhánù wá rí báyìí kọjá ohunkóhun táwọn èèyàn òde òní tíì rí nínú fídíò! Ó kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo rí, sì wò ó! ilẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, ohùn àkọ́kọ́ tí mo sì gbọ́ dà bí ti kàkàkí, ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé: ‘Máa bọ̀ lókè níhìn-ín, èmi yóò sì fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.’” (Ìṣípayá 4:1) Nínú ìran, Jòhánù wọnú ọ̀run tí a kò lè fojú rí, ó wá sí iwájú Jèhófà, ẹni tó wà níbi tó ga fíofío kọjá gbalasa òfuurufú tó ṣeé fojú rí táwọn tó ń rìnrìn àjò ní gbalasa òfuurufú tíì mọ̀, àní ó kọjá ibi tàwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ojú ọ̀run wà pàápàá. Bí ẹní wọlé sínú ilẹ̀kùn ṣíṣí sílẹ̀ kan ni a ṣe ní kí Jòhánù wọlé wá wo ìran àgbàyanu kan nípa inú òkè ọ̀run pátápátá lọ́hùn-ún táwọn ẹni ẹ̀mí ń gbé, níbi tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti gúnwà sórí ìtẹ́. (Sáàmù 11:4; Aísáyà 66:1) Àǹfààní yìí mà ga o!
3. Kí ni ohùn tó “dà bí ti kàkàkí” mú wá sọ́kàn wa, láìsí iyè méjì, ta sì ni Orísun rẹ̀?
3 Bíbélì kò sọ ohun tí “ohùn àkọ́kọ́” yìí jẹ́. Àmọ́ ó ní ìró àṣẹ bíi ti kàkàkí tí ohùn alágbára ti Jésù tí a gbọ́ ní ìṣáájú ní. (Ìṣípayá 1:10, 11) Ó mú wa rántí ìró ìwo tí ń wọni létí tó jẹ́ àmì wíwà tí Jèhófà wà ní Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 19:18-20) Láìsí iyè méjì, Jèhófà tó tóbi lọ́ba ni Orísun ohùn tó ń pa àṣẹ náà. (Ìṣípayá 1:1) Ńṣe ló ṣí ilẹ̀kùn kí Jòhánù lè tipa ìran wọ ibi tó jẹ́ ibi mímọ́ jù lọ láàárín ibi tó lọ salalu tí Jèhófà Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ń ṣàkóso.
Ìrísí Ológo Jèhófà
4. (a) Ìtumọ̀ wo ni ìran Jòhánù ní fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró? (b) Ìtumọ̀ wo ni ó ní fún àwọn tó ní ìrètí ìwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé?
4 Kí ni Jòhánù rí? Fetí sílẹ̀, kó o gbọ́ bó ṣe ń sọ ohun àgbàyanu tó rí. Ó ní: “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, mo wá wà nínú agbára ẹ̀mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀: sì wò ó! ìtẹ́ kan wà ní ipò rẹ̀ ní ọ̀run, ẹni kan sì wà tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà.” (Ìṣípayá 4:2) Ní ìṣẹ́jú akàn, ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run gbé Jòhánù lọ nínú ẹ̀mí, síbi ìtẹ́ Jèhófà gan-an. Èyí mára Jòhánù yá gágá gan-an! Níhìn-ín, a jẹ́ kó rí àkọ́wò ìran kan tó jẹ́ àrímáleèlọ nípa ọ̀run, níbi tí a ti tọ́jú “ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá” pa mọ́ sí de òun àti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yòókù. (1 Pétérù 1:3-5; Fílípì 3:20) Ìran Jòhánù tún ní ìtumọ̀ pàtàkì pẹ̀lú fún àwọn tó ní ìrètí pé wọn á wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ó jẹ́ kí wọ́n lè róye ìrísí ológo tó wà níbi tí Jèhófà wà kí wọ́n sì mọ̀ nípa ètò tí Jèhófà ń lò lọ́run láti fi ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, tó sì jẹ́ èyí tí yóò tún lò nígbà tó bá yá láti fi darí ìgbésí ayé àwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run ètò tí ó ga lọ́lá ni Jèhófà lóòótọ́!
5. Ohun gidi wo ni Jòhánù rí èyí ti ìdérí àpótí májẹ̀mú náà ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?
5 Púpọ̀ lára ohun tí Jòhánù rí lókè ọ̀run lọ́hùn-ún jọ àwọn apá tó ṣe pàtàkì nínú àgọ́ ìjọsìn tí ń bẹ ní aginjù. Wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn yẹn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún ṣáájú ìgbà ayé Jòhánù gẹ́gẹ́ bí ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ti máa ṣe ìjọsìn tòótọ́. Nínú ibi Mímọ́ Jù Lọ àgọ́ ìjọsìn yẹn ni àpótí májẹ̀mú wà, orí ìdérí oníwúrà líle koránkorán Àpótí yẹn ni Jèhófà sì ti sọ̀rọ̀. (Ẹ́kísódù 25:17-22; Hébérù 9:5) Fún ìdí yìí, ìdérí Àpótí náà jẹ́ àpẹẹrẹ ìtẹ́ Jèhófà. Nísinsìnyí Jòhánù wá rí ohun gidi tí èyí jẹ́ àpẹẹrẹ rẹ̀, ìyẹn: Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fúnra rẹ̀ tó gúnwà sórí ìtẹ́ rẹ̀ gíga fíofío ní ọ̀run tòun ti ògo tó kọyọyọ!
6. Kí ni Jòhánù sọ fún wa nípa Jèhófà, kí sì nìdí tí èyí fi bá a mu wẹ́kú?
6 Jòhánù kò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àpèjúwe nípa Ẹni Mímọ́ tó jókòó sórí rẹ̀ bí àwọn wòlíì ìṣáájú tí wọ́n ti rí àwọn ìran ìtẹ́ Jèhófà ti ṣe. (Ìsíkíẹ́lì 1:26, 27; Dáníẹ́lì 7:9, 10) Ṣùgbọ́n bí Jòhánù ṣe sọ ohun tó rí nípa Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà nìyí: “Ẹni tí ó jókòó, ní ìrísí, sì dà bí òkúta jásípérì àti òkúta aláwọ̀ pupa tí ó ṣeyebíye, àti yí ká ìtẹ́ náà òṣùmàrè kan wà tí ó dà bí òkúta émírádì ní ìrísí.” (Ìṣípayá 4:3) Áà, ògo tí kò láfiwé yìí kọyọyọ! Ohun tí Jòhánù rí ni ẹwà tó wà nípò tó tòrò mini, tó ń dán tó sì ń kọ mànà bí àwọn òkúta iyebíye dídán gbinrin, tí ń kọ yẹ̀rì. Ẹ sì wo bí èyí ti bá àpèjúwe tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn ṣe nípa Jèhófà pé ó jẹ́ “Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá” mu wẹ́kú tó! (Jákọ́bù 1:17) Ní gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí Jòhánù gan-an kọ Ìṣípayá, ló sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀, kò sì sí òkùnkùn kankan rárá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (1 Jòhánù 1:5) Ẹni ológo tó ga lọ́lá jù lọ ni Jèhófà jẹ́ ní tòótọ́!
7. Kí ni ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú wíwà tí òṣùmàrè wà yí ká ìtẹ́ Jèhófà?
7 Kíyè sí i pé Jòhánù rí òṣùmàrè kan, tí àwọ̀ rẹ̀ jẹ́ àwọ̀ émírádì aláwọ̀ ewé yí ká ìtẹ́ náà. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ níhìn-ín sí òṣùmàrè (irʹis) fi hàn pé ńṣe ló rí bìrìkìtì ní ìrísí. Ìgbà tí Bíbélì kọ́kọ́ mẹ́nu kan òṣùmàrè ni ìgbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ Nóà. Lẹ́yìn tí Ìkún-omi gbẹ, Jèhófà mú kí òṣùmàrè kan fara hàn ní àwọsánmà, ó sì ṣàlàyé ohun tó ṣàpẹẹrẹ, ó ní: “Òṣùmàrè mi ni mo fi sí àwọsánmà, yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàárín èmi àti ilẹ̀ ayé. Èmi yóò sì rántí májẹ̀mú mi dájúdájú, èyí tí ń bẹ láàárín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo alààyè ọkàn láàárín gbogbo ẹran ara; omi kì yóò sì di àkúnya omi mọ́ láti run gbogbo ẹran ara.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:13, 15) Nígbà náà, kí ni ìran tí Jòhánù wá rí ni ọ̀run yóò mú wá sọ́kàn Jòhánù? Ó yẹ kí òṣùmàrè tó rí yẹn rán an létí pé ó yẹ kó ní àjọṣe alálàáfíà pẹ̀lú Jèhófà, irú èyí tí ẹgbẹ́ Jòhánù ń gbádùn lónìí. Yóò tún jẹ́ kó mọ irú ìtòròmini àti àlàáfíà tó wà níbi tí Jèhófà wà pẹ̀lú, ìtòròmini kan tí gbogbo èèyàn onígbọràn yóò ní nígbà tí Jèhófà bá ta àgọ́ rẹ̀ bo aráyé nínú ayé tuntun.—Sáàmù 119:165; Fílípì 4:7; Ìṣípayá 21:1-4.
Dídá Àwọn Alàgbà Mẹ́rìnlélógún Náà Mọ̀
8. Àwọn wo ni Jòhánù rí yí ká ìtẹ́ náà, ta ni àwọn wọ̀nyí sì dúró fún?
8 Jòhánù mọ̀ pé a yan àwọn àlùfáà kí wọ́n máa sìn nínú àgọ́ ìjọsìn ìgbàanì. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó yà á lẹ́nu láti rí ohun tó ṣàpèjúwe tẹ̀ lé e yìí: “Àti yí ká ìtẹ́ náà ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún wà, mo sì rí àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún tí wọ́n wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun, tí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ̀nyí, adé wúrà sì ń bẹ ní orí wọn.” (Ìṣípayá 4:4) Bẹ́ẹ̀ ni, kàkà kó rí àwọn àlùfáà, alàgbà mẹ́rìnlélógún ló rí, tí wọ́n wà lórí ìtẹ́ tí wọ́n sì dé adé bí ọba. Àwọn wo ni alàgbà wọ̀nyí? Àwọn ẹni àmì òróró inú ìjọ Kristẹni ni, tó jẹ́ pé wọ́n ti jíǹde tí wọ́n sì wà ní ipò tí Jèhófà ṣèlérí fún wọn lọ́run. Báwo la ṣe mọ èyí?
9, 10. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé alàgbà mẹ́rìnlélógún náà dúró fún ìjọ Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n wà nínú ipò ológo wọn ní ọ̀run?
9 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n dé adé. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé wọ́n gba ‘adé kan tí kò lè díbàjẹ́’ wọ́n sì tún gba ìwàláàyè àìlópin, ìyẹn àìleèkú. (1 Kọ́ríńtì 9:25; 15:53, 54) Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí alàgbà mẹ́rìnlélógún wọ̀nyí ti jókòó lórí ìtẹ́, adé wúrà tí wọ́n dé níbí yìí dúró fún níní tí wọ́n ní ọlá àṣẹ bí ọba. (Fi wé Ìṣípayá 6:2; 14:14.) Èyí wà níbàámu pẹ̀lú àlàyé tá a ti ṣe pé alàgbà mẹ́rìnlélógún náà dúró fún àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù bí wọ́n ṣe wà ní ipò wọn ní ọ̀run, torí Jésù bá wọn dá májẹ̀mú pé wọ́n máa jókòó sórí ìtẹ́ nínú Ìjọba òun. (Lúùkù 22:28-30) Jésù àti alàgbà mẹ́rìnlélógún wọ̀nyí nìkan ni a ṣàpèjúwe pé wọ́n ń ṣàkóso ní ọ̀run ní iwájú Jèhófà, kódà Bíbélì ò sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì.
10 Èyí bá ìlérí tí Jésù ṣe fún ìjọ Laodíkíà mu pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi.” (Ìṣípayá 3:21) Ṣùgbọ́n iṣẹ́ tí a yàn fún àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ní ọ̀run kò mọ sí ṣíṣe ìjọba. Nígbà tí Jòhánù ń nasẹ̀ ìwé Ìṣípayá, ó sọ nípa Jésù pé: “Ó sì mú kí a jẹ́ ìjọba kan, àlùfáà fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀.” (Ìṣípayá 1:5, 6) Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọba àti àlùfáà bákan náà. “Wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.”—Ìṣípayá 20:6.
11. Èé ṣe tó fi bá a mu wẹ́kú pé iye àwọn alàgbà wọnnì jẹ́ mẹ́rìnlélógún, kí sì ni iye yẹn túmọ̀ sí?
11 Kí ni ó ṣe pàtàkì nípa iye náà mẹ́rìnlélógún, tó fi jẹ́ pé alàgbà mẹ́rìnlélógún ni Jòhánù rí yí ká ìtẹ́ náà? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà làwọn olóòótọ́ nínú àlùfáà Ísírẹ́lì ìgbàanì gbà jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣáájú fún àwọn alàgbà wọ̀nyí. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.’” (1 Pétérù 2:9) Ẹ sì wá wò ó o, ẹgbẹ́ mẹ́rìnlélógún ni wọ́n pín ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn Júù ìgbàanì sí. Ìpín kọ̀ọ̀kan ni a pín àwọn ọ̀sẹ̀ tirẹ̀ fún lọ́dún kí wọ́n máa wá sìn níwájú Jèhófà, tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ ń bá a lọ láìsí ìdádúró. (1 Kíróníkà 24:5-19) Ó bá a mu wẹ́kú, nígbà náà, pé alàgbà mẹ́rìnlélógún ni Jòhánù rí nínú ìran nípa ẹgbẹ́ àlùfáà ti ọ̀run nítorí ńṣe ni ẹgbẹ́ àlùfáà yìí ń sin Jèhófà nígbà gbogbo, láìdáwọ́dúró. Nígbà tí wọ́n bá pé, ìpín mẹ́rìnlélógún ni yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ẹgbàáta [6,000] aṣẹ́gun, nítorí Ìṣípayá 14:1-4 sọ fún wa pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], (ìyẹn, mẹ́rìnlélógún lọ́nà ẹgbàáta [24 x 6,000]), ni a “rà láti ilẹ̀ ayé wá” láti dúró ní Òkè Síónì ti ọ̀run pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi. Níwọ̀n bí iye náà méjìlá ti túmọ̀ sí ètò tí Ọlọ́run mú kó fìdí múlẹ̀ gbọn-in, mẹ́rìnlélógún jẹ́ ìlọ́po méjì, tàbí èyí tó túbọ̀ fún irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ lókun.
Mànàmáná, Ohùn, àti Ààrá
12. Kí ni Jòhánù rí tó sì gbọ́ lẹ́yìn èyí, kí sì ni “mànàmáná àti ohùn àti ààrá” mú wa rántí?
12 Kí ni Jòhánù rí tí ó sì gbọ́ lẹ́yìn èyí? Ó ní: “Mànàmáná àti ohùn àti ààrá sì ń jáde wá láti inú ìtẹ́ náà.” (Ìṣípayá 4:5a) Èyí múni rántí àwọn ọ̀nà àgbàyanu míì tí Jèhófà ti gbà fi agbára rẹ̀ hàn gan-an ni! Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà “sọ̀ kalẹ̀” sórí Òkè Sínáì, Mósè ròyìn pé: “Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó sì ṣẹlẹ̀ pé ààrá sán, mànàmáná sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ, àti àwọsánmà ṣíṣú dùdù lórí òkè ńlá náà àti ìró ìwo adúnròkè lálá. . . . Nígbà tí ìró ìwo náà túbọ̀ ń dún kíkankíkan láìdáwọ́ dúró, Mósè bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, Ọlọ́run tòótọ́ sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ohùn dá a lóhùn.”—Ẹ́kísódù 19:16-19.
13. Kí ni mànàmáná tí ń ti ibi ìtẹ́ Jèhófà jáde dúró fún?
13 Ní ọjọ́ Olúwa, Jèhófà ń fi agbára rẹ̀ àti wíwà tó wà nítòsí hàn lọ́nà ológo tó ga lọ́lá. Àmọ́ kì í ṣe nípa lílo mànàmáná gidi, nítorí àmì làwọn ohun tí Jòhánù rí jẹ́. Kí wá ni mànàmáná náà dúró fún? Ó dára, ìbùyẹ̀rì mànàmáná lè fúnni ní ìmọ́lẹ̀, ó sì tún lè pani. Fún ìdí yìí, mànàmáná tí ń bù yẹ̀rì jáde láti ibi ìtẹ́ Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ìbùyẹ̀rì ìlàlóye àti ní pàtàkì jù lọ, àwọn ìhìn nípa ìdájọ́ amú-bí-iná tí Ọlọ́run ń bá a lọ láti fún àwọn èèyàn rẹ̀ láìdáwọ́dúró.—Fi wé Sáàmù 18:14; 144:5, 6; Mátíù 4:14-17; 24:27.
14. Báwo ni ohùn ṣe ń dún jáde lónìí?
14 Àwọn ohùn náà ńkọ́? Lákòókò tí Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Sínáì, ohùn kan bá Mósè sọ̀rọ̀. (Ẹ́kísódù 19:19) Àwọn ohùn láti ọ̀run ló sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó jẹ́ àṣẹ àti ìpòkìkí inú ìwé Ìṣípayá. (Ìṣípayá 4:1; 10:4, 8; 11:12; 12:10; 14:13; 16:1, 17; 18:4; 19:5; 21:3) Lónìí Jèhófà pẹ̀lú ti sọ àwọn ohun tó jẹ́ àṣẹ àti àwọn ìpòkìkí kan fáwọn èèyàn rẹ̀, ní títan ìmọ́lẹ̀ sí òye wọn nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti àwọn ìlànà Bíbélì. A sábà máa ń gbọ́ àwọn ìsọfúnni tó ń lani lóye láwọn àpéjọ àgbègbè, irú àwọn òtítọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀ ni a sì ti pòkìkí kárí ayé lẹ́yìn náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn olóòótọ́ oníwàásù ìhìn rere pé: “Họ́wù, ní ti tòótọ́, ‘ìró wọ́n jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, àsọjáde wọn sì jáde lọ sí àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.’”—Róòmù 10:18.
15. Ààrá wo ló ti sán jáde láti orí ìtẹ́ náà ní apá tá a wà yìí nínú ọjọ́ Olúwa?
15 Ààrá sábà máa ń tẹ̀ lé mànàmáná. Dáfídì tọ́ka sí ààrá gidi gẹ́gẹ́ bí “ohùn Jèhófà.” (Sáàmù 29:3, 4) Nígbà tí Jèhófà bá àwọn ọ̀tá jà fún Dáfídì, ààrá ni Bíbélì sọ pe Ó rán sí wọn. (2 Sámúẹ́lì 22:14; Sáàmù 18:13) Élíhù sọ fún Jóòbù pé ohùn Jèhófà dún bí ààrá, bí Ó ti ń ṣe “àwọn ohun ńlá ti a kò lè mọ̀.” (Jóòbù 37:4, 5) Ní apá tá a wà yìí nínú ọjọ́ Olúwa, Jèhófà ti ‘sán ààrá,’ ní kíkìlọ̀ nípa àwọn ohun ńláǹlà tí òun yóò ṣe sí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìró àwọn ààrá ìṣàpẹẹrẹ wọ̀nyí ti dún àdúntúndún jákèjádò ilẹ̀ ayé. Ayọ̀ ńbẹ fún ọ o, tó o bá ń fiyè sí ìpòkìkí adún-bí-ààrá wọ̀nyí tó o sì ń lo ahọ́n rẹ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu láti fi kún ìró wọn!—Aísáyà 50:4, 5; 61:1, 2.
Àwọn Fìtílà Iná àti Òkun Bí Gíláàsì
16. Kí ni “fìtílà iná méje” náà túmọ̀ sí?
16 Kí ni Jòhánù rí síwájú sí i? Ohun tí ó rí nìyí: “Fìtílà iná méje sì wà tí ń jó níwájú ìtẹ́ náà, ìwọ̀nyí sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run. Àti níwájú ìtẹ́ náà ni ohun tí a lè pè ní òkun bí gíláàsì, tí ó dà bí kírísítálì wà.” (Ìṣípayá 4:5b, 6a) Jòhánù fúnra rẹ̀ sọ ohun tí fìtílà méje náà dúró fún pé: “Ìwọ̀nyí sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run.” Iye náà, méje, ṣàpẹẹrẹ ìpépérépéré nínú àwọn ohun ti Ọlọ́run; fún ìdí yìí, fìtílà méje náà ní láti dúró fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ìlanilóye ti ẹ̀mí mímọ́. Ẹ wo bí ẹgbẹ́ Jòhánù náà ti kún fún ìmoore tó lónìí pé a ti fi ìlàlóye yìí sí ìkáwọ́ rẹ̀, tó sì tún jẹ́ ojúṣe rẹ̀ láti rí i dájú pé ìlàlóye yìí dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ebi ń pa nípa tẹ̀mí nínú ayé! Inú wa sì dùn gan-an ni pé lọ́dọọdún ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ń bá a lọ láti máa tan ìmọ́lẹ̀ yìí jáde ní nǹkan bí igba [200] èdè!—Sáàmù 43:3.
17. Kí ni “òkun bí gíláàsì tí ó dà bí òkúta kírísítálì” náà ṣàpẹẹrẹ?
17 Pẹ̀lúpẹ̀lù Jòhánù rí “òkun bí gíláàsì tí ó dà bí kírísítálì.” Kí ni èyí yóò ṣàpẹẹrẹ nínú ọ̀ràn àwọn tí Jèhófà pè wá sínú ààfin rẹ̀ lọ́run? Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí Jésù gbà sọ ìjọ Ọlọ́run di mímọ́, pé ó ‘wẹ̀ ẹ́ mọ́ pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà.’ (Éfésù 5:26) Ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ti mọ́ nísinsìnyí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín.” (Jòhánù 15:3) Nítorí bẹ́ẹ̀, òkun bí gíláàsì tó dà bíi kírísítálì yìí ní láti dúró fún àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń wẹni mọ́. Àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà tó jẹ́ ọba tí wọ́n wá síwájú Jèhófà ní láti jẹ́ àwọn tí a fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wẹ̀ mọ́ tónítóní.
Wò Ó—“Ẹ̀dá Alààyè Mẹ́rin”!
18. Kí ni Jòhánù rí láàárín ìtẹ́ náà àti yí ká rẹ̀?
18 Jòhánù tún kíyè sí nǹkan mìíràn wàyí. Ó kọ̀wé pé: “Àti ní àárín ìtẹ́ náà àti yí ká ìtẹ́ náà ni àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà tí wọ́n kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn.”—Ìṣípayá 4:6b.
19. Kí ni àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì dúró fún, báwo la sì ṣe mọ èyí?
19 Kí ni àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí dúró fún? Ìran kan tí wòlíì mìíràn, ìyẹn Ìsíkíẹ́lì, ròyìn jẹ́ ká rí ìdáhùn rẹ̀. Ìsíkíẹ́lì rí Jèhófà lórí ìtẹ́ kan tó wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run tó láwọn ẹ̀dá alààyè kan, àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì fàwọn nǹkan kan jọ àwọn tí Jòhánù ṣàpèjúwe. (Ìsíkíẹ́lì 1:5-11, 22-28) Lẹ́yìn èyí, Ìsíkíẹ́lì tún rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ìtẹ́ wà lórí rẹ̀ yìí kan náà tòun tàwọn ẹ̀dá alààyè náà. Ṣùgbọ́n, lọ́tẹ̀ yí, kérúbù ló pe àwọn ẹ̀dá alààyè náà. (Ìsíkíẹ́lì 10:9-15) Nígbà náà, ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí Jòhánù rí ní láti dúró fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kérúbù Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ẹ̀dá tó wà nípò gíga nínú ètò Rẹ̀ tó jẹ́ tàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Kò ní ṣàjèjì sí Jòhánù láti rí àwọn kérúbù pé wọ́n wà ní ipò tó sún mọ́ ibi tí Jèhófà wà pẹ́kípẹ́kí, nítorí pé nínú ìṣètò àgọ́ ìjọsìn ìgbàanì, àwọn kérúbù oníwúrà méjì wà lórí ọmọrí àpótí májẹ̀mú, èyí tó dúró fún ìtẹ́ Jèhófà. Ohùn Jèhófà sì máa ń sọ àwọn òfin fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti àárín àwọn kérúbù wọ̀nyí.—Ẹ́kísódù 25:22; Sáàmù 80:1.
20. Ọ̀nà wo la lè gbà sọ pé ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì wà ní “àárín ìtẹ́ náà àti yí ká ìtẹ́ náà”?
20 Ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí wà “ní àárín ìtẹ́ náà àti yí ká ìtẹ́ náà.” Kí ni èyí túmọ̀ sí gan-an? Ó lè túmọ̀ sí pé wọ́n wà yí ká ìtẹ́ náà lọ́nà tó fi jẹ́ pé ọ̀kan dúró ní agbedeméjì ìhà kọ̀ọ̀kan. Nípa báyìí, àwọn tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì Today’s English Version tún ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà sọ lọ́rọ̀ mìíràn, wọ́n ní: “yí ìtẹ́ náà ká ní àwọn ìhà rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” Gbólóhùn náà sì tún lè túmọ̀ sí pé ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà wà ní àárín gbùngbùn ọ̀run níbi tí ìtẹ́ náà wà. Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ìdí tí Bíbélì The Jerusalem Bible fi túmọ̀ gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà lọ́nà yìí: “ní àárín gbùngbùn, a pín wọn sí ẹgbẹẹgbẹ́ yí ká ìtẹ́ náà.” Ohun tó ṣáà ṣe pàtàkì ni bí àwọn kérúbù náà ṣe sún mọ́ ìtẹ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí, lọ́nà tó jọ tàwọn kérúbù tí Ìsíkíẹ́lì rí ní igun kọ̀ọ̀kan kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó dúró fún ètò Jèhófà. (Ìsíkíẹ́lì 1:15-22) Gbogbo èyí bá àwọn ọ̀rọ̀ Sáàmù 99:1 mu pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba. . . . Ó jókòó lórí àwọn kérúbù.”
21, 22. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì? (b) Kí ni ìrísí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà dúró fún?
21 Jòhánù ń bá a lọ pé: “Ẹ̀dá alààyè kìíní sì dà bí kìnnìún, ẹ̀dá alààyè kejì sì dà bí ẹgbọrọ akọ màlúù, ẹ̀dá alààyè kẹta sì ní ojú bí ti ènìyàn, ẹ̀dá alààyè kẹrin sì dà bí idì tí ń fò.” (Ìṣípayá 4:7) Èé ṣe tí ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí fi ní ìrísí tó yàtọ̀ síra wọn? Ó hàn gbangba pé ńṣe làwọn ẹ̀dá alààyè tó dá yàtọ̀ wọ̀nyí ń fi apá pàtó kan lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run hàn. Àkọ́kọ́ níbẹ̀ ni kìnnìún. Nínú Bíbélì, a máa ń fi kìnnìún ṣàpẹẹrẹ ìgboyà, pàápàá tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe ẹ̀tọ́ àti òdodo. (2 Sámúẹ́lì 17:10; Òwe 28:1) Nípa báyìí, kìnnìún dúró fún ànímọ́ Ọlọ́run tí í ṣe ìdájọ́ òdodo onígboyà. (Diutarónómì 32:4; Sáàmù 89:14) Ẹ̀dá alààyè kejì jọ ẹgbọrọ akọ màlúù. Ànímọ́ wo ni akọ màlúù mú wá sọ́kàn rẹ? Lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, akọ màlúù jẹ́ ohun ìní kan tó ṣeyebíye nítorí agbára rẹ̀. (Òwe 14:4; tún wo Jóòbù 39:9-11.) Ẹgbọrọ akọ màlúù, nígbà náà, dúró fún agbára, okun inú gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pèsè rẹ̀.—Sáàmù 62:11; Aísáyà 40:26.
22 Ẹ̀dá alààyè kẹta ní ojú bíi tèèyàn. Èyí ní láti dúró fún ìfẹ́ lọ́nà ti Ọlọ́run, nítorí pé lórí ilẹ̀ ayé, èèyàn nìkan ni Ọlọ́run dá ní àwòrán ara rẹ̀, tó sì dá ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ náà, ìfẹ́, mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; Mátíù 22:36-40; 1 Jòhánù 4:8, 16) Láìsí iyè méjì, àwọn kérúbù ń fi ànímọ́ yìí hàn bí wọ́n ti ń sìn ní àyíká ìtẹ́ Jèhófà. Wàyí o, ẹ̀dá alààyè kẹrin ńkọ́? Èyí ní ìrísí idì tí ń fò. Jèhófà fúnra rẹ̀ pe àfiyèsí sí agbára ìríran ńláǹlà idì, ó ní: “Ojú rẹ̀ ń wo ọ̀nà jíjìn.” (Jóòbù 39:29) Fún ìdí yìí, idì dúró fún ọgbọ́n tí ń ríran jìnnà. Jèhófà ni Orísun ọgbọ́n. Àwọn kérúbù rẹ̀ ń lo ọgbọ́n àtọ̀runwá bí wọ́n ti ń ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀.—Òwe 2:6; Jákọ́bù 3:17.
Ìyìn Jèhófà Ró Gbọnmọgbọnmọ
23. Kí ni kíkún tí ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì “kún fún ojú” ṣàpẹẹrẹ, kí sì ni níní tí wọ́n ní ìyẹ́ apá méjì méjì lọ́nà mẹ́ta ń fi hàn?
23 Jòhánù ń bá àpèjúwe rẹ̀ lọ pé: “Àti ní ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, olúkúlùkù wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìyẹ́ apá mẹ́fà; yí ká àti lábẹ́, wọ́n kún fún ojú. Wọn kò sì ní ìsinmi rárá lọ́sàn-án àti lóru bí wọ́n ti ń wí pé: ‘Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀.’” (Ìṣípayá 4:8) Kíkún tí wọ́n kún fún ojú yìí ń fi hàn pé wọ́n ní agbára ìríran tó pé pérépéré tó sì ríran jìnnà. Ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì ń lò wọ́n láìdáwọ́dúró, torí pé wọn kì í sùn ní tiwọn. Wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ẹni tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Níwọ̀n bí àwọn kérúbù yìí ti ní ojú tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, wọ́n lè rí ibi gbogbo. Kò sí ohunkóhun tó ń fo àfiyèsí wọn. Nípa báyìí, wọ́n ti gbára dì ní kíkún láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run bá yàn fún wọ́n nínú iṣẹ́ ìdájọ́ rẹ̀. Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.” (Òwe 15:3) Bákan náà, bí àwọn kérúbù náà ṣe ní ìyẹ́ apá méjì méjì lọ́nà mẹ́ta, wọ́n lè gbéra lọ fàì bíi ti mànàmáná lọ síbikíbi láti polongo àwọn ìdájọ́ Jèhófà kí wọ́n sì mú wọn ṣẹ, nítorí pé iye tàbí nọ́ńbà náà, mẹ́ta là ń lò nínú Bíbélì fún ìtẹnumọ́.
24. Báwo ni àwọn kérúbù ṣe ń yin Jèhófà, kí nìyẹn sì tún mọ̀ sí?
24 Fetí sílẹ̀! Orin ìyìn tí àwọn kérúbù ń kọ sí Jèhófà jẹ́ orin adùnyùngbà tó ń mórí ẹni wú gidigidi. Wọ́n ní: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀.” Lẹ́ẹ̀kan sí i, ńṣe ni jíjẹ́ tí ìpolongo wọn jẹ́ mẹ́ta ń fi hàn pé ó gbóná janjan. Àwọn kérúbù náà ń tẹnu mọ́ ọn gidigidi pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ mímọ́. Òun ni Orísun ìjẹ́mímọ́, òun gan-an sì ni Ìdiwọ̀n ìjẹ́mímọ́. Òun pẹ̀lú tún ni “Ọba ayérayé,” ìgbà gbogbo ni òun sì jẹ́ “Ááfà àti Ómégà, ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin.” (1 Tímótì 1:17; Ìṣípayá 22:13) Àwọn kérúbù kì í fìgbà kankan sinmi rárá o bí wọ́n ti ń pòkìkí àwọn ànímọ́ Jèhófà aláìlẹ́gbẹ́ níwájú gbogbo ẹ̀dá.
25. Báwo ni àwọn ẹ̀dá alààyè àti alàgbà mẹ́rìnlélógún wọnnì ṣe ń fi ìṣọ̀kan júbà Jèhófà?
25 Ìyìn Jèhófà wá ń dún lọ réré ní gbogbo inú ìsálú ọ̀run! Jòhánù ń bá ohun tó ń sọ lọ pé: “Àti nígbàkigbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá fi ògo àti ọlá àti ìdúpẹ́ fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, Ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé, àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà a wólẹ̀ níwájú Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a jọ́sìn Ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé, wọn a sì ju adé wọn síwájú ìtẹ́ náà, wọn a sọ pé: ‘Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.’” (Ìṣípayá 4:9-11) Nínú gbogbo Ìwé Mímọ́, èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tó ga lọ́lá jù lọ tí wọ́n gbà júbà Jèhófà, Ọlọ́run wa àti Olúwa Ọba Aláṣẹ!
26. Kí nìdí tí alàgbà mẹ́rìnlélógún wọnnì fi ju adé wọn sílẹ̀ níwájú Jèhófà?
26 Alàgbà mẹ́rìnlélógún wọnnì ní irú ẹ̀mí kan náà tí Jésù ní, àní débi pé wọ́n ju adé wọn sílẹ̀ níwájú Jèhófà. Kò sóhun tó jọ èrò gbígbé ara ẹni ga níwájú Ọlọ́run lọ́kàn wọn rárá. Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi mọ̀ dájú pé ìdí kan ṣoṣo tí wọ́n fi wà nípò ọba ni láti máa fi ọlá àti ògo fún Ọlọ́run àní bí Jésù ti ń ṣe nígbà gbogbo. (Fílípì 2:5, 6, 9-11) Pẹ̀lú ìtẹríba ni wọ́n fi fi hàn pé ipò rírẹlẹ̀ làwọn wà, tí wọ́n sì tún fi hàn pé ọlá Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ làwọn fi ń ṣàkóso. Nípa báyìí, wọ́n wà ní ìṣọ̀kan látọkànwá pẹ̀lú àwọn kérúbù àti ìyókù ìṣẹ̀dá olóòótọ́ ní fífi ìyìn àti ògo fún Ọlọ́run tí ó dá ohun gbogbo.—Sáàmù 150:1-6.
27, 28. (a) Ipa wo ló yẹ kí àpèjúwe Jòhánù nípa ìran yìí ní lórí wa? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ nípa ohun tí Jòhánù rí tó sì gbọ́ tẹ̀ lé èyí?
27 Ta ní lè ka ohun tí Jòhánù kọ nípa ìran yìí tí orí rẹ̀ ò ní wú? Ó kàmàmà, àní àgbàyanu ni! Ṣùgbọ́n báwo ni gbogbo èyí ṣe kàn wá? Ẹnikẹ́ni tó bá lẹ́mìí ìmọrírì ní láti jẹ́ kí ọlá ńlá Jèhófà mú kí òun dara pọ̀ mọ́ ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì àti alàgbà mẹ́rìnlélógún náà láti máa yin Jèhófà, nínú àdúrà gbígbà àti nípa pípòkìkí orúkọ rẹ̀ fáwọn èèyàn. Èyí ni Ọlọ́run tí àwa Kristẹni ní àǹfààní láti jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ lónìí. (Aísáyà 43:10) Rántí pé ìran Jòhánù kan ọjọ́ Olúwa, èyí tá a wà lónìí. “Ẹ̀mí méje” yẹn wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo láti ṣamọ̀nà wa kó sì fún wa lókun. (Gálátíà 5:16-18) A ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lónìí, tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ mímọ́ bá a ṣe ń sin Ọlọ́run mímọ́. (1 Pétérù 1:14-16) Dájúdájú, a láyọ̀ láti ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè. (Ìṣípayá 1:3) Ẹ wo bí wọ́n ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ tó ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ká má sì jẹ́ kí ayé pín ọkàn wa níyà nínú kíkọrin ìyìn rẹ̀ déédéé!—1 Jòhánù 2:15-17.
28 Jòhánù ti ṣàpèjúwe ohun tó rí nígbà tí a ké sí i láti gba ẹnu ilẹ̀kùn ṣíṣí sílẹ̀ yẹn ní ọ̀run wọlé wá. Ní pàtàkì jù lọ, ó ròyìn pé Jèhófà, Ọ̀gá Ògo, gúnwà sórí ìtẹ́ Rẹ̀ lókè ọ̀run nínú ọlá ńlá àti gbogbo ògo Rẹ̀. Ètò tó lágbára jù lọ láyé àtọ̀run sì wà yí i ká, ìyẹn ètò tó jẹ́ pé ògo ẹwà rẹ̀ àti ìdúróṣinṣin rẹ̀ kọyọyọ. Bẹ́ẹ̀ ni, Kóòtù ọ̀run wà lẹ́nu iṣẹ́. (Dáníẹ́lì 7:9, 10, 18) Ohun àrà ọ̀tọ̀ kan máa tó ṣẹlẹ̀ wàyí. Kí ni ohun náà, báwo ló sì ṣe kàn wá lónìí? Ẹ jẹ́ ká máa wo bí ìran náà yóò ṣe máa ṣẹlẹ̀!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 75]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 78]
-
-
“Ta Ni Ó Yẹ Láti Ṣí Àkájọ Ìwé Náà?”Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
Orí 15
“Ta Ni Ó Yẹ Láti Ṣí Àkájọ Ìwé Náà?”
1. Kí ló ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí nínú ìran tí Jòhánù rí?
Ó GA LỌ́LÁ! ÀGBÀYANU NI! Ìran nípa ìtẹ́ Jèhófà, ìyẹn bá a ṣe gbé e kalẹ̀ láàárín àwọn fìtílà iná, àwọn kérúbù, alàgbà mẹ́rìnlélógún, àti òkun bí gíláàsì náà kàmàmà. Alàgbà Jòhánù, kí lo wá rí lẹ́yìn ìyẹn o? Jòhánù tẹjú mọ́ àárín gbùngbùn ibi ìran ọ̀run yìí, ó sì sọ fún wa pé: “Mo sì rí ní ọwọ́ ọ̀tún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àkájọ ìwé kan tí a kọ̀wé sí tinú-tẹ̀yìn, tí a fi èdìdì méje dì pinpin. Mo sì rí áńgẹ́lì alágbára kan tí ń pòkìkí pẹ̀lú ohùn rara pé: ‘Ta ni ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà, kí ó sì tú àwọn èdìdì rẹ̀?’ Ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ ẹnì kan ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé tí ó lè ṣí àkájọ ìwé náà tàbí láti wo inú rẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí pé a kò rí ẹnì kan tí ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà tàbí láti wo inú rẹ̀.”—Ìṣípayá 5:1-4.
2, 3. (a) Kí nìdí tí Jòhánù fi ń hára gàgà pé ká rí ẹnì kan tí yóò ṣí àkájọ ìwé náà, ṣùgbọ́n kí ló dà bíi pé ó wá fẹ́ ṣẹlẹ̀ báyìí? (b) Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni àmì òróró ti ń fi ìháragàgà dúró dè nígbà tiwa?
2 Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ gbogbo ẹ̀dá fúnra rẹ̀ ló na àkájọ ìwé yẹn síta. Ó ní láti jẹ́ pé ìsọfúnni pàtàkì kún inú rẹ̀, nítorí tojú-tẹ̀yìn rẹ̀ la kọ nǹkan sí. Ara wa ti wà lọ́nà láti mọ̀ nípa rẹ̀. Kí ló wà nínú àkájọ ìwé yìí? A rántí pé ohun tí Jèhófà sọ fún Jòhánù níbẹ̀rẹ̀ ni: “Máa bọ̀ lókè níhìn-ín, èmi yóò sì fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.” (Ìṣípayá 4:1) A ti ń hára gàgà láti mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n, áà, ó ṣe! Ńṣe ni wọ́n pa àkájọ ìwé náà dé pinpin, wọ́n fi èdìdì méje dì í pa!
3 Ǹjẹ́ áńgẹ́lì alágbára náà yóò rí ẹnì kan tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà? Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Kingdom Interlinear ti wí, “ọwọ́ ọ̀tún” Jèhófà ni àkájọ ìwé náà wà. Èyí fi hàn pé ńṣe ló la àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bó ṣe nà án síta. Ṣùgbọ́n ó jọ pé kò sí ẹnì kankan ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé tó kúnjú òṣùwọ̀n láti gba àkájọ ìwé yẹn kó sì ṣí i. Kò tilẹ̀ sí ẹnikẹ́ni lábẹ́ ilẹ̀ ayé pàápàá, ìyẹn láàárín àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti kú, tó kúnjú òṣùwọ̀n ọlá gíga yìí. Abájọ tí inú Jòhánù fi bà jẹ́! Ṣé bí kò ṣe wá ní mọ “àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀” yẹn mọ́ nìyẹn? Nígbà tiwa yìí pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni àmì òróró ṣe fi ìháragàgà dúró de Jèhófà pé kó rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ jáde sórí Ìṣípayá. Ńṣe ni yóò sì ṣe é ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ní àkókò tá a yàn kalẹ̀ fún ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà, láti lè ṣamọ̀nà àwọn èèyàn rẹ̀ lọ sí ọ̀nà “ìgbàlà títóbi lọ́lá.”—Sáàmù 43:3, 5.
Ẹni Yíyẹ Náà
4. (a) Níkẹyìn, ta ni a rí pé ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà àtàwọn èdìdì rẹ̀? (b) Èrè àti àǹfààní wo ni ẹgbẹ́ Jòhánù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń rí ní nísinsìnyí?
4 Bẹ́ẹ̀ ni! Ẹnì kan wà tó lè ṣí àkájọ ìwé náà! Jòhánù ròyìn pé: “Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn alàgbà náà wí fún mi pé: ‘Dẹ́kun ẹkún sísun. Wò ó! Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà, gbòǹgbò Dáfídì, ti ṣẹ́gun láti lè ṣí àkájọ ìwé náà àti èdìdì méje rẹ̀.’” (Ìṣípayá 5:5) Nítorí náà, Jòhánù, nu omijé rẹ! Lónìí pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ ọdún ni ẹgbẹ́ Jòhánù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó jẹ́ adúróṣinṣin fi fara da àwọn àdánwò lílekoko bí wọ́n ṣe ń fi sùúrù dúró de ìgbà tí wọ́n máa gba ìlàlóye. Èrè ńlá tó ń tuni nínú gan-an ló jẹ́ fún wa o nísinsìnyí láti lóye ìran náà, ẹ sì wo àǹfààní tó jẹ́ láti nípìn-ín nínú ìmúṣẹ rẹ̀ ní ti pé à ń pòkìkí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn!
5. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni a sọ nípa Júdà, ibo sì ni àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà ti ṣàkóso? (b) Ta ni Ṣílò?
5 Áà, “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà”! Jòhánù mọ àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù, baba ńlá ìran àwọn Júù, sọ nípa Júdà ọmọ rẹ̀ kẹrin dáadáa, pé: “Ọmọ kìnnìún ni Júdà. Ọmọkùnrin mi, láti inú ẹran ọdẹ ni ìwọ yóò ti gòkè lọ. Ó tẹrí ba, ó na ara rẹ̀ tàntàn bí kìnnìún, àti bí kìnnìún, ta ní jẹ́ gbójú-gbóyà láti ta á jí? Ọ̀pá aládé kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ kì yóò yà kúrò ní àárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣílò yóò fi dé; ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:9, 10) Ọ̀dọ̀ Júdà ni ìlà àwọn ọba tó ń jẹ lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti wá. Bẹ̀rẹ̀ látorí Dáfídì, gbogbo àwọn ọba tí wọ́n ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù títí táwọn ará Bábílónì fi pa ìlú yẹn run jẹ́ àtọmọdọ́mọ Júdà. Ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí lára wọn tó jẹ́ Ṣílò tí Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀. Ṣílò túmọ̀ sí “Ẹni Tí [Ẹ̀tọ́] Jẹ́ Tirẹ̀.” Jésù, ẹni tí Ìjọba Dáfídì nísinsìnyí jẹ́ tirẹ̀ títí lọ gbére, ni orúkọ yìí ń tọ́ka sí lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 21:25-27; Lúùkù 1:32, 33; Ìṣípayá 19:16.
6. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ẹ̀ka igi” Jésè àti “gbòǹgbò Dáfídì” pẹ̀lú?
6 Kíákíá ni Jòhánù dá gbólóhùn náà “gbòǹgbò Dáfídì” mọ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pe Mèsáyà tí a ṣèlérí náà ní “ẹ̀ka igi kan . . . láti ara kùkùté Jésè [ìyẹn baba Dáfídì Ọba] . . . èéhù kan” àti “gbòǹgbò Jésè . . . tí yóò dìde dúró gẹ́gẹ́ bí àmì àfiyèsí fún àwọn ènìyàn.” (Aísáyà 11:1, 10) Jésù jẹ́ ẹ̀ka igi Jésè, níwọ̀n bí a ti bí i sínú ìlà ìdílé Dáfídì ọmọ Jésè, tí wọ́n ti ń jọba. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bíi gbòǹgbò Jésè, òun ni Ẹni tó mú kí ìlà ọba Dáfídì hù lẹ́ẹ̀kan sí i, tó mú kó wà láàyè tó sì ń tì í lẹ́yìn, títí láé.—2 Sámúẹ́lì 7:16.
7. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù ló yẹ láti gba àkájọ ìwé náà lọ́wọ́ Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà?
7 Ní pàtàkì jù lọ, Jésù ni ẹ̀dá èèyàn pípé tó fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà, àní lábẹ́ àwọn àdánwò tó le koko jù lọ. Ó pèsè ìdáhùn pípé sí ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀. (Òwe 27:11) Ìyẹn ló fi lè sọ ohun tó sọ lóru ọjọ́ tó ṣáájú ikú tó kú láti fi ṣèrúbọ, pé: “Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33) Ìdí nìyí tí Jèhófà fi gbé “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé” lè Jésù lọ́wọ́ nígbà tó jí i dìde. Nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, òun nìkan ṣoṣo ló kúnjú òṣùwọ̀n láti gba àkájọ ìwé náà, láti lè jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì tó wà nínú rẹ̀.—Mátíù 28:18.
8. (a) Báwo ni àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe jẹ́ kó hàn pé Jésù lẹni yíyẹ yẹn lóòótọ́? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu pé kí ọ̀kan nínú àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà sọ ẹni tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà fún Jòhánù?
8 Ó bá a mu gan-an lóòótọ́, pé Jésù lẹni tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà. Látọdún 1914 ló ti di Ọba Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run, ohun púpọ̀ ni àkájọ ìwé náà sì ti jẹ́ ká mọ̀ nípa Ìjọba náà àtàwọn ohun tí yóò ṣe. Jésù fi ìṣòtítọ́ jẹ́rìí sí òtítọ́ nípa Ìjọba náà nígbà tó wà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 18:36, 37) Ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún dídé Ìjọba náà. (Mátíù 6:9, 10) Òun ló bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run níbẹ̀rẹ̀ sànmánì Kristẹni tó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù yẹn ṣe máa parí lákòókò òpin. (Mátíù 4:23; Máàkù 13:10) Bákan náà, ó tún bá a mu wẹ́kú pé ọ̀kan nínú alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ló sọ fún Jòhánù pé Jésù ni ẹni tí yóò ṣí àwọn èdìdì náà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn alàgbà wọ̀nyí wà lórí ìtẹ́ wọ́n sì dé adé nítorí àjùmọ̀jogún ni wọ́n jẹ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀.—Róòmù 8:17; Ìṣípayá 4:4.
‘Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Tí A Pa’
9. Dípò kìnnìún, kí ni Jòhánù rí tó dúró “ní àárín ìtẹ́,” báwo ló sì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀?
9 Jòhánù tẹjú mọ́ ibẹ̀ láti rí “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà” yìí. Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu gbáà lohun tó rí! Ẹ̀dá ìṣàpẹẹrẹ tó yàtọ̀ pátápátá ló jáde wá. Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí ní ìdúró ní àárín ìtẹ́ náà àti ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà àti ní àárín àwọn alàgbà náà, ọ̀dọ́ àgùntàn kan bí ẹni pé a ti fikú pa á, tí ó ní ìwo méje àti ojú méje, àwọn ojú tí wọ́n túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run tí a ti rán jáde sí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 5:6.
10. Ta ni “ọ̀dọ́ àgùntàn” tí Jòhánù rí, kí sì nìdí tí orúkọ náà fi bá a mu?
10 Àárín gbùngbùn gan-an, lẹ́bàá ìtẹ́ náà, láàárín agbo tí ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì àti alàgbà mẹ́rìnlélógún náà pa yí ká, ló ti rí ọ̀dọ́ àgùntàn kan! Láìsí àní-àní, kíákíá ni Jòhánù mọ̀ pé ọ̀dọ́ àgùntàn yìí ni “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà” àti “gbòǹgbò Dáfídì.” Ó mọ̀ pé nígbà tí Jòhánù Oníbatisí ń fi Jésù han àwọn Júù tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún ṣáájú, ó pe Jésù ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòhánù 1:29) Ní gbogbo ìgbé ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jésù ò jẹ́ kí ayé kó àbààwọ́n kankan bá òun, àní gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lálèébù rárá, tó fi lè wá fi ìwàláàyè rẹ̀ aláìlẹ́gàn rú ẹbọ fún aráyé.—1 Kọ́ríńtì 5:7; Hébérù 7:26.
11. Kí nìdí tí kì í fi í ṣe nǹkan àbùkù láti fi “ọ̀dọ́ àgùntàn kan bí ẹni pé a ti fikú pa á” ṣàpẹẹrẹ Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo?
11 Ǹjẹ́ kì í ṣe nǹkan àbùkù láti fi “ọ̀dọ́ àgùntàn kan bí ẹni pé a ti fikú pa á” ṣàpẹẹrẹ Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo? Rárá o! Ìṣẹ́gun ńlá lórí Sátánì ni jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, ó sì jẹ́ ìṣẹ́gun ńláǹlà fún Jèhófà Ọlọ́run. Ńṣe ni ṣíṣàpẹẹrẹ Jésù lọ́nà yìí ń fi ọ̀nà tó gbà ṣẹ́gun ayé Sátánì hàn kedere, ó sì ń múni rántí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà àti Jésù ní fún aráyé. (Jòhánù 3:16; 15:13; fi wé Kólósè 2:15.) Bá a sì ṣe wá fi hàn nìyẹn pé Jésù ni Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí náà, tó kúnjú òṣùwọ̀n gbáà láti ṣí àkájọ ìwé náà.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
12. Kí ni ìwo méje Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣàpẹẹrẹ?
12 Ohun mìíràn wo ló jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì “ọ̀dọ́ àgùntàn” yìí? Ó jẹ́ torí pé ó ní ìwo méje. Bíbélì sábà máa ń fi ìwo ṣàpẹẹrẹ agbára tàbí ọlá àṣẹ, jíjẹ́ tó sì jẹ́ méje yóò fi hàn pé ó pé pérépéré. (Fi wé 1 Sámúẹ́lì 2:1, 10; Sáàmù 112:9; 148:14.) Fún ìdí yìí, ìwo méje Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà dúró fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára tí Jèhófà gbé lé Jésù lọ́wọ́. Ó wà “lókè fíofío ré kọjá gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí nìkan, ṣùgbọ́n nínú èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.” (Éfésù 1:20-23; 1 Pétérù 3:22) Ní pàtàkì, Jésù ti ń lo agbára, ìyẹn agbára ìjọba láti ọdún 1914 tí Jèhófà ti fi jẹ ọba ní ọ̀run.—Sáàmù 2:6.
13. (a) Kí ni ojú méje Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wá ṣe?
13 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jésù kún fún ẹ̀mí mímọ́, torí pé ìyẹn lóhun tí ojú méje Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, tó “túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run,” ń ṣàpẹẹrẹ. Ọ̀nà kan tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀mí Jèhófà gbà ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ni nípasẹ̀ Jésù. (Títù 3:6) Ẹ̀rí fi hàn pé, ẹ̀mí kan náà yìí ló ń mú kó lè máa rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé láti ọ̀run. Jésù ní ìfòyemọ̀ pípé bíi ti Baba rẹ̀. Kò sí nǹkan kan tó pa mọ́ fún un, gbogbo rẹ̀ ló ń rí kedere. (Fi wé Sáàmù 11:4; Sekaráyà 4:10.) Ó ṣe kedere pé, Ọmọ yìí, ìyẹn olùpa ìwà títọ́ mọ́ tó ṣẹ́gun ayé; Kìnnìún ẹ̀yà Júdà; gbòǹgbò Dáfídì; ẹni tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ fún aráyé; tó ní ọlá àṣẹ pípé pérépéré, tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀mí mímọ́, àti ìfòyemọ̀ pípé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni tó ta yọ yìí gan-an ló yẹ láti gba àkájọ ìwé náà ní ọwọ́ Jèhófà. Ǹjẹ́ ó wá lọ́ tìkọ̀ láti gba iṣẹ́ yìí nínú ètò Jèhófà tó ga fíofío? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni “ó . . . lọ, ó sì gbà á [ìyẹn àkájọ ìwé náà] lójú ẹsẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́.” (Ìṣípayá 5:7) Àpẹẹrẹ rere gbáà ni èyí jẹ́ ní ti pé ká múra tán láti ṣègbọràn!
Orin Ìyìn
14. (a) Kí ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọnnì àti alàgbà mẹ́rìnlélógún ṣe nígbà tí Jésù gba àkájọ ìwé náà? (b) Báwo ni ìsọfúnni tí Jòhánù rí gbà nípa alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ṣe túbọ̀ jẹ́ ká mọ àwọn àti ipò wọn dájú?
14 Kí ni àwọn yòókù tó wà níwájú ìtẹ́ Jèhófà wá ṣe? “Nígbà tí ó sì gba àkájọ ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin àti àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn ní háàpù kan lọ́wọ́ àti àwokòtò wúrà tí ó kún fún tùràrí, tùràrí náà sì túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 5:8) Bí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó jẹ́ kérúbù tó wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run ṣe tẹrí ba náà làwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ṣe tẹrí ba fún Jésù láti fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn alàgbà wọ̀nyí nìkan ni wọ́n ní háàpù àti àwokòtò tùràrí.a Àwọn nìkan sì ni wọ́n ń kọrin tuntun kan nísinsìnyí. (Ìṣípayá 5:9) Nípa báyìí wọ́n jọ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tí wọ́n jẹ́ mímọ́, táwọn pẹ̀lú ní háàpù tí wọ́n sì ń kọrin tuntun kan. (Gálátíà 6:16; Kólósè 1:12; Ìṣípayá 7:3-8; 14:1-4) Síwájú sí i, alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ni a fi hàn pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ kan ní ọ̀run, ìyẹn iṣẹ́ àlùfáà. Àpẹẹrẹ tiwọn ni iṣẹ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n ń sun tùràrí fún Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn ní Ísírẹ́lì ìgbàanì jẹ́, èyí tó ti dópin lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Ọlọ́run mú Òfin Mósè kúrò ní ojú ọ̀nà, tó kàn án mọ́ igi oró Jésù. (Kólósè 2:14) Kí la rí fà yọ nínú gbogbo èyí? Òun ni pé ńṣe ni ibí yìí ń jẹ́ ká rí àwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun bí wọ́n ṣe wà lẹ́nu iṣẹ́ wọn gíga jù lọ, tí í ṣe ‘àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, tí wọ́n ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún.’—Ìṣípayá 20:6.
15. (a) Ní Ísírẹ́lì, ta ni ẹnì kan ṣoṣo tó láǹfààní láti wọ ibi Mímọ́ Jù Lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn? (b) Kí nìdí tí àlùfáà àgbà fi gbọ́dọ̀ sun tùràrí kó tó wọnú ibi Mímọ́ Jù Lọ nítorí ẹ̀mí rẹ̀?
15 Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àlùfáà àgbà nìkan ló lè wọ ibi Mímọ́ Jù Lọ láti wá síwájú ibi tó ń ṣàpẹẹrẹ ibi tí Jèhófà wà. Tí àlùfáà àgbà yìí kò bá fẹ́ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ gbé tùràrí dání wá síbẹ̀. Òfin Jèhófà sọ pé: “Kí [Áárónì] mú ìkóná tí ó kún fún ẹyín iná tí ń jó láti orí pẹpẹ níwájú Jèhófà, kí ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sì kún fún àtàtà tùràrí onílọ́fínńdà, kí ó sì mú wọn wá sínú aṣọ ìkélé. Kí ó sì fi tùràrí sínú iná níwájú Jèhófà, kí ìṣúdùdù èéfín tùràrí sì bo ìbòrí Àpótí, tí ó wà lórí Gbólóhùn Ẹ̀rí, kí ó má bàa kú.” (Léfítíkù 16:12, 13) Àlùfáà àgbà ò lè rí inú ibi Mímọ́ Jù Lọ wọ̀ láàyè àyàfi tó bá sun tùràrí.
16. (a) Lábẹ́ ètò àwọn nǹkan ti Kristẹni, àwọn wo ló wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ lọ́run, èyí tí ibi mímọ́ jù lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀? (b) Kí nìdí táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi ní láti ‘sun tùràrí’?
16 Nínú ètò àwọn nǹkan ti Kristẹni, Jésù Kristi, Àlùfáà Àgbà táwọn àlùfáà àgbà ìṣáájú jẹ́ àpẹẹrẹ rẹ̀, nìkan kọ́ ló wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ìyẹn ibi tí Jèhófà wà ní ọ̀run, èyí tí ibi mímọ́ jù lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn ń ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Olúkúlùkù ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ àlùfáà lábẹ́ Jésù náà wọ̀ ọ́ níkẹyìn. (Hébérù 10:19-23) Àwọn àlùfáà yìí, táwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ń ṣàpẹẹrẹ, kò lè wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ náà àyàfi bí wọ́n bá ‘sun tùràrí,’ ìyẹn ni pé kí wọ́n máa gbàdúrà kí wọ́n sì máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà nígbà gbogbo.—Hébérù 5:7; Júúdà 20, 21; fi wé Sáàmù 141:2.
Orin Tuntun Kan
17. (a) Orin tuntun wo ni alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ń kọ? (b) Báwo la ṣe sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “orin tuntun” nínú Bíbélì?
17 Orin adùnyùngbà kan bẹ̀rẹ̀ sí í dún wàyí. Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà làwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ìyẹn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà, ń kọrin sí: “Wọ́n sì ń kọ orin tuntun kan, pé: ‘Ìwọ ni ó yẹ láti gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, nítorí pé a fikú pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.’” (Ìṣípayá 5:9) Ọ̀rọ̀ náà “orin tuntun” wáyé ní ìgbà mélòó kan nínú Bíbélì, ó sì sábà máa ń tọ́ka sí yíyin táwọn èèyàn ń yin Jèhófà fún àwọn iṣẹ́ ìdáǹdè ńláǹlà kan tó ṣe. (Sáàmù 96:1; 98:1; 144:9) Ìyẹn fi hàn pé orin náà jẹ́ tuntun nítorí pé ẹni tó ń kọ ọ́ á pòkìkí àwọn àfikún iṣẹ́ àgbàyanu tí Jèhófà ṣe á sì tún sọ bó ṣe mọrírì orúkọ Rẹ̀ ológo tó lẹ́ẹ̀kan sí i.
18. Torí kí ni alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ṣe ń kọ orin tuntun láti fi yin Jésù?
18 Níhìn-ín, iwájú Jésù làwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà ti ń kọ orin tuntun kan dípò kó jẹ́ níwájú Jèhófà. Ṣùgbọ́n ìlànà kan náà ni wọ́n ń tẹ̀ lé. Ńṣe ni wọ́n ń yin Jésù fáwọn ohun tí òun, Ọmọ Ọlọ́run, ṣe nítorí tiwọn. Ó tipa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe alárinà májẹ̀mú tuntun, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó ṣeé ṣe láti mú orílẹ̀-èdè tuntun kan tó jẹ́ àkànṣe ìní Jèhófà jáde. (Róòmù 2:28, 29; 1 Kọ́ríńtì 11:25; Hébérù 7:18-25) Inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ayé làwọn tí wọ́n jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun yìí ti wá, ṣùgbọ́n Jésù so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan sínú ìjọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan.—Aísáyà 26:2; 1 Pétérù 2:9, 10.
19. (a) Ìbùkún wo ni kò ṣẹ sí Ísírẹ́lì ti ara lára nítorí àìṣòótọ́ wọn? (b) Ìbùkún wo ni orílẹ̀-èdè tuntun ti Jèhófà ń rí gbà?
19 Nígbà tí Jèhófà sọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè kan nígbà ayé Mósè lọ́hùn-ún, ó bá wọn dá májẹ̀mú ó sì ṣèlérí pé bí wọ́n bá ń bá a lọ láti pa májẹ̀mú yẹn mọ́, wọn yóò di ìjọba àwọn àlùfáà fún òun. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò máa bá a lọ láti pa májẹ̀mú náà mọ́, nítorí náà ìlérí yẹn kò ṣẹ sí wọn lára rárá. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè tuntun náà, tí a tipa májẹ̀mú tuntun tí Jésù ṣalárinà rẹ̀ dá sílẹ̀, jẹ́ olóòótọ́. Bí àwọn tí wọ́n wà nínú orílẹ̀-èdè náà ṣe dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ọba nìyẹn, tí wọ́n sì tún ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà, ní ríran àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ nínú aráyé lọ́wọ́ láti padà bá Jèhófà rẹ́. (Kólósè 1:20) Gan-an bí orin tuntun náà ti sọ ọ́ ló rí, ó ní: “O sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:10) Inú alàgbà mẹ́rìnlélógún wọnnì mà dùn gan-an o, bí wọ́n ṣe ń kọ orin ìyìn tuntun yìí sí Jésù tá a ti ṣe lógo!
Orin Ọ̀run
20. Orin ìyìn wo ni wọ́n wá ń kọ sí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà nísinsìnyí?
20 Kí ni àwọn ọ̀kẹ́ àìmọye ẹgbẹ́ ọmọ ogun yòókù tó wà nínú ètò Jèhófà ní ọ̀run wá ṣe nípa orin tuntun yìí? Orí Jòhánù wú gan-an nígbà tó rí bí wọ́n ṣe fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú orin yìí tọkàntọkàn, ó ní: “Mo sì rí, mo sì gbọ́ ohùn ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ní àyíká ìtẹ́ àti àwọn ẹ̀dá alààyè àti àwọn alàgbà náà, iye wọn sì jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí wọ́n ń wí ní ohùn rara pé: ‘Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí a fikú pa ni ó yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.’” (Ìṣípayá 5:11, 12) Orin ìyìn yìí mà wuni lórí o!
21. Ǹjẹ́ yíyin tí wọ́n ń yin Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà bu ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run kù? Ṣàlàyé.
21 Ṣé èyí ń fi hàn pé Jésù ti wá bọ́ sípò Jèhófà Ọlọ́run ni lọ́nà kan ṣá nísinsìnyí àti pé òun ni gbogbo ẹ̀dá wá ń yìn dípò Baba rẹ̀? Kò rí bẹ́ẹ̀ o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lorin ìyìn yìí bá ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé rẹ̀ mu pé: “Ọlọ́run . . . gbé [Jésù] sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.” (Fílípì 2:9-11) Ńṣe ni wọ́n ń kókìkí Jésù níhìn-ín nítorí ipa tó kó nínú yíyanjú ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ tí gbogbo ẹ̀dá dojú kọ, ìyẹn ọ̀ràn bí yóò ṣe di mímọ̀ pé Jèhófà nìkan ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ògo tí èyí sì ti mú wá fún Baba rẹ̀ pọ̀ gan-an ni!
Orin Ìyìn Tó Túbọ̀ Ń Dún Ròkè
22. Orin ìyìn wo ni àwọn ẹ̀dá ilẹ̀ ayé náà ń kọ nínú rẹ̀?
22 Nínú ìran tí Jòhánù ń sọ fún wa, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run fi orin adùnyùngbà yin Jésù láti fi hàn pé wọ́n mọrírì ìṣòtítọ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ tó gbà lọ́run. Àwọn ẹ̀dá ilẹ̀ ayé náà ń bá wọn kọ orin yìí níwọ̀n bí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ti ń yin Baba àti Ọmọ rẹ̀. Bí àwọn àṣeyọrí ọmọ èèyàn kan ṣe lè gbé ògo àwọn òbí rẹ̀ yọ náà ni ìwà ìdúróṣinṣin Jésù ṣe mú kí òkìkí rẹ̀ kàn láàárín gbogbo ẹ̀dá “fún ògo Ọlọ́run Baba.” Ìyẹn ni Jòhánù fi ń bá a lọ láti ròyìn pé: “Àti gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé àti lórí òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé: ‘Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni kí ìbùkún àti ọlá àti ògo àti agbára ńlá wà fún títí láé àti láéláé.’”—Ìṣípayá 5:13.
23, 24. (a) Kí ló jẹ́ ká mọ ìgbà tí orin ìyìn yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? (b) Báwo ni ìró ohùn orin ìyìn náà ṣe ń lọ sókè sí i bí ọdún ti ń gorí ọdún?
23 Ìgbà wo ni ìró orin ìyìn gíga lọ́lá tó sì bùáyà yìí dún jáde? Apá ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa ló bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà tí a lé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jáde ní ọ̀run ni “gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ ní ọ̀run” lè jùmọ̀ fi ìṣọ̀kan kọ orin ìyìn yìí. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ sì ti fi hàn, látọdún 1919 ni ògìdìgbó èèyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé ti fi ìṣọ̀kan pa ohùn pọ̀ nínú yíyin Jèhófà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i láti orí ẹgbẹ̀rún díẹ̀ ní ìgbà náà dé iye tó ju mílíọ̀nù mẹ́fà lọ dáadáa ní ọdún 2005.b Lẹ́yìn tí a bá ti wá pa ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé run, “gbogbo ẹ̀dá . . . lórí ilẹ̀ ayé” yóò máa kọ orin ìyìn Jèhófà àti ti Ọmọ rẹ̀. Ní àkókò yíyẹ lójú Jèhófà, àjíǹde àìlóǹkà ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òkú yóò bẹ̀rẹ̀, nígbà náà “gbogbo ẹ̀dá . . . nísàlẹ̀ ilẹ̀ ayé” tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run yóò wá láǹfààní láti nípìn-ín nínú kíkọ orin ìyìn náà.
24 Ní báyìí pàápàá, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn “láti ìkángun ilẹ̀ ayé . . . òkun àti . . . erékùṣù,” ń kọ orin tuntun kan bí wọ́n ṣe ń wá sínú ètò Jèhófà kárí ayé. (Aísáyà 42:10; Sáàmù 150:1-6) Orin ìyìn aláyọ̀ yìí yóò dún dókè pátápátá rẹ̀ ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìjọba Kristi, nígbà tí a óò ti mú aráyé dé ipò ìjẹ́pípé. Sátánì, ejò ògbólógbòó nì, olórí atannijẹ, ni a óò pa run lẹ́yìn náà láti mú ọ̀rọ̀ Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣẹ délẹ̀. Nígbà yẹn, gbogbo ẹ̀dá alààyè, yálà ẹ̀dá ẹ̀mí tàbí ẹ̀dá èèyàn, yóò wá fi ayọ̀ kọrin ìṣẹ́gun ní ìṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀, pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni kí ìbùkún àti ọlá àti ògo àti agbára ńlá wà fún títí láé àti láéláé.” Nígbà náà, kò ní sí ohùn ẹnikẹ́ni tó máa yapa rárá láyé àtọ̀run.
25. (a) Kí ni kíka àkọsílẹ̀ Jòhánù nípa orin ìyìn yìí mú ká ṣe? (b) Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti alàgbà mẹ́rìnlélógún náà fi lélẹ̀ fún wa bí ìran náà ṣe fẹ́ parí?
25 Ẹ wo bí ìgbà náà yóò ṣe jẹ́ àkókò aláyọ̀ tó! Dájúdájú, ohun tí Jòhánù ṣàpèjúwe níhìn-ín mú kí ọkàn wa kún fún ayọ̀, ó sì mórí wa yá gágá láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run ní kíkọ àwọn orin ìyìn àtọkànwá sí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. Ǹjẹ́ èyí kò mú ká túbọ̀ pinnu ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé a ó máa bá àwọn iṣẹ́ rere nìṣó? Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè retí pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, kálukú wa yóò wà níbẹ̀ nígbà ìparí rẹ̀ aláyọ̀, tí a ó jọ kọ orin ìyìn tí yóò gba gbogbo ayé àtọ̀run. Dájúdájú, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó jẹ́ kérúbù wọnnì àti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí a ti jí dìde jọ fohùn ṣọ̀kan pátápátá, nítorí bí ìran náà ṣe parí ni pé: “Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà sì ń wí pé: ‘Àmín!’ àwọn alàgbà náà sì wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn.”—Ìṣípayá 5:14.
26. A ní láti lo ìgbàgbọ́ nínú kí ni, kí sì ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ti ṣe tán láti ṣe?
26 Ǹjẹ́ kí ìwọ òǹkàwé wa ọ̀wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn nì, tó jẹ́ ‘ẹni yíyẹ’ náà, kó o sì gba ìbùkún bí o ṣe ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sapá láti máa sin Jèhófà, “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́” náà. Jẹ́ kí ẹgbẹ́ Jòhánù ràn ọ́ lọ́wọ́ lónìí bí wọ́n ṣe ń pèsè “ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Lúùkù 12:42) Ṣùgbọ́n, wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ti ṣe tán láti ṣí èdìdì méjèèje. Àwọn ìṣípayá tó wúni lórí wo la máa rí nísinsìnyí?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tá a bá fojú gírámà wo ọ̀rọ̀ náà “olúkúlùkù wọn ní háàpù kan lọ́wọ́ àti àwokòtò wúrà tí ó kún fún tùràrí,” ó lè tọ́ka sí àwọn alàgbà àti ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà pa pọ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tá à ń bá bọ̀ ká tó kan gbólóhùn náà jẹ́ kó ṣe kedere pé alàgbà mẹ́rìnlélógún náà nìkan lọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí.
b Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ewé 64.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 86]
-