-
Ṣíṣèdájọ́ Aṣẹ́wó Burúkú NáàÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
Orí 33
Ṣíṣèdájọ́ Aṣẹ́wó Burúkú Náà
Ìran 11—Ìṣípayá 17:1-18
Ohun tó dá lé: Bábílónì Ńlá gun ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó wá yí padà lòdì sí i nígbẹ̀yìngbẹ́yín tó sì pa á run
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Láti 1919 títí di ìgbà ìpọ́njú ńlá
1. Kí ni ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì méje náà ṣí payá fún Jòhánù?
GBOGBO ìbínú òdodo Jèhófà tó wà nínú àwokòtò méjèèje la gbọ́dọ̀ dà jáde pátápátá! Nígbà tí áńgẹ́lì kẹfà da ohun tó wà nínú àwokòtò rẹ̀ jáde sí ibi tí Bábílónì ìgbàanì wà, ó jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìyọnu ṣe máa bá Bábílónì Ńlá, bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì ṣe ń yára kánkán ṣẹlẹ̀. (Ìṣípayá 16:1, 12, 16) Nísinsìnyí, ó dà bíi pé, áńgẹ́lì yìí kan náà ló ń ṣí ìdí tí Jèhófà fi ń mú àwọn ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣẹ àti bó ṣe ń mú un ṣẹ payá. Kàyéfì ṣe Jòhánù torí ohun tó gbọ́ tó sì rí lẹ́yìn ìyẹn, ó ní: “Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní àwokòtò méje lọ́wọ́ sì wá, ó sì bá mi sọ̀rọ̀, pé: ‘Wá, èmi yóò fi ìdájọ́ lórí aṣẹ́wó ńlá tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ hàn ọ́, ẹni tí àwọn ọba ilẹ̀ ayé bá ṣe àgbèrè, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ń gbé ilẹ̀ ayé ni a ti mú kí wọ́n mu wáìnì àgbèrè rẹ̀ ní àmupara.’”—Ìṣípayá 17:1, 2.
2. Ẹ̀rí wo ló wà pé “aṣẹ́wó ńlá náà” (a) kì í ṣe Róòmù ìgbàanì? (b) kì í ṣe iṣẹ́ ajé aládàá ńlá? (d) jẹ́ ètò ìsìn?
2 “Aṣẹ́wó ńlá náà”! Kí nìdí tí orúkọ náà fi burú tó bẹ́ẹ̀? Ta ni obìnrin náà? Àwọn kan sọ pé Róòmù ìgbàanì ni aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ yìí. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè olóṣèlú ni Róòmù. Aṣẹ́wó yìí ń bá àwọn ọba ilẹ̀ ayé ṣàgbèrè, ó sì hàn gbangba pé àwọn ọba Róòmù wà nínú èyí. Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn ìparun rẹ̀, “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” ni Ìwé Mímọ́ sọ pé wọ́n ṣọ̀fọ̀ lórí ikú rẹ̀. Nítorí náà, obìnrin náà kò lè jẹ́ ètò ìṣèlú. (Ìṣípayá 18:9, 10) Ní àfikún, níwọ̀n bí àwọn oníṣòwò ayé ti ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, obìnrin náà kò lè ṣàpẹẹrẹ iṣẹ́ ajé aládàá ńlá. (Ìṣípayá 18:15, 16) Àmọ́ Bíbélì sọ pé ‘àwọn ìṣe ìbẹ́mìílò rẹ̀ ti ṣi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà.’ (Ìṣípayá 18:23) Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé aṣẹ́wó ńlá náà ní láti jẹ́ ètò ìsìn tó kárí ayé.
3. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ohun tí aṣẹ́wó ńlá náà dúró fún gbọ́dọ̀ ju ìjọ Kátólíìkì tàbí gbogbo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lọ? (b) Àwọn ẹ̀kọ́ Bábílónì wo là ń rí nínú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìsìn Ìlà Oòrùn àtàwọn ẹ̀ya ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì? (d) Kí ni kádínà ìjọ Kátólíìkì náà John Henry Newman sọ nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́, ayẹyẹ, àtàwọn àṣà ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
3 Ìsìn wo ni obìnrin yìí dúró fún? Ṣé ìjọ Kátólíìkì ni, bí àwọn kan ṣe sọ? Àbí gbogbo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló dúró fún? Rárá o. Ó gbọ́dọ̀ tóbi ju àwọn wọ̀nyí lọ bó bá máa lágbára láti ṣi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà. Ní tòótọ́, ó jẹ́ ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, ìyẹn gbogbo ìsìn èké lápapọ̀. Ohun tó fi hàn pé inú àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Bábílónì ló ti pilẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àtàwọn àṣà Bábílónì wọ́pọ̀ láàárín àwọn ìsìn jákèjádò ayé. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìsìn Ìlà Oòrùn àtàwọn ẹ̀ya ìsìn Ṣọ́ọ̀ṣì ló gbà gbọ́ pé ẹ̀dá èèyàn ti jogún ọkàn tí kì í kú, pé iná ọ̀run àpáàdì wà àti pé ọlọ́run mẹ́talọ́kan wà. Ìsìn èké, tó ti wà láti ohun tó lé ní ẹgbàajì [4,000] ọdún sẹ́yìn ní ìlú Bábílónì ìgbàanì, ti di ohun àràmàǹdà òde òní tá a mọ̀ sí Bábílónì Ńlá.a Àmọ́, kí nìdí tó fi jẹ́ pé orúkọ tó ń kóni nírìíra náà, “aṣẹ́wó ńlá” ni Ìwé Mímọ́ fi ṣàpèjúwe rẹ̀?
4. (a) Báwo ni Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe ṣe àgbèrè? (b) Ọ̀nà títayọ wo ni Bábílónì Ńlá gbà ṣe àgbèrè?
4 Àkókò Nebukadinésárì ni ògo Bábílónì (tàbí Bábélì, tó túmọ̀ sí “Ìdàrúdàpọ̀”) dé òtéńté rẹ̀. Ó jẹ́ ilẹ̀ tí ọ̀rọ̀ ìsìn àti ìṣèlú ti wọnú ara wọn gan-an, níbi tí àwọn tẹ́ńpìlì àtàwọn ilé ìsìn kéékèèké tó lé ní ẹgbẹ̀rún wà. Àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀ lágbára gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí Bábílónì ti dẹ́kun jíjẹ́ agbára ayé, Bábílónì Ńlá tó jẹ́ ètò ìsìn ṣì wà, àti pé bíi ti Bábílónì ìgbàanì, ó ṣì ń wá ọ̀nà láti darí bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ètò ìṣèlú. Ṣùgbọ́n ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí dída ọ̀rọ̀ ìsìn mọ́ ìṣèlú? Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, Bíbélì sọ pé Ísírẹ́lì sọ ara rẹ̀ di kárùwà nígbà tó lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké, tó sì lọ bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní àjọṣepọ̀, dípò kó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. (Jeremáyà 3:6, 8, 9; Ìsíkíẹ́lì 16:28-30) Bábílónì Ńlá pẹ̀lú ń ṣe àgbèrè. Àní ọ̀ràn tiẹ̀ ta yọ ní ti pé ó ti ṣe ohunkóhun yòówù tó bá rí i pé ó pọn dandan kó bàa lè máa darí àwọn ọba tó ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé, kó sì máa lo agbára rẹ̀ lórí wọn.—1 Tímótì 4:1.
5. (a) Kí làwọn àlùfáà ìsìn máa ń fẹ́ káwọn èèyàn rí wọn pé àwọn ń ṣe? (b) Kí nìdí tí ìfẹ́ fún jíjẹ́ gbajúmọ̀ nínú ayé fi ta ko àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Kristi ní tààràtà?
5 Lónìí, ńṣe làwọn olórí ìsìn máa ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè di ipò gíga mú nínú ìjọba, láwọn ilẹ̀ kan sì rèé, àwọn àtàwọn olóṣèlú ni wọ́n jọ ń ṣèjọba, àní wọ́n tiẹ̀ tún ń ní ipò nínú ìgbìmọ̀ alábẹ-ṣékélé ìjọba. Lọ́dún 1988, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì méjì táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ló díje fún ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn aṣáájú nínú Bábílónì Ńlá fẹ́ràn káwọn èèyàn máa rí wọn ṣáá; ọ̀pọ̀ ìgbà ni fọ́tò bí wọ́n ṣe ń ṣe wọlé-wọ̀de pẹ̀lú àwọn gbajúmọ̀ olóṣèlú máa ń wà nínú àwọn ìwé ìròyìn. Àmọ́ ti Jésù ò rí bẹ́ẹ̀ rárá o, ńṣe ló kẹ̀yìn sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú pátápátá, ó sì sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.”—Jòhánù 6:15; 17:16; Mátíù 4:8-10; tún wo Jákọ́bù 4:4 pẹ̀lú.
‘Iṣẹ́ Aṣẹ́wó’ Òde Òní
6, 7. (a) Báwo ni Ẹgbẹ́ Násì ti Hitler ṣe dé orí àlééfà ní Jámánì? (b) Báwo ni àdéhùn ìmùlẹ̀ tí Póòpù ṣe pẹ̀lú ilẹ̀ Jámánì tí ìjọba Násì ń ṣàkóso ṣe ran Hitler lọ́wọ́ nínú gbogbo akitiyan rẹ̀ láti ṣàkóso lórí ayé?
6 Nípasẹ̀ àtojúbọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìṣèlú, aṣẹ́wó ńlá náà ti kó aráyé sínú ìbànújẹ́ tí kò ṣeé fẹnu sọ. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ kó tó di pé Hitler gorí àlééfà ní Jámánì. Àwọn ohun wọ̀nyẹn burú débi pé ì bá wu àwọn kan pé kí wọ́n pa á rẹ́ pátápátá kúrò nínú àwọn ìwé ìtàn. Ní May 1924, aṣojú méjìlélọ́gbọ̀n ni Ẹgbẹ́ Násì ní nínú Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Jámánì. Nígbà tó fi máa di May 1928, ìwọ̀nyí ti dín kù sí méjìlá. Àmọ́, ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lágbàáyé lọ́dún 1930; ẹgbẹ́ Násì sì lo àǹfààní yìí láti yára kọ́fẹ padà, tó fi di pé ẹgbẹ́ náà ní igba ó lé ọgbọ̀n [230] aṣojú lára ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ [608] aṣojú nígbà táwọn èèyàn Jámánì dìbò ní July 1932. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, olórí ìjọba tẹ́lẹ̀ rí Franz von Papen, ẹni tí póòpù ti fi oyè Ajagungboyè dá lọ́lá, dìde fún ìrànlọ́wọ́ Ẹgbẹ́ Násì. Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn ti wí, von Papen ní àfojúsùn pé Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ á di àkọ̀tun. Òtúbáńtẹ́ ni gbogbo ohun tó ṣe níwọ̀nba àkókò kúkúrú tó fi jẹ́ olórí ìjọba já sí, nítorí náà nísinsìnyí ó ń wá bí agbára tún ṣe máa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn Násì. Nígbà tó fi máa di January 1933, ó ti sún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀gá láwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá láti gbárùkù ti Hitler. Ó sì tún lo ọgbọ́n àrékérekè láti rí i dájú pé Hitler di olórí ìjọba ní January 30, 1933. Wọ́n fi òun fúnra rẹ̀ ṣe igbá kejì olórí ìjọba, Hitler sì lò ó láti wá ìtìlẹyìn àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì nílẹ̀ Jámánì. Láàárín oṣù méjì tí Hitler gba agbára, Hitler tú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ká, ó fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ alátakò ránṣẹ́ sí àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ láìjáfara, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn Júù lórí ba ní gbangba gbàǹgbà.
7 Ní July 20, 1933, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fi hàn pé Vatican, ìyẹn Ìjọba Póòpù, nífẹ̀ẹ́ sí agbára Ìjọba Násì tó ń pọ̀ sí i. Lọ́jọ́ náà, nílùú Róòmù, Kádínà Pacelli (ẹni tó wá di Póòpù Pius Kejìlá lẹ́yìn náà) fọwọ́ sí ìwé àdéhùn ìmùlẹ̀ kan láàárín Vatican àti ilẹ̀ Jámánì tí ìjọba Násì ń ṣàkóso. Von Papen fọwọ́ sí ìwé náà gẹ́gẹ́ bí aṣojú Hitler, ibẹ̀ ni Pacelli sì ti fi oyè pàtàkì kan tí póòpù fi ń dáni lọ́lá, ìyẹn òye Àgbélébùú Títóbilọ́lá ti Ẹgbẹ́ Piusb dá von Papen lọ́lá. Nínú ìwé tí Tibor Koeves kọ tó pè ní Satan in Top Hat, ó sọ̀rọ̀ nípa èyí, ó ní: “Àdéhùn Ìmùlẹ̀ náà jẹ́ ìjagunmólú fún Hitler. Àdéhùn yẹn ni ìtìlẹyìn tó kọ́kọ́ rí gbà láti ibòmíràn yàtọ̀ sí ilẹ̀ Jámánì, èyí sì wá láti orísun tó ga jù lọ láyé.” Ohun tí àdéhùn ìmùlẹ̀ náà béèrè fún ni pé kí Póòpù yọwọ́ ìtìlẹyìn rẹ̀ kúrò nínú ẹgbẹ́ Catholic Center Party ti Jámánì, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ fohùn sí “ìjọba apàṣẹwàá”c Hitler tó jẹ́ ẹgbẹ́ kan ṣoṣo. Síwájú sí i, ìpínrọ̀ kẹrìnlá nínú àdéhùn náà sọ pé: “Ó dìgbà tí gómìnà tí Ìjọba Násì fi jẹ bá ti rí i dájú ṣáká pé kò sí iyèméjì kankan nípa bóyá kò ní sí wàhálà ìṣèlú kí wọ́n tó lè yan àwọn olórí bíṣọ́ọ̀bù, àwọn bíṣọ́ọ̀bù, àtàwọn bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sípò.” Ní òpin ọdún 1933 (tí Póòpù Pius Kọkànlá pè ní “Ọdún Mímọ́”), ìtìlẹyìn Ìjọba Póòpù ti di ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó mú kí gbogbo akitiyan Hitler láti ṣàkóso lórí ayé ṣeé ṣe.
8, 9. (a) Kí ni Ìjọba Póòpù àti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti àwọn àlùfáà rẹ̀ ṣe sí ìwà ìkà Násì? (b) Kí làwọn bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì ní Jámánì sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì? (d) Kí làjọṣe tó wà láàárín ìsìn àti ìṣèlú ti yọrí sí?
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba kéréje lára àwọn àlùfáà àtàwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé fi ẹ̀hónú wọn hàn sí ìwà ìkà Hitler tí ìyà sì jẹ wọ́n nítorí ẹ̀, ibùjókòó Ìjọba Póòpù àti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlùfáà wọn ṣètìlẹyìn fún ìwà ìkà ìjọba Násì, èyí tí wọ́n kà sóhun tí ò ní jẹ́ kí ìjọba Kọ́múníìsì ayé rọ́wọ́ mú kárí ayé. Wọ́n ń ṣètìlẹyìn fún ìjọba Násì, bóyá ní tààràtà tàbí lábẹ́lẹ̀. Ńṣe ni Póòpù Pius Kejìlá jókòó gbẹdẹmukẹ ní ibùjókòó rẹ̀, tó ń wo bí wọ́n ṣe ń fẹ́ pa àwọn Júù run àti bí wọ́n ṣe ń ṣe inúnibíni oníwà ìkà sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn mìíràn, kò sì sọ pé ohun tí ìjọba ń ṣe ò dáa. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó yani lẹ́nu pé nígbà tí Póòpù John Paul Kejì ń ṣèbẹ̀wò sí Jámánì ní May 1987, ó gbóṣùbà fún àlùfáà olóòótọ́ inú kan torí bí kò ṣe gbè sẹ́yìn ìjọba Násì. Kí ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àlùfáà Jámánì yòókù ń ṣe lákòókò ìjọba Hitler tó ń kó ìpayà bá àwọn èèyàn? Lẹ́tà kan táwọn bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì ilẹ̀ Jámánì kọ sáwọn olùre ṣọ́ọ̀ṣì ní September 1939, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀ ṣàlàyé lórí kókó yìí. Ó kà lápá kan pé: “Ní wákàtí tọ́rọ̀ ti dojú ọ̀gbagadè yìí, a gba àwọn ọmọ ogun wa ní Kátólíìkì níyànjú pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ nípa gbígbọ́ràn sí Hitler Abàṣẹwàá lẹ́nu kí wọ́n sì múra tán láti fi gbogbo ara wọn fún ogun yìí. A rọ àwọn ọmọ ìjọ láti dara pọ̀ nínú àdúrà gbígbóná janjan pé kí Ọlọ́run bá wa lọ́wọ́ sí ogun yìí kó lè yọrí sí rere kó sì bù kún un.”
9 Irú ọgbọ́n mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń lò nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú ètò ìṣèlú jẹ́ ká rí bí ìsìn ti ṣe ń ṣe aṣẹ́wó láti ẹgbàajì [4,000] ọdún sẹ́yìn, tí wọ́n ń fa ojú Ìjọba elétò òṣèlú mọ́ra kí wọ́n lè ní agbára, kí wọ́n sì rí àǹfààní jẹ. Irú àwọn àjọṣe tó wà láàárín ìsìn àti ìṣèlú bẹ́ẹ̀ ti ṣokùnfà ogun àti inúnibíni, ó sì ti kó ìnira tó bùáyà bá ẹ̀dá èèyàn. Ẹ wo bí aráyé á ti láyọ̀ tó, pé ìdájọ́ Jèhófà lórí aṣẹ́wó ńlá náà kù sí dẹ̀dẹ̀. Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run mú ìdájọ́ náà wá láìpẹ́!
Ó Jókòó Lórí Omi Púpọ̀
10. Kí ni “omi púpọ̀” tí Bábílónì Ńlá fi ṣe ààbò, kí ló sì ń ṣẹlẹ̀ sí wọn?
10 Bábílónì ìgbàanì jókòó lórí omi púpọ̀, ìyẹn ni Odò Yúfírétì àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ipa odò. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ ààbò fún un, wọ́n sì tún jẹ́ ibi tí owó ń bá wọlé fún un tó fi jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni, kó tó di pé wọ́n gbẹ táútáú lóru ọjọ́ kan. (Jeremáyà 50:38; 51:9, 12, 13) Bábílónì Ńlá pẹ̀lú ń wojú “omi púpọ̀” láti dáàbò bò ó kó sì sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀. Omi ìṣàpẹẹrẹ yìí ni “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n,” ìyẹn gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún mílíọ̀nù èèyàn tó ń jọba lé lórí tó sì ti gba àwọn ohun ìní tara lọ́wọ́ wọn. Ṣùgbọ́n àwọn omi wọ̀nyí náà ti ń gbẹ lọ, tó túmọ̀ sí pé wọ́n ti ń fawọ́ ìtìlẹyìn wọn sẹ́yìn.— Ìṣípayá 17:15; fi wé Sáàmù 18:4; Aísáyà 8:7.
11. (a) Báwo ni Bábílónì ìgbàanì ṣe ‘mú kí gbogbo ilẹ̀ ayé mu àmupara’? (b) Báwo ni Bábílónì Ńlá ṣe ‘mú kí gbogbo ilẹ̀ ayé mu àmupara’?
11 Síwájú sí i, Bíbélì tún ṣàpèjúwe Bábílónì ìgbàanì gẹ́gẹ́ bí “ife wúrà ní ọwọ́ Jèhófà, ó ń mú kí gbogbo ilẹ̀ ayé mu àmupara.” (Jeremáyà 51:7) Bábílónì ìgbàanì mú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà nítòsí rẹ̀ tipátipá láti gbé àwọn ohun tó ń fi ìbínú Jèhófà hàn mì nípa ṣíṣẹ́gun wọn lójú ogun, tó sọ wọ́n di aláìlera bí ọ̀mùtípara. Lọ́nà yẹn, ó jẹ́ ohun èlò Jèhófà. Bábílónì Ńlá náà ti ja àjàṣẹ́gun débi pé ó ti di ilẹ̀ ọba tó kárí ayé. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé òun kì í ṣe ohun èlò Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti sin “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” tó ń bá ṣe àgbèrè ìsìn. Ó ti ṣe ohun táwọn ọba wọ̀nyí fẹ́ nípa lílo àwọn ẹ̀kọ́ èké rẹ̀ àtàwọn àṣà tó ń sọ àwọn èèyàn dẹrú láti fi sọ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ “àwọn tí ń gbé ilẹ̀ ayé” di aláìlera gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtípara, àwọn tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn ń ṣe ohunkóhun táwọn alákòóso wọn bá sọ fún wọn láìjanpata rárá.
12. (a) Báwo ni ẹ̀ka Bábílónì Ńlá kan ní Japan ṣe fa ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì? (b) Báwo la ṣe fa “àwọn omi” tó ń ṣètìlẹyìn fún Bábílónì Ńlá gbẹ ní Japan, kí sì ni èyí yọrí sí?
12 Àpẹẹrẹ kan tó hàn gbangba lórí ọ̀ràn yìí ni ilẹ̀ Japan tó jẹ́ ibi tí ìsìn Ṣintó ti ṣẹ̀ wá. Àwọn ọmọ ogun Japan tí wọ́n ti gbin èrò òdì sí lọ́kàn kà á sí ọlá gíga jù lọ láti fi ẹ̀mí wọn rúbọ fún olú ọba, ẹni tó jẹ́ ọlọ́run ìsìn Ṣintó tó ga jù lọ. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan ààbọ̀ [1,500,000] ọmọ ogun Japan ló kú lójú ogun; ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ka títúúbá sí nǹkan àbùkù. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun Japan, ó di dandan fún Olú Ọba Hirohito láti kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ pé òun jẹ́ ọlọ́run. Èyí yọrí sí fífa “àwọn omi” tí ń ṣètìlẹyìn fún ẹ̀ka Ṣintó nínú Bábílónì Ńlá gbẹ lọ́nà kíkàmàmà. Ó mà ṣe o, èyí jẹ́ lẹ́yìn tí ìsìn Ṣintó ti lóhùn sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ lójú ogun ní Pàsífíìkì! Bí ìsìn Ṣintó ò ṣe lágbára mọ́ yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún ohun tó ju ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] àwọn ará Japan, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ onísìn Ṣintó àti onísìn Búdà tẹ́lẹ̀ rí, láti ya ara wọn sí mímọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣèrìbọmi, wọ́n sì di òjíṣẹ́ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.
Aṣẹ́wó Náà Gun Ẹranko Kan
13. Ìran tí ń ṣeni ní kàyéfì wo ni Jòhánù rí nígbà tí áńgẹ́lì náà fi agbára ẹ̀mí gbé e lọ sínú aginjù?
13 Kí ló tún kù tí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣí payá nípa aṣẹ́wó ńlá náà àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i? Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ti sọ nísinsìnyí, ìran mìíràn tó hàn ketekete tún wá sí ojútáyé òun ni pé: “Ó [ìyẹn áńgẹ́lì náà] sì gbé mi nínú agbára ẹ̀mí lọ sínú aginjù kan. Mo sì tajú kán rí obìnrin kan tí ó jókòó lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí ó kún fún àwọn orúkọ ọ̀rọ̀ òdì, tí ó sì ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.”—Ìṣípayá 17:3.
14. Kí nìdí tó fi yẹ wẹ́kú pé áńgẹ́lì gbé Jòhánù lọ sínú aginjù?
14 Kí nìdí tí áńgẹ́lì fi gbé Jòhánù lọ sínú aginjù? Ìkéde ìṣáájú nípa ìparun Bábílónì ìgbàanì ni Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí èyí tó wà “lòdì sí aginjù òkun.” (Aísáyà 21:1, 9) Èyí jẹ́ ìkìlọ̀ pé, láìka gbogbo omi tó fi ń dáàbò bo ara rẹ̀ sí, Bábílónì ìgbàanì yóò di ahoro láìní olùgbé kankan. Abájọ tí áńgẹ́lì fi gbé Jòhánù lọ sí aginjù kan nínú ìran kó lè rí òpin Bábílónì Ńlá. Bábílónì Ńlá náà gbọ́dọ̀ di ahoro àti òfìfo. (Ìṣípayá 18:19, 22, 23) Àmọ́, ohun tí Jòhánù rí níbẹ̀ ṣe é ní kàyéfì. Aṣẹ́wó ńlá náà kò dá wà ní òun nìkan o! Orí abàmì ẹranko ẹhànnà kan ló jókòó lé!
15. Àwọn ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ẹranko ẹhànnà ti Ìṣípayá 13:1 àti ti Ìṣípayá 17:3?
15 Ẹranko ẹhànnà yìí ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. Àmọ́, ṣé ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ẹranko ẹhànnà tí Jòhánù kọ́kọ́ rí, èyí tí òun pẹ̀lú ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá? (Ìṣípayá 13:1) Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìyàtọ̀ wà láàárín wọn. Ẹranko ẹhànnà kejì yìí jẹ́ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, àti pé, láìdà bí ẹranko ẹhànnà ìṣáájú, Jòhánù kò sọ pé ó ní adé dáyádémà. Orí ẹ̀ méjèèje nìkan kọ́ làwọn orúkọ ọ̀rọ̀ òdì wà, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni gbogbo ara rẹ̀ “kún fún àwọn orúkọ ọ̀rọ̀ òdì.” Àmọ́ láìka èyí sí, nǹkan kan gbọ́dọ̀ da ẹranko ẹhànnà tuntun yìí àti ti àkọ́kọ́ pọ̀; ìjọra tó wà láàárín wọn pọ̀ débi pé kò lè jẹ́ pé wọ́n ṣèèṣì jọra ni.
16. Kí lohun tí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jẹ́, kí sì nìdí tí wọ́n sọ pé wọ́n fi dá a sílẹ̀?
16 Kí wá ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tuntun yìí? Ó ní láti jẹ́ pé òun ni ère ẹranko ẹhànnà tí wọ́n mú jáde látàrí ìsapá ẹranko ẹhànnà tó ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, èyí tó dúró fún agbára ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe ère náà, ẹranko ẹhànnà oníwo méjì yẹn ni a yọ̀ǹda fún láti fi èémí fún ère ẹranko ẹhànnà náà. (Ìṣípayá 13:14, 15) Nísinsìnyí Jòhánù wá rí ère tó wà lóòyẹ̀, tí ń mí. Ó ṣàpẹẹrẹ àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà mú wá sí ìyè lọ́dún 1920. Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà, Wilson, ti fọkàn yàwòrán pé àjọ Ìmùlẹ̀ náà “yóò jẹ́ ibi ìjíròrò fún mímú kí wọ́n máa ṣe ẹ̀tọ́ fún gbogbo èèyàn, yóò sì fòpin sí ogun títí láé.” Nígbà tí wọ́n jí àjọ náà dìde lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì gẹ́gẹ́ bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìdí tí wọ́n fi dá a sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé àṣẹ ìdásílẹ̀ ni “láti rí i pé àlàáfíà àti ààbò wà lágbàáyé.”
17. (a) Báwo ni ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ṣe kún fún orúkọ ọ̀rọ̀ òdì? (b) Ta ló ń gun ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà? (d) Báwo ni ìsìn Bábílónì ṣe dara pọ̀ mọ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti arọ́pò rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀?
17 Báwo ni ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ yìí ṣe kún fún orúkọ ọ̀rọ̀ òdì? Bó ṣe kún fún ọ̀rọ̀ òdì ni pé àwọn èèyàn ti gbé ohun tó dà bí òrìṣà ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yìí kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arọ́pò Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n ní òun ló máa ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé Ìjọba òun nìkan ló lè ṣe é. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 12:18, 21) Àmọ́, ohun tó pẹtẹrí nípa ìran tí Jòhánù rí ni pé Bábílónì Ńlá ń gun ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, ìsìn Bábílónì, pàápàá ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ti dara pọ̀ mọ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti arọ́pò rẹ̀. Nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, ìyẹn December 18, 1918, ẹgbẹ́ tí a wá mọ̀ sí Ìgbìmọ̀ Àpapọ̀ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristi ní Amẹ́ríkà tẹ́wọ́ gba ìpolongo kan tó sọ lápá kan pé: “Irú Ìmùlẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í wulẹ̀ ṣe ètò ìṣèlú kan tá a kàn gbé kalẹ̀ nítorí àǹfààní ojú ẹsẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ ìfihàn Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà ìṣèlú lórí ilẹ̀ ayé. . . . Ṣọ́ọ̀ṣì lè fúnni ní ẹ̀mí ìfẹ́ inú rere, èyí tó jẹ́ pé láìsí i, kò sí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó lè wà pẹ́ títí. . . . Ńṣe ni Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ìhìn Rere. Bíi ti Ìhìn Rere, ohun tó mú kí wọ́n dá a sílẹ̀ ni ‘àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé, ìfẹ́ inú rere sí àwọn ènìyàn.’”
18. Báwo làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ṣe fi ìtìlẹyìn wọn hàn fún Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè?
18 Ní January 2, 1919, ìwé ìròyìn náà, San Francisco Chronicle, gbé àkọlé kan jáde ní ojú ìwé àkọ́kọ́ pé: “Póòpù Jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún Ìtẹ́wọ́gbà Ìgbìmọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí Wilson Dábàá.” Ní October 16, 1919, wọ́n gbé ìwé ìbéèrè kan síwájú Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó rọ ìgbìmọ̀ náà “láti fọwọ́ sí àdéhùn àlàáfíà ti Paris èyí tó ní májẹ̀mú ìmùlẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè nínú.” Ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àti irínwó ó lé àádọ́ta [14,450] àlùfáà látinú àwọn ẹ̀ka ìsìn tó yọrí ọlá jù ló fọwọ́ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kò fọwọ́ sí àdéhùn náà, ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kò jáwọ́ nínú akitiyan wọn láti fi àjọ Ìmùlẹ̀ náà lọ́lẹ̀. Báwo ni wọ́n sì ṣe ṣayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ Ìmùlẹ̀ náà? Ìròyìn kan tí wọ́n fi ránṣẹ́ láìjáfara láti ilẹ̀ Switzerland, ní November 15, 1920, kà pé: “A ti kéde ṣíṣí àpèjọ àkọ́kọ́ ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní agogo mọ́kànlá òwúrọ̀ yìí nípa lílu aago gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ìlú Geneva.”
19. Nígbà tí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà fara hàn, kí ni ẹgbẹ́ Jòhánù ṣe?
19 Ǹjẹ́ ẹgbẹ́ Jòhánù, tó jẹ́ àwùjọ kan ṣoṣo lórí ilẹ̀ ayé tó fi ìháragàgà tẹ́wọ́ gba Ìjọba Mèsáyà tí ń bọ́ náà, bá àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lọ́wọ́ nínú jíjúbà ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà? Ká má rí i! Ní Sunday, September 7, 1919, J. F. Rutherford sọ àsọyé kan ní àpéjọ àwọn èèyàn Jèhófà ní Cedar Point, Ohio, èyí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ìrètí fún Ìran Aráyé Onídààmú.” Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, ìwé ìròyìn Star Journal ti ìlú Sandusky ròyìn pé nígbà tí J. F. Rutherford ń bá ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn sọ̀rọ̀, ó “polongo pé ó dájú pé ìbínú Olúwa ń bọ̀ lórí Ìmùlẹ̀ náà . . . nítorí pé àwùjọ àlùfáà—ti Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì—tí wọ́n sọ pé àwọn ni aṣojú Ọlọ́run, ti pa ìfẹ́ Ọlọ́run tì wọ́n sì ti fọwọ́ sí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí wọ́n ń kókìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìfihàn ìjọba Kristi lọ́nà ìṣèlú lórí ilẹ̀ ayé.”
20. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ òdì ni àwùjọ àlùfáà ń sọ bí wọ́n ṣe ń kókìkí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí “ìfihàn Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà ìṣèlú lórí ilẹ̀ ayé”?
20 Ó yẹ kí ìkùnà ẹ̀tẹ̀ tó bá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti jẹ́ kí àwùjọ àlùfáà mọ̀ pé irú àwọn àjọ tí ẹ̀dá èèyàn gbé kalẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe apá kan Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀rọ̀ òdì gbáà ni téèyàn bá ń sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Ó jẹ́ kó dà bíi pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí rádaràda ńláǹlà tí Ìmùlẹ̀ náà wá bá ara rẹ̀ nínú rẹ̀. Ní ti Ọlọ́run, “pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀.” Ìjọba ọ̀run tí Jèhófà gbé kalẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Kristi ni ohun èlò tí yóò tipasẹ̀ rẹ̀ mú àlàáfíà wá tí yóò sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀run, kì í ṣe nípasẹ̀ àjọṣepọ̀ àwọn olóṣèlú tí wọ́n bá ara wọn ta kàn-ǹ-gbàn, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́.—Diutarónómì 32:4; Mátíù 6:10.
21. Kí ló fi hàn pé aṣẹ́wó ńlá náà ń ṣètìlẹ́yìn fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó rọ́pò Ìmùlẹ̀ náà, tó sì ń kan sáárá sí i?
21 Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó rọ́pò Ìmùlẹ̀ náà ńkọ́? Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àjọ yìí ni aṣẹ́wó ńlá náà ti ń gùn ún, ní ti pé aṣẹ́wó ńlá náà dara pọ̀ mọ́ ọn lọ́nà tó hàn gbangba ó sì ń gbìyànjú láti dárí ọ̀ràn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní June 1965, nígbà tí wọ́n ń ṣàjọyọ̀ ogún ọdún tí wọ́n ti dá a sílẹ̀, àwọn aṣojú Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì àti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì, àwọn Júù, àwọn onísìn Híńdù, àwọn onísìn Búdà, àtàwọn Mùsùlùmí—tí wọ́n sọ pé wọ́n ṣojú fún bílíọ̀nù méjì [2,000,000,000] àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé—pé jọ sí ìlú San Francisco láti fi ìtìlẹyìn wọn àti oríyìn wọn hàn fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Nígbà tí Póòpù Paul Kẹfà ṣèbẹ̀wò sí iléeṣẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní October 1965, ó ṣàpèjúwe àjọ náà gẹ́gẹ́ bí “èyí tó tóbi jù lọ nínú gbogbo àwọn àjọ àgbáyé” ó sì fi kún un pé: “Àwọn èèyàn ayé yíjú sí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí ìrètí ìkẹyìn fún ìṣọ̀kan àti àlàáfíà.” Nígbà tí póòpù mìíràn tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, ìyẹn Póòpù John Paul Kejì, ń bá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ̀rọ̀ ní October 1979, ó ni: “Mo nírètí pé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè yóò máa fìgbà gbogbo jẹ́ àjọ táá máa ṣètò ìjíròrò gíga jù lọ fún àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo.” Ó jọni lójú pé agbára káká ni póòpù náà fi sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa Jésù Kristi tàbí Ìjọba Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The New York Times ṣe sọ, nígbà tí John Paul ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní September ọdún 1987, “ ó fi àkókò gígùn sọ̀rọ̀ nípa ipa rere tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń kó nínú gbígbé . . . ‘ìfọwọ́sowọ́pọ̀ kárí ayé tó jẹ́ àkọ̀tun’ lárugẹ.”
Orúkọ Kan, Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan
22. (a) Irú ẹranko wo ni aṣẹ́wó ńlá náà yàn láti gùn? (b) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ náà, Bábílónì Ńlá?
22 Àpọ́sítélì Jòhánù máa tó mọ̀ pé ẹranko eléwu ni ẹranko tí aṣẹ́wó ńlá náà yàn láti gùn. Àmọ́, ọ̀rọ̀ Bábílónì Ńlá fúnra rẹ̀ ló kọ́kọ́ sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe obìnrin náà lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì, síbẹ̀, ó kóni nírìíra gidigidi. Jòhánù ròyìn pe: “A sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò àti rírẹ̀dòdò ṣe obìnrin náà ní ọ̀ṣọ́, a sì fi wúrà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti àwọn péálì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, ó sì ní ife wúrà kan lọ́wọ́ rẹ̀ tí ó kún fún àwọn ohun ìríra àti àwọn ohun àìmọ́ àgbèrè rẹ̀. Àti sí iwájú orí rẹ̀ a kọ orúkọ kan, ohun ìjìnlẹ̀ kan: ‘Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.’ Mo sì rí i pé obìnrin náà ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Jésù ní àmupara.”—Ìṣípayá 17:4-6a.
23. Kí ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ orúkọ Bábílónì Ńlá, kí ló sì túmọ̀ sí?
23 Gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn ní Róòmù ìgbàanì, orúkọ tó wà ní iwájú orí kárùwà yìí la fi dá a mọ̀.d Orúkọ gígùn lorúkọ yẹn: “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.” Orúkọ yẹn jẹ́ “ohun ìjìnlẹ̀ kan,” ohun tí ìtumọ̀ rẹ̀ fara sin. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, àlàyé ohun ìjìnlẹ̀ yìí yóò wá sójútáyé. Ní tòótọ́, áńgẹ́lì náà ṣe àlàyé tó pọ̀ tó fún Jòhánù, tó lè jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí fòye mọ ohun tí orúkọ aṣàpèjúwe yìí túmọ̀ sí gan-an. A mọ̀ pé Bábílónì Ńlá ni gbogbo ìsìn èké lápapọ̀. Òun ni “ìyá àwọn aṣẹ́wó” nítorí pé ńṣe ni gbogbo àwọn ìsìn èké kọ̀ọ̀kan nínú ayé, títí kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀ya ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, dà bí ọmọbìnrin fún un, tí àwọn náà ń farawé wé e nínú ṣíṣe aṣẹ́wó nípa tẹ̀mí. Òun tún ni ìyá “àwọn ohun ìríra” ní ti pé ó ti bí àwọn ọmọ tó ń ríni lára gan-an, irú bí ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò, iṣẹ́ wíwò, ìwòràwọ̀, wíwo àtẹ́lẹwọ́, fífi èèyàn rúbọ, ṣíṣe kárùwà nínú tẹ́ńpìlì, fífi ọtí àmupara bọlá fún àwọn ọlọ́run èké, àtàwọn àṣàkaṣà mìíràn.
24. Kí nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú pé a wọ Bábílónì Ńlá ní aṣọ “aláwọ̀ àlùkò àti rírẹ̀dòdò,” a sì “fi wúrà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti àwọn péálì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́”?
24 Bábílónì Ńlá wọ aṣọ “aláwọ̀ àlùkò àti rírẹ̀dòdò,” ìyẹn àwọn àwọ̀ táwọn ọba máa ń lò, a sì “fi wúrà àti òkúta ṣíṣeyebíye àti àwọn péálì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.” Ó mà bá a mu o! Ṣáà ronú nípa gbogbo àwọn ilé ràgàjì, àwọn ère ìrántí àtàwọn àwòrán tó ṣọ̀wọ́n, àwọn ère ìsìn tó gbówó lórí gan-an, àtàwọn ohun èlò mìíràn tó jẹ́ ti ìsìn, pa pọ̀ pẹ̀lú owó gidi àti dúkìá tó pọ̀ jaburata, èyí táwọn ìsìn ayé yìí ti kó jọ rẹpẹtẹ. Yálà ní Ibùjókòó Póòpù ni o, tàbí lórí ètò ìjíhìnrere orí tẹlifíṣọ̀n tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni o, tàbí nínú àwọn wat, àtàwọn tẹ́ńpìlì àràmàǹdà ti Ìlà Oòrùn ni o, Bábílónì Ńlá ti to ọlà tó pabanbarì jọ gègèrè, ó sì ń pàdánù rẹ̀ nígbà míì.
25. (a) Kí làwọn ohun tó wà nínú “ife wúrà kan tí ó kún fún àwọn ohun ìríra” ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni mímu tí aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ náà mu àmupara túmọ̀ sí?
25 Nísinsìnyí, wá wo ohun tó wà lọ́wọ́ aṣẹ́wó náà. Ẹ̀rù ti gbọ́dọ̀ ba Jòhánù bó ṣe rí ohun kan, ìyẹn ni ife wúrà kan tó “kún fún àwọn ohun ìríra àtàwọn ohun àìmọ́ àgbèrè rẹ̀”! Èyí ni ife tí “wáìnì ìbínú àgbèrè rẹ̀” wà nínú rẹ̀, èyí tó fi mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè mu àmupara. (Ìṣípayá 14:8; 17:4) Ife náà fara hàn bí ohun tó dára lóde, ṣùgbọ́n àwọn ohun ìríra, ohun aláìmọ́ ló wà nínú rẹ̀. (Fi wé Mátíù 23:25, 26.) Gbogbo àwọn àṣà ẹlẹ́gbin àti irọ́ tí aṣẹ́wó ńlá náà ti lò láti yí àwọn orílẹ̀-èdè lérò padà àti láti mú wọn wá sábẹ́ agbára rẹ̀ ló wà nínú ife náà. Èyí tó tiẹ̀ túbọ̀ wá ríni lára ni pé, Jòhánù rí i pé aṣẹ́wó náà fúnra rẹ̀ ti yó kẹ́ri, ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní àmupara! Àní, ohun tí Bíbélì tún sọ níwájú ni pé “nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 18:24) Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ yìí mà pọ̀ o!
26. Ẹ̀rí wo ló wà pé Bábílónì Ńlá jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀?
26 Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ti ń ta ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Japan nígbà ojú dúdú, wọ́n sọ àwọn tẹ́ńpìlì ìlú Kyoto di ibi odi agbára, àwọn àlùfáà ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí wọ́n jẹ́ jagunjagun, tí wọ́n ń gbàdúrà ní “orúkọ mímọ́ Búdà,” sì ń bá ara wọn jà lẹ́nì kìíní-kejì títí àwọn ojú pópó fi pọ́n dẹ̀dẹ̀ fún ẹ̀jẹ̀. Ní ọ̀rúndún ogún, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì yan pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè wọn, àwọn ọmọ ogun yìí sì ń pa ara wọn nípakúpa, pẹ̀lú àdánù ẹ̀mí tó tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000,000], ó kéré tán. Ní October 1987, ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí Nixon sọ pé: “Ọ̀rúndún ogún yìí ni wọ́n tíì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ jù lọ rí. Àwọn èèyàn tó bógun lọ ní ọ̀rúndún yìí pọ̀ ju àwọn tó kú nínú gbogbo ogun tí wọ́n ti jà kí ọ̀rúndún yìí tó bẹ̀rẹ̀.” Ọlọ́run yóò dá àwọn ìsìn ayé lẹ́jọ́ nítorí ipa tí wọ́n kó nínú gbogbo èyí; Jèhófà kórìíra “ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 6:16, 17) Ṣáájú èyí, Jòhánù ti gbọ́ igbe kan láti ibi pẹpẹ: “Títí di ìgbà wo, Olúwa Ọba Aláṣẹ mímọ́ àti olóòótọ́, ni ìwọ ń fà sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣèdájọ́ àti gbígbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé?” (Ìṣípayá 6:10) Nígbà tí àkókò náà bá dé láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ọ̀rọ̀ náà á kan Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àtàwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé gbọ̀ngbọ̀n.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ìwé Essay on the Development of Christian Doctrine, èyí tí kádínà Roman Kátólíìkì ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún náà John Henry Newman kọ, ó fi hàn pé kì í ṣe inú ẹ̀sìn Kristẹni ni ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà, àwọn ayẹyẹ wọn àtàwọn àṣà tí wọ́n ń tẹ̀ lé ti wá. Ó wá ṣàlàyé pé: “Àtọ̀dọ̀ àwọn olórìṣà la ti kọ́ ìlò àwọn tẹ́ńpìlì tí a sì ya ìwọ̀nyí sí mímọ́ fún àwọn ẹni mímọ́ kan ní pàtó, tí a sì tún ń fi àwọn ẹ̀ka igi ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́ nígbà míì; tùràrí, fìtílà, àti àbẹ́là; ẹ̀jẹ́ sísan lẹ́yìn téèyàn bá ti rí ìwòsàn gbà; omi mímọ́; ilé ààbò; àwọn ọjọ́ àti àsìkò mímọ́, ìlò kàlẹ́ńdà, ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́rìn, àti ìsúre lórí pápá; aṣọ oyè àlùfáà, ìfárí oyè, òrùka ìgbéyàwó, yíyíjú sí Ìlà Oòrùn, ère táwọn Kristẹni wá ń lò lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, bóyá sísun rárà àlùfáà, àti orin Kyrie Eleison [ìyẹn orin “Olúwa, Ṣàánú fún Wa”]. Gbogbo wọn pátá la kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn olórìṣà, a sì sọ wọ́n di mímọ́ nípa lílò wọ́n nínú Ṣọ́ọ̀ṣì.”
“Jèhófà Olódùmarè” kò sọ irú ìbọ̀rìṣà bẹ́ẹ̀ di mímọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló sọ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀, . . . kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́ kan ohun àìmọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:14-18.
b Nínú ìwé ìtàn tí William L. Shirer kọ, tó pe àkọlé rẹ̀ ní The Rise and Fall of the Third Reich, ó ní “kò tún sẹ́lòmíì bíi ti [von Papen] nílẹ̀ Jámánì tó jẹ́ kí Hitler lè gorí àlééfà.” Ní January 1933, olórí ìjọba Jámánì tẹ́lẹ̀ rí, ọ̀gbẹ́ni von Schleicher ti sọ nípa von Papen pé: “Ó jẹ́ irú ọ̀dàlẹ̀ kan tó burú débi pé ẹni mímọ́ ni Júdásì Ísíkáríótù tá a bá fi àwọn méjèèjì wéra.”
c Nígbà tí Póòpù Pius Kọkànlá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Mondragone ní May 14, 1929, ó ní òun á bá Èṣù fúnra rẹ̀ dúnàádúrà bó bá pọn dandan fún àǹfààní àwọn èèyàn.
d Fi èyí wé ọ̀rọ̀ tí òǹkọ̀wé ará Róòmù náà Seneca sọ sí àlùfáà obìnrin kan tó jẹ́ onírìn gbéregbère (gẹ́gẹ́ bí Swete ti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ) pé: “Ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí ti dúró ní ilé aṣẹ́wó . . . orúkọ rẹ so rọ̀ níwájú orí rẹ; ìwọ ń gba owó fún àbùkù rẹ.”—Ìwé Controv. i, 2.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 237]
Òǹkọ̀wé Churchill Tú Àṣírí ‘Ìwà Aṣẹ́wó’
Nínú ìwé rẹ̀ The Gathering Storm (1948), Winston Churchill sọ pé Hitler yan ọ̀gbẹ́ni Franz von Papen gẹ́gẹ́ bí aṣojú ilẹ̀ Jámánì ní ìlú Vienna “kó lè pa àwọn abẹnugan nínú òṣèlú ilẹ̀ Austria lẹ́nu mọ́ tàbí kó sọ wọ́n di alátìlẹyìn ilẹ̀ Jámánì.” Churchill tún fa ọ̀rọ̀ tí aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó wà ní Vienna sọ nípa von Papen yọ, pé: “Papen ò pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ rárá bó ṣe ń pẹ̀gàn àwọn ará Austria . . . ó wá sọ fún mi pé . . . òun ní in lọ́kàn láti lo jíjẹ́ tí òun jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì rere láti fi wá ìtìlẹ́yìn àwọn ará Austria, irú bíi Kádínà Innitzer.”
Lẹ́yìn tí Austria ti túúbá, tí àwọn ọmọ ogun Hitler tí wọ́n jẹ́ òǹrorò sì ti yan wọ Vienna, kádínà Innitzer tó jẹ́ ọmọ Ìjọ Kátólíìkì pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Austria ta àsíá ìjọba Násì, kí wọ́n lu aago wọn, kí wọ́n sì gbàdúrà fún Adolf Hitler láti ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 238]
‘ÀDÚRÀ OGUN’ FÚN ÌJỌBA NÁSÌ
Lábẹ́ àkòrí yìí, àpilẹ̀kọ tá a tú sísàlẹ̀ yìí fara hàn nínú ẹ̀dà ìwé ìròyìn The New York Times ti December 7, 1941 tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀:
“Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì Ìlú Fulda Gbàdúrà fún Ìbùkún àti Ìṣẹ́gun . . . Ẹgbẹ́ Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì Ilẹ̀ Jámánì tí wọ́n pé jọ ní Fulda ti dámọ̀ràn pé kí àkànṣe ‘àdúrà ogun’ kan wà tí wọn yóò máa kà ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí gbogbo àwọn ìpàdé ìjọsìn. Àdúrà náà jẹ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ káwọn ohun ìjà ogun Jámánì máa ṣẹ́gun nìṣó kó sì dáàbò bo ẹ̀mí àti ìlera gbogbo àwọn ọmọ ogun. Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù náà tún sọ fún àwọn àlùfáà Kátólíìkì pé kí wọ́n máa rántí àwọn ọmọ ogun Jámánì tí wọ́n wà ‘lórí ilẹ̀, lórí omi àti lójú òfuurufú’ nínú àkànṣe ìwàásù tí wọ́n máa ń ṣe lọ́jọ́ Sunday, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lóṣù, kí wọ́n sì máa ṣe èyí déédéé.”
Wọ́n yọ àpilẹ̀kọ yìí kúrò nínú àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí tí wọ́n tún tẹ̀ lẹ́yìn náà. December 7, 1941, ni ọjọ́ tí orílẹ̀-èdè Japan, tó ń bá ìjọba Násì ti Jámánì pawọ́ pọ̀ jagun, kọ lu àwọn ọkọ̀ ojú omi ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní àgbègbè Pearl Harbor.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 244]
“Àwọn Orúkọ Ọ̀rọ̀ Òdì”
Nígbà tí ẹranko ẹhànnà tó ní ìwo méjì náà rọ àwọn orílẹ̀-èdè láti dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn onísìn tí wọ́n jẹ́ àlè rẹ̀ gbìyànjú láti fọwọ́ sí àbá yìí. Nítorí èyí, àjọ tí wọ́n ló máa mú àlàáfíà wá náà di èyí tó “kún fún àwọn orúkọ ọ̀rọ̀ òdì.”
“Ìsìn Kristẹni lè mú kí ìfẹ́ inú rere wà, èyí tí wọ́n torí rẹ̀ dá ìmùlẹ̀ [àwọn orílẹ̀-èdè] sílẹ̀, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ yí àdéhùn náà padà kúrò ní àkọsílẹ̀ orí bébà lásánlàsàn sí ètò kan tí ìjọba Ọlọ́run ń lò.”—The Christian Century, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, June 19, 1919, ojú ìwé 15.
“Ìdí tí wọ́n fi dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ ni láti tan èrò náà kálẹ̀ jákèjádò ayé pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ètò ìfẹ́ inú rere kárí ayé. . . . Òun ni ohun tí gbogbo àwọn Kristẹni ń gbàdúrà fún nígbà tí wọ́n bá wí pé, ‘Kí Ìjọba rẹ dé.’”—The Christian Century, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, September 25, 1919, ojú ìwé 7.
“Ẹ̀jẹ̀ Kristi ló gbé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè dúró.”—Dókítà Frank Crane, àlùfáà ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
‘Ìgbìmọ̀ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Congregational Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbà pé Májẹ̀mú [Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè] nìkan ni ètò ìṣèlú tó wà nísinsìnyí tó lè mú kí Ẹ̀mí Jésù Kristi di èyí tí gbogbo èèyàn yóò máa lò nínú àlámọ̀rí àwọn orílẹ̀-èdè.’—The Congregationalist and Advance, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, November 6, 1919, ojú ìwé 642.
“Ìgbìmọ̀ náà ké pe gbogbo àwọn onísìn Mẹ́tọ́díìsì pé kí wọ́n gbé àwọn ohun dáradára tí [Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè] pinnu láti ṣe lárugẹ, èyí tó dúró fún èrò Ọlọ́run Baba àti àwọn ọmọ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.”—The Wesleyan Methodist Church, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
“Nígbà tá a bá ronú nípa àwọn ohun tí àjọ yìí ń retí, àwọn ohun tó lè gbé ṣe àtàwọn ohun tó ti pinnu láti ṣe látàrí àdéhùn yìí, a ó rí i pé ohun tó jẹ́ lájorí àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi wà nínú àdéhùn yìí, ìyẹn ni Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ . . . Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn.”—Ìwàásù Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti Canterbury nígbà tí wọ́n ń ṣí Àpéjọ Àpapọ̀ ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní ìlú Geneva, December 3, 1922.
“Àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní orílẹ̀-èdè yìí ní ẹ̀tọ́ mímọ́ kan náà tí ẹgbẹ́ míṣọ́nnárì afẹ́nifẹ́re èyíkéyìí ní, nítorí ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, òun ni aṣojú tó gbéṣẹ́ jù lọ fún ìṣàkóso Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Aládé àlàáfíà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”—Dókítà Garvie, àlùfáà ìjọ Congregational, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 236]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Bábílónì ni àwọn ẹ̀kọ́ èké táwọn èèyàn gbà gbọ́ kárí ayé ti ṣẹ̀ wá
Bábílónì
Àwọn mẹ́talọ́kan tàbí ọlọ́run mẹ́ta alápapọ̀
Ọkàn èèyàn ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú
Ìbẹ́mìílò—bíbá “òkú” sọ̀rọ̀
Lílo àwọn ère nínú ìjọsìn
Lílo oògùn láti fi tu àwọn ẹ̀mí èṣù lójú
Ìṣàkóso nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àlùfáà alágbára
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 239]
Bábílónì ìgbàanì jókòó lórí omi púpọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 239]
Aṣẹ́wó ńlá òde òní náà jókòó lórí “omi púpọ̀”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 241]
Bábílónì Ńlá jókòó lórí ẹranko ẹhànnà eléwu
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 242]
Aṣẹ́wó ìsìn ti bá àwọn ọba ilẹ̀ ayé ṣe àgbèrè
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 245]
Obìnrin náà “ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́” ní àmupara
-
-
A Rí Ojútùú Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan Tó Ṣeni Ní KàyéfìÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
Orí 34
A Rí Ojútùú Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan Tó Ṣeni Ní Kàyéfì
1. (a) Kí ló ṣe Jòhánù nígbà tó rí aṣẹ́wó ńlá náà àti ẹranko ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ń gùn, kí sì nìdí? (b) Kí ló ṣe ẹgbẹ́ Jòhánù lóde òní bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń mú ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ ṣe ń ṣẹlẹ̀?
KÍ LÓ ṣe Jòhánù nígbà tó rí aṣẹ́wó ńlá náà àti ẹranko ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ń gùn? Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Tóò, ní títajúkán rí i, kàyéfì ńlá ṣe mí.” (Ìṣípayá 17:6b) Ẹ̀dá èèyàn ò lè dá ronú kan irú ohun abàmì bẹ́ẹ̀ rárá. Síbẹ̀, ohun abàmì yìí ṣẹlẹ̀ nínú aginjù lọ́hùn-ún. Aṣẹ́wó oníwàkiwà kan ń gun abàmì ẹranko ẹhànnà kan tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò! (Ìṣípayá 17:3) Kàyéfì ńlá ṣe ẹgbẹ́ Jòhánù lóde òní pẹ̀lú bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń mú ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ ṣe ń ṣẹlẹ̀. Ká ní àwọn èèyàn ayé lè rí i ni, wọn ì bá kígbe pé, ‘Èèmọ̀ rè é!,’ àwọn olùṣàkóso ayé ì bá sì sọ pé, ‘Áà, kí rèé!’ Ṣùgbọ́n ìran tó ṣeni ní kàyéfì yìí ń nímùúṣẹ lóòótọ́ lákòókò wa yìí. Àwọn èèyàn Ọlọ́run ti kópa tó pọ̀ nínú ìmúṣẹ ìran náà, èyí sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ ìran náà yóò ní ìmúṣẹ rẹ̀ yíyanilẹ́nu tó kẹ́yìn.
2. (a) Nígbà tí áńgẹ́lì náà kíyè sí bí ẹnu ṣe ya Jòhánù, kí ló sọ fún Jòhánù? (b) Kí ni Ọlọ́run ti ṣí payá fún ẹgbẹ́ Jòhánù, báwo ló sì ṣe ṣí i payá?
2 Áńgẹ́lì náà kíyè sí i pé ìyàlẹ́nu ni ìran náà jẹ́ fún Jòhánù. Ohun tí Jòhánù sì wí pé áńgẹ́lì náà sọ nìyí: “Nítorí náà, áńgẹ́lì náà wí fún mi pé: ‘Èé ṣe tí ìwọ fi ṣe kàyéfì? Ó dájú pé èmi yóò sọ ohun ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ àti ti ẹranko ẹhànnà tí ń gbé e, tí ó sì ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.’” (Ìṣípayá 17:7) Ní báyìí, áńgẹ́lì náà yóò sọ ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ náà! Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé ohun tí onírúurú nǹkan tó wà nínú ìran náà túmọ̀ sí, ó sì sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó máa tó ṣẹlẹ̀ fún Jòhánù tí ìyàlẹ́nu ti bá. Bákan náà, lóde òní Ọlọ́run ti ṣí ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà payá fún ẹgbẹ́ Jòhánù tó wà lójúfò bí ẹgbẹ́ náà ṣe ń sìn lábẹ́ ìdarí àwọn áńgẹ́lì. Jósẹ́fù olóòótọ́ béèrè pé, “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?” Bíi ti Jósẹ́fù, a gbà pé ti Ọlọ́run ni ìtumọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 40:8; fi wé Dáníẹ́lì 2:29, 30.) Ńṣe ló dà bíi pé àwa èèyàn Ọlọ́run wà ní àárín méjì orí ìtàgé kan bí Jèhófà ṣe ń sọ ìtumọ̀ ìran náà àti ipa tó yẹ kó ní lórí ìgbésí ayé wa. (Sáàmù 25:14) Ní àkókò tó yẹ gẹ́lẹ́, ó jẹ́ ká rí ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ obìnrin náà àti ẹranko ẹhànnà náà.—Sáàmù 32:8.
3, 4. (a) Àsọyé fún gbogbo ènìyàn wo ni N. H. Knorr sọ ní 1942, kí ló sì sọ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jẹ́? (b) Ọ̀rọ̀ wo ni áńgẹ́lì náà sọ fún Jòhánù, èyí tí N. H. Knorr sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
3 Lákòókò tí Ogun Àgbáyé Kejì gbóná janjan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n pè ní Àpéjọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun ti Ìjọba Ọlọ́run, ní September 18 sí 20, 1942. Ìlú Cleveland ni wọ́n ti ṣe àpéjọ àgbègbè náà, wọ́n wá fi tẹlifóònù gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà sáfẹ́fẹ́ láwọn ìlú mìíràn tó lé ní àádọ́ta, tó fi jẹ́ pé iye àwọn tó gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàádóje ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín kan [129,699]. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe àpéjọ yìí jákèjádò ayé láwọn ibi tó ti ṣeé ṣe lákòókò ogun náà. Lákòókò yẹn, èrò ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà ni pé ńṣe ni ogun náà yóò máa le sí í títí tí yóò fi yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà, “Ǹjẹ́ Àlàáfíà Lè Wà Pẹ́?,” ńṣe ni wọ́n ń hára gàgà láti gbọ́ àlàyé tó máa wáyé. Báwo ni ààrẹ tuntun fún Watch Tower Society, N. H. Knorr ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà nígbà tó jẹ́ pé òdìkejì rẹ̀ ló dà bíi pé àwọn orílẹ̀-èdè máa rí?a Ìdí ni pé ẹgbẹ́ Jòhánù ń “fún” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.”—Hébérù 2:1; 2 Pétérù 1:19.
4 Báwo ni àsọyé náà “Ǹjẹ́ Àlàáfíà Lè Wà Pẹ́?” ṣe ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ náà? Nínú àsọyé náà, N. H. Knorr fi hàn kedere pé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó wà nínú Ìṣípayá 17:3. Lẹ́yìn náà, ó wá sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ò ṣe ní fararọ fún un, ó sì gbé ìyẹn ka ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì sọ fún Jòhánù, pé: “Ẹranko ẹhànnà tí ìwọ rí ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí, síbẹ̀ ó máa tó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, yóò sì kọjá lọ sínú ìparun.”—Ìṣípayá 17:8a.
5. (a) Báwo ló ṣe jẹ́ pé “ẹranko ẹhànnà [náà] . . . ti wà tẹ́lẹ̀” àti lẹ́yìn náà tí “kò sí”? (b) Báwo ní N. H. Knorr ṣe dáhùn ìbéèrè náà, “Ǹjẹ́ ìmùlẹ̀ náà yóò máa wà nínú kòtò títí lọ?”
5 “Ẹranko ẹhànnà [náà] . . . ti wà tẹ́lẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó ti wà tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti January 10, 1920. Nígbà yẹn, orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] ló wà nínú ìmùlẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n, níkọ̀ọ̀kan, Japan, Jámánì, àti Ítálì yọwọ́yọsẹ̀, nígbà tó yá, wọ́n yọ Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí kúrò nínú Ìmùlẹ̀ náà. Ní September 1939, aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tó jẹ́ olórí Ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì bẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì.b Nígbà tí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti kùnà láti mú kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé, ó rì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, kò lè ṣe nǹkan kan mọ́. Nígbà tó fi máa di 1942, ó ti dohun ìtàn. Àkókò oníyánpọnyánrin yẹn gan-an ni Jèhófà túmọ̀ ìran náà fáwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, kò túmọ̀ rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn tàbí lẹ́yìn náà! Ní Àpéjọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun ti Ìjọba Ọlọ́run, N. H. Knorr polongo pé “ẹranko ẹhànnà [náà] . . . kò sí” bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ. Lẹ́yìn náà ó béèrè pé, “Ǹjẹ́ ìmùlẹ̀ náà yóò máa wà nínú kòtò títí lọ?” Ó wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìṣípayá 17:8, ó sì dáhùn pé: “Àjọ àpapọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè náà yóò tún fara hàn.” Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn, èyí tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run kì í kùnà!
Bó Ṣe Jáde Látinú Ọ̀gbun Àìnísàlẹ̀
6. (a) Ìgbà wo ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jáde láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, orúkọ tuntun wo sì ni wọ́n fún un? (b) Kí nìdí tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi jẹ́ ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí?
6 Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ lóòótọ́. Ní June 26, 1945, afẹfẹyẹ̀yẹ̀ aláriwo ni àádọ́ta [50] orílẹ̀-èdè fi kéde ìbẹ̀rẹ̀ ìdìbò tí wọ́n fi fọwọ́ sí Ìwé Ìdásílẹ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní San Francisco, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ní ojúṣe àjọ náà ni “láti rí i pé mìmì kan ò mi àlàáfíà àti ààbò àgbáyé.” Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi jọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Láwọn ọ̀nà kan, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní . . . Ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n para pọ̀ dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ náà ló para pọ̀ dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀. Bíi ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìdí tí wọ́n fi dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ ni kó lè máa rí i pé àlàáfíà wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn ẹ̀ka pàtàkì-pàtàkì tí ń bẹ nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.” Nítorí náà, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà nínú àjọ yìí jẹ́ nǹkan bí igba ó dín mẹ́wàá [190], èyí tó pọ̀ fíìfíì ju orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] tó wà nínú Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè; yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ kó máa ṣe pọ̀ ju ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ.
7. (a) Ọ̀nà wo làwọn olùgbé ilẹ̀ ayé fi ṣe kàyéfì tí wọ́n sì kan sáárá sí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí náà? (b) Kí ló jẹ́ àléèbá fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kí sì ni akọ̀wé àgbà àjọ yẹn tẹ́lẹ̀ rí sọ nípa èyí?
7 Nígbà tí wọ́n dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, àwọn èèyàn sọ nǹkan ńláńlá tí wọ́n nírètí pé á gbé ṣe. Èyí mú ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì náà sọ ṣẹ, pé: “Nígbà tí wọ́n bá sì rí bí ẹranko ẹhànnà náà ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò sí, síbẹ̀ tí yóò tún wà, àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò ṣe kàyéfì lọ́nà ìkansáárá, ṣùgbọ́n a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:8b) Àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé kan sáárá sí àjọ ńlá tuntun yìí, tí wọ́n fi ilé gàgàrà gagara kan ṣe oríléeṣẹ́ rẹ̀ ní East River ní New York. Ṣùgbọ́n ohun àléèbá ni ojúlówó àlàáfíà àti ààbò jẹ́ fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè o. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ní ọ̀rúndún ogún, ìlànà ‘tó o bá ló o fẹ́ pa mí run, àá jọ para wa run ni’ [“mutual assured destruction” tí ìkékúrú rẹ̀ jẹ́ MAD] làwọn orílẹ̀-èdè alágbára fi ń halẹ̀ mọ́ ara wọn kí àlàáfíà lè wà láyé. Ìlànà MAD yìí ni pé bí orílẹ̀-èdè alágbára kan bá yin ohun ìjà runlé-rùnnà sí orílẹ̀-èdè kan, kí ó mọ̀ dájú pé àwọn ọ̀tà máa yin irú ẹ̀ padà sórílẹ̀-èdè tòun. Abájọ tí ṣíṣe ohun ìjà ogun fi ń pọ̀ sí i. Ní 1985, ìyẹn lẹ́yìn ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì [40] ọdún tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti ń gbìyànjú pé kí àlàáfíà wà láyé, Javier Pérez de Cuéllar tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àjọ náà nígbà yẹn, dárò pé: “Àkókò tá a wà yìí jẹ́ sànmánì àwọn oníwà ẹhànnà bíi tàwọn ìgbà kan, a ò sì mọ nǹkan tá a lè ṣe sí i.”
8, 9. (a) Kí nìdí tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò fi lè fòpin sí ìṣòro ayé, kí sì ni yóò ṣẹlẹ̀ sí i láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tí a kò fi kọ orúkọ àwọn tó ṣe ìdásílẹ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti orúkọ àwọn tó ń kan sáárá sí i sínú “àkájọ ìwé ìyè” Ọlọ́run? (d) Kí ni Ìjọba Jèhófà yóò ṣe láṣeyọrí?
8 Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò lè fòpin sí ìṣòro ayé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹni tó ṣẹ̀dá ọmọ aráyé kọ́ ló dá a sílẹ̀. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò ní wà pẹ́, nítorí àṣẹ Ọlọ́run ni pé ‘yóò kọjá lọ sínú ìparun.’ Orúkọ àwọn tó dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ àti orúkọ àwọn tó ń kan sáárá sí i kò sí nínú ìwé ìyè Ọlọ́run. Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ná, báwo làwọn èèyàn wọ̀nyí, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àtẹni kíkú, tí ọ̀pọ̀ lára wọn sì ń pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà, ṣe lè fi Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣàṣeyọrí ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun á ṣe láìpẹ́, àmọ́ pé òun ò ní tipasẹ̀ èèyàn ṣe é bí kò ṣe nípasẹ̀ Ìjọba Kristi Ọlọ́run?—Dáníẹ́lì 7:27; Ìṣípayá 11:15.
9 Ní tòdodo, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jẹ́ ayédèrú Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run. Nǹkan àbùkù ló sì jẹ́ sí Jésù Kristi Ọmọ Aládé Àlàáfíà tí Ọlọ́run fi jẹ ọba Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run yìí, tó jẹ́ pé ìjọba rẹ̀ ò ní dópin. (Aísáyà 9:6, 7) Bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè bá tiẹ̀ ṣètò àlàáfíà onígbà díẹ̀, kò ní pẹ́ tí ogun á tún fi rú yọ. Àwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ò lè ṣe kí wọ́n má jagun nítorí ó ti mọ́ wọn lára. Ìṣípayá sọ pé “a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” Ìjọba Jèhófà tí Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀ yóò mú àlàáfíà tí ò lópin wá sórí ilẹ̀ ayé, kì í wá ṣe ìyẹn nìkan, yóò tún jí àwọn òkú dìde lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, ìyẹn òkú àwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo tí wọ́n wà ní ìrántí Ọlọ́run. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Lára àwọn tó máa ní àjíǹde yìí ni gbogbo àwọn tó dúró gbọn-in nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìfi àtakò tí Sátánì àti irú-ọmọ rẹ̀ ṣe sí wọn pè, àtàwọn tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fi hàn bóyá wọ́n á jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run. Ó hàn gbangba pé orúkọ àwọn tí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní kúrò nínú Bábílónì Ńlá tàbí orúkọ ẹnikẹ́ni tí ò bá yéé jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà kò ní wọ ìwé ìyè Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 32:33; Sáàmù 86:8-10; Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 16:2; 17:5.
Àlàáfíà àti Ààbò—Ìrètí Asán
10, 11. (a) Kí ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè polongo ní 1986, kí sì làwọn orílẹ̀-èdè ṣe? (b) “Àwùjọ ìsìn” mélòó ló pé jọ sí Ásísì ní Ítálì láti gbàdúrà pé kí àlàáfíà wà, ṣé Ọlọ́run sì máa ń dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Ṣàlàyé.
10 Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbìyànjú láti mú kó túbọ̀ dá àwọn èèyàn lójú pé ìrètí ń bẹ, ó polongo pé 1986 jẹ́ “Ọdún Àlàáfíà Kárí Ayé,” ohun tó sì fi ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ ìpolongo rẹ̀ ni, “A Fẹ́ Rí I Pé Mìmì Kan Ò Mi Àlàáfíà àti Ọjọ́ Ọ̀la Ọmọ Aráyé.” Wọ́n sọ fáwọn orílẹ̀-èdè tó ń jagun pé kí wọ́n dáwọ́ ogun dúró, ó kéré tán fún ọdún kan. Kí làwọn orílẹ̀-èdè náà wá ṣe? Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àlàáfíà Àgbáyé ròyìn pé ní 1986 nìkan, ó tó mílíọ̀nù márùn-ún [5,000,000] èèyàn tí ogun pa! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe àkànṣe owó ẹyọ àti òǹtẹ̀ ìrántí ọdún àlàáfíà yìí, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè ò ṣe ohun tó máa mú kọ́wọ́ wọn tẹ àlàáfíà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọdún yẹn. Àmọ́, ńṣe làwọn ìsìn ayé bẹ̀rẹ̀ sí í polongo ọdún yẹn lóríṣiríṣi ọ̀nà, torí ohun táwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí kúkú ń wá ni bí àjọṣe á ṣe wà láàárín àwọn àti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ní January 1, 1986, Póòpù John Paul Kejì gbóṣùbà fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pé ó ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́, ó sì wá ya ọdún tuntun náà sọ́tọ̀ pé ó jẹ́ ọdún àlàáfíà. Lẹ́yìn náà, ní October 27, ó pe àwọn aṣáájú ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsìn ayé jọ sí Ásísì ní Ítálì, kí wọ́n lè gbàdúrà pé kí àlàáfíà wà.
11 Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Ó dáa, Ọlọ́run wo làwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn gbàdúrà sí? Bó o bá bi wọ́n léèrè, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan máa sọ. Ǹjẹ́ àgbájọ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọlọ́run kan wà tó lè gbọ́ onírúurú àdúrà tí wọ́n gbà lóríṣiríṣi ọ̀nà kó sì dáhùn rẹ̀? Mẹ́talọ́kan àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbàdúrà náà ń jọ́sìn.c Àwọn onísìn Búdà, Híńdù, àtàwọn míì gba onírúurú àdúrà sí ọ̀kẹ́ àìmọye ọlọ́run. Lápapọ̀, “àwùjọ ìsìn” méjìlá ló pé jọ, àwọn to sì ṣojú fún wọn ni àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn bíi Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Áńgílíkà ní Canterbury, Dalai Lama onísìn Búdà, Bíṣọ́ọ̀bù kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ojúbọ Ṣintó ní Tokyo, àwọn abọgibọ̀pẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà, àtàwọn Àmẹ́ríńdíà méjì tí wọ́n dé ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n fi ìyẹ́ ṣe sórí. Lọ́rọ̀ kan ṣá, àpéjọ yẹn jojú ní gbèsè ó sì mú kí tẹlifíṣọ̀n rí ìròyìn tó fakíki gbé jáde. Ọ̀kan lára àwọn àwùjọ náà gbàdúrà láìdákẹ́ fún wákàtí méjìlá. (Fi wé Lúùkù 20:45-47.) Síbẹ̀, ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú ọ̀pọ̀ àdúrà tí wọ́n gbà yẹn kọjá àwọsánmà? Rárá o. A óò rí ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ní ìpínrọ̀ tó kàn.
12. Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi dáhùn àdúrà àlàáfíà táwọn aṣáájú ìsìn ayé gbà?
12 Àwọn onísìn tí póòpù pè yẹn ò ṣe bíi tàwọn tó ń “rìn ní orúkọ Jèhófà,” ìkankan wọn ò gbàdúrà sí Jèhófà, Ọlọ́run alààyè tí orúkọ rẹ̀ fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Míkà 4:5; Aísáyà 42:8, 12)d Wọn ò para pọ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run lórúkọ Jésù, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ò tiẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. (Jòhánù 14:13; 15:16) Kò sí ọ̀kan nínú wọn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe lákòókò wa yìí, ìyẹn ni pé ká máa pòkìkí jákèjádò ayé pé Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀ ni ojúlówó ìrètí ayé, kì í ṣe pé ká máa pòkìkí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. (Mátíù 7:21-23; 24:14; Máàkù 13:10) Àní àwọn ìsìn ayé yìí lọ́wọ́ sí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ogun ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀, tó fi mọ́ ogun àgbáyé méjèèjì tó jà ní ọ̀rúndún ogún. Ohun tí Ọlọ́run sì sọ fún irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ ni pé: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.”—Aísáyà 1:15; 59:1-3.
13. (a) Kí ni dídarapọ̀ táwọn aṣáájú ìsìn ayé dara pọ̀ mọ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà fi hàn? (b) Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wo ni igbe fún àlàáfíà yóò jálẹ̀ sí?
13 Bákan náà, báwọn aṣáájú ìsìn ayé ṣe dara pọ̀ mọ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà lákòókò yìí fi nǹkan kan hàn. Àwọn aṣáájú ìsìn náà yóò fẹ́ láti darí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún àǹfààní ara wọn, pàápàá lóde òní tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ wọn ń pa ìsìn tì. Bíi tàwọn aláìṣòótọ́ aṣáájú Ísírẹ́lì ayé àtijọ́, wọ́n ń kéde pé, “‘Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!’ nígbà tí kò sí àlàáfíà.” (Jeremáyà 6:14) Ó dájú pé igbe wọn fún àlàáfíà ò ní yéé dún, ńṣe ni yóò máa dún sókè sí i láti fi hàn pé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ yóò nímùúṣẹ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 Tẹsalóníkà 5:2, 3.
14. Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí igbe “Àlàáfíà àti ààbò!” gbà dún, kí sì lẹnì kan lè ṣe tí ìyẹn ò fi ní tàn án jẹ?
14 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn olóṣèlú ti lo gbólóhùn náà, “àlàáfíà àti ààbò” láti fi ṣàpèjúwe oríṣiríṣi ohun tí àwọn ènìyàn ń gbèrò láti ṣe. Ǹjẹ́ akitiyan tí àwọn aṣáájú ayé ń ṣe yìí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmúṣẹ 1 Tẹsalóníkà 5:3? Àbí gbankọgbì ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa gbàfiyèsí gbogbo ayé ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lẹ́yìn tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì bá ṣẹ tán tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣẹ lọ́wọ́ la sábà máa ń lóye wọn ní kíkún, a ní láti ṣe sùúrù ká wo ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí. Àmọ́, ó dá àwọn Kristẹni lójú pé bí ayé tiẹ̀ ń sọ pé ọwọ́ àwọn tẹ àlàáfíà àti ààbò lọ́nà kan tàbí òmíràn, ohunkóhun ò ní yí padà. Ìdí ni pé, ìmọtara-ẹni-nìkan, ìkórìíra, ìwà ọ̀daràn, fífọ́ tí ìdílé ń fọ́, ìṣekúṣe, àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú á ṣì máa ṣẹlẹ̀. Ìdí nìyẹn tí kò fi yẹ kí igbe “àlàáfíà àti ààbò” kankan tan ìwọ jẹ tó o bá ń wà lójúfò láti mọ ìtumọ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé tó o sì ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Máàkù 13:32-37; Lúùkù 21:34-36.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a J. F. Rutherford kú ní January 8, 1942, N. H. Knorr sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Watch Tower Society.
b Ní November 20, 1940, Jámánì, Ítálì, Japan, àti Hungary fọwọ́ sí ìwé láti dá “Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tuntun” kan sílẹ̀. Ní ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà, Vatican kéde ìsìn Máàsì àti àdúrà fún àlàáfíà ìsìn àti fún ètò àwọn nǹkan tuntun. Àmọ́ “Ìmùlẹ̀ tuntun” yẹn ò fìdí múlẹ̀.
c Ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan wá láti Bábílónì ayé ọjọ́un tí wọ́n ti ń jọ́sìn ọlọ́run mẹ́ta alápapọ̀, ìyẹn, Shamash ọlọ́run oòrùn, Sin ọlọ́run òṣùpá, àti Ishtar ọlọ́run ìràwọ̀. Báwọn ará Íjíbítì náà ṣe ṣe nìyẹn, wọ́n jọ́sìn ọlọ́run Osiris, Isis, àti Horus. Orí mẹ́ta ni wọ́n fi hàn pé Asshur tó jẹ́ olú ọlọ́run orílẹ̀-èdè Ásíríà ní. Ohun táwọn Kátólíìkì náà sì ṣe nìyẹn, wọ́n gbé àwọn àwòrán tó fi Ọlọ́run hàn bí olórí mẹ́ta sínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn.
d Ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Third New International Dictionary ti ọdún 1993 sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ni “ẹni tá a mọ̀ sí Ọlọ́run gíga jù lọ, òun sì ni Ọlọ́run kan ṣoṣo tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jọ́sìn.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 250]
Òdì Kejì “Àlàáfíà”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún 1986 ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè polongo pé ó jẹ́ Ọdún Àlàáfíà Kárí Ayé, ńṣe ni ìdíje àwọn ohun ìjà apanirun peléke sí i. Ìwé World Military and Social Expenditures 1986 pèsè àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó gbàrònú wọ̀nyí:
Ní 1986 àwọn ìnáwó ológun kárí ayé tó bílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900,000,000,000] owó dọ́là.
Owó tí wọ́n ná sórí àwọn ológun kárí ayé ní wákàtí kan ṣoṣo ì bá ti tó láti fi pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára fún mílíọ̀nù mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500,000] tó ń kú lọ́dọọdún látàrí àrùn tí ń gbèèràn tí ì bá má ṣẹlẹ̀.
Kárí ayé, ẹnì kan nínú ẹni márùn-ún wà nínú ipò òṣì paraku. Gbogbo àwọn èèyàn tí ebi pa wọ̀nyẹn ni wọn ì bá ti fi owó tí ayé ná sórí àwọn ohun ìjà ní ọjọ́ méjì bọ́ fún ọdún kan.
Agbára ìbúgbàù tó wà nínú àpapọ̀ àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tí ayé ní fi ìlọ́po ọgọ́jọ mílíọ̀nù [160,000,000] ju ti ìbúgbàù iléeṣẹ́ ẹ̀rọ Chernobyl lọ.
Bọ́ǹbù runlé-rùnnà kan ṣoṣo tó ní agbára ìbúgbàù tó fi ìlọ́po ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ìgbà lágbára ju ti bọ́ǹbù tá a jù sí ìlú Hiroshima ní 1945 lọ ń bẹ lọ́wọ́ ọmọ aráyé.
Àkójọ àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tó wà lọ́wọ́ ní ohun tó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ irú àdó olóró tí wọ́n jù sí ìlú Hiroshima lọ. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ìgbà ni àpapọ̀ agbára ìbúgbàù wọn fi ju ti àwọn bọ́ǹbù tí wọ́n jù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tó pa mílíọ̀nù méjìdínlógójì [38] èèyàn.
Ogun ti túbọ̀ ń wáyé léraléra jù wọ́n sì ń gbẹ̀mí èèyàn jù. Díẹ̀ ni àròpọ̀ iye àwọn tí ogun pa fi dín ní mílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ó sì fi díẹ̀ dín ní mílíọ̀nù mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] láàárín ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún ogún. Láti ọ̀rúndún kejìdínlógún, àwọn tógun ń pa ti yára fi ìlọ́po mẹ́fà ju iye àwọn èèyàn tó wà láyé lọ. Ìlọ́po mẹ́wàá ni iye àwọn tí ń kú nínú ogun kọ̀ọ̀kan ní ọ̀rúndún yìí tá a bá fi wé ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 247]
Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ṣe sọ, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àmọ́ ó sọ jí padà gẹ́gẹ́ bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 249]
Ní ìlú Ásísì lórílẹ̀-èdè Ítálì, àwọn aṣojú ìsìn ayé gba ọ̀pọ̀ àdúrà onídàrúdàpọ̀ láti ṣètìlẹyìn fún “Ọdún Àlàáfíà” àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, àmọ́ kò sí ọ̀kan nínú wọn tó gbàdúrà sí Jèhófà, Ọlọ́run alààyè
-