-
A Rí Ojútùú Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan Tó Ṣeni Ní KàyéfìÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
Orí 34
A Rí Ojútùú Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan Tó Ṣeni Ní Kàyéfì
1. (a) Kí ló ṣe Jòhánù nígbà tó rí aṣẹ́wó ńlá náà àti ẹranko ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ń gùn, kí sì nìdí? (b) Kí ló ṣe ẹgbẹ́ Jòhánù lóde òní bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń mú ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ ṣe ń ṣẹlẹ̀?
KÍ LÓ ṣe Jòhánù nígbà tó rí aṣẹ́wó ńlá náà àti ẹranko ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ń gùn? Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Tóò, ní títajúkán rí i, kàyéfì ńlá ṣe mí.” (Ìṣípayá 17:6b) Ẹ̀dá èèyàn ò lè dá ronú kan irú ohun abàmì bẹ́ẹ̀ rárá. Síbẹ̀, ohun abàmì yìí ṣẹlẹ̀ nínú aginjù lọ́hùn-ún. Aṣẹ́wó oníwàkiwà kan ń gun abàmì ẹranko ẹhànnà kan tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò! (Ìṣípayá 17:3) Kàyéfì ńlá ṣe ẹgbẹ́ Jòhánù lóde òní pẹ̀lú bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń mú ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ ṣe ń ṣẹlẹ̀. Ká ní àwọn èèyàn ayé lè rí i ni, wọn ì bá kígbe pé, ‘Èèmọ̀ rè é!,’ àwọn olùṣàkóso ayé ì bá sì sọ pé, ‘Áà, kí rèé!’ Ṣùgbọ́n ìran tó ṣeni ní kàyéfì yìí ń nímùúṣẹ lóòótọ́ lákòókò wa yìí. Àwọn èèyàn Ọlọ́run ti kópa tó pọ̀ nínú ìmúṣẹ ìran náà, èyí sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ ìran náà yóò ní ìmúṣẹ rẹ̀ yíyanilẹ́nu tó kẹ́yìn.
2. (a) Nígbà tí áńgẹ́lì náà kíyè sí bí ẹnu ṣe ya Jòhánù, kí ló sọ fún Jòhánù? (b) Kí ni Ọlọ́run ti ṣí payá fún ẹgbẹ́ Jòhánù, báwo ló sì ṣe ṣí i payá?
2 Áńgẹ́lì náà kíyè sí i pé ìyàlẹ́nu ni ìran náà jẹ́ fún Jòhánù. Ohun tí Jòhánù sì wí pé áńgẹ́lì náà sọ nìyí: “Nítorí náà, áńgẹ́lì náà wí fún mi pé: ‘Èé ṣe tí ìwọ fi ṣe kàyéfì? Ó dájú pé èmi yóò sọ ohun ìjìnlẹ̀ obìnrin náà fún ọ àti ti ẹranko ẹhànnà tí ń gbé e, tí ó sì ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá.’” (Ìṣípayá 17:7) Ní báyìí, áńgẹ́lì náà yóò sọ ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ náà! Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé ohun tí onírúurú nǹkan tó wà nínú ìran náà túmọ̀ sí, ó sì sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó máa tó ṣẹlẹ̀ fún Jòhánù tí ìyàlẹ́nu ti bá. Bákan náà, lóde òní Ọlọ́run ti ṣí ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà payá fún ẹgbẹ́ Jòhánù tó wà lójúfò bí ẹgbẹ́ náà ṣe ń sìn lábẹ́ ìdarí àwọn áńgẹ́lì. Jósẹ́fù olóòótọ́ béèrè pé, “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?” Bíi ti Jósẹ́fù, a gbà pé ti Ọlọ́run ni ìtumọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 40:8; fi wé Dáníẹ́lì 2:29, 30.) Ńṣe ló dà bíi pé àwa èèyàn Ọlọ́run wà ní àárín méjì orí ìtàgé kan bí Jèhófà ṣe ń sọ ìtumọ̀ ìran náà àti ipa tó yẹ kó ní lórí ìgbésí ayé wa. (Sáàmù 25:14) Ní àkókò tó yẹ gẹ́lẹ́, ó jẹ́ ká rí ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ obìnrin náà àti ẹranko ẹhànnà náà.—Sáàmù 32:8.
3, 4. (a) Àsọyé fún gbogbo ènìyàn wo ni N. H. Knorr sọ ní 1942, kí ló sì sọ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jẹ́? (b) Ọ̀rọ̀ wo ni áńgẹ́lì náà sọ fún Jòhánù, èyí tí N. H. Knorr sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
3 Lákòókò tí Ogun Àgbáyé Kejì gbóná janjan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n pè ní Àpéjọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun ti Ìjọba Ọlọ́run, ní September 18 sí 20, 1942. Ìlú Cleveland ni wọ́n ti ṣe àpéjọ àgbègbè náà, wọ́n wá fi tẹlifóònù gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà sáfẹ́fẹ́ láwọn ìlú mìíràn tó lé ní àádọ́ta, tó fi jẹ́ pé iye àwọn tó gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàádóje ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín kan [129,699]. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe àpéjọ yìí jákèjádò ayé láwọn ibi tó ti ṣeé ṣe lákòókò ogun náà. Lákòókò yẹn, èrò ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà ni pé ńṣe ni ogun náà yóò máa le sí í títí tí yóò fi yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà, “Ǹjẹ́ Àlàáfíà Lè Wà Pẹ́?,” ńṣe ni wọ́n ń hára gàgà láti gbọ́ àlàyé tó máa wáyé. Báwo ni ààrẹ tuntun fún Watch Tower Society, N. H. Knorr ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà nígbà tó jẹ́ pé òdìkejì rẹ̀ ló dà bíi pé àwọn orílẹ̀-èdè máa rí?a Ìdí ni pé ẹgbẹ́ Jòhánù ń “fún” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.”—Hébérù 2:1; 2 Pétérù 1:19.
4 Báwo ni àsọyé náà “Ǹjẹ́ Àlàáfíà Lè Wà Pẹ́?” ṣe ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ náà? Nínú àsọyé náà, N. H. Knorr fi hàn kedere pé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó wà nínú Ìṣípayá 17:3. Lẹ́yìn náà, ó wá sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ò ṣe ní fararọ fún un, ó sì gbé ìyẹn ka ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì sọ fún Jòhánù, pé: “Ẹranko ẹhànnà tí ìwọ rí ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí, síbẹ̀ ó máa tó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, yóò sì kọjá lọ sínú ìparun.”—Ìṣípayá 17:8a.
5. (a) Báwo ló ṣe jẹ́ pé “ẹranko ẹhànnà [náà] . . . ti wà tẹ́lẹ̀” àti lẹ́yìn náà tí “kò sí”? (b) Báwo ní N. H. Knorr ṣe dáhùn ìbéèrè náà, “Ǹjẹ́ ìmùlẹ̀ náà yóò máa wà nínú kòtò títí lọ?”
5 “Ẹranko ẹhànnà [náà] . . . ti wà tẹ́lẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó ti wà tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti January 10, 1920. Nígbà yẹn, orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] ló wà nínú ìmùlẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n, níkọ̀ọ̀kan, Japan, Jámánì, àti Ítálì yọwọ́yọsẹ̀, nígbà tó yá, wọ́n yọ Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí kúrò nínú Ìmùlẹ̀ náà. Ní September 1939, aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tó jẹ́ olórí Ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì bẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì.b Nígbà tí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti kùnà láti mú kí àlàáfíà wà lórí ilẹ̀ ayé, ó rì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, kò lè ṣe nǹkan kan mọ́. Nígbà tó fi máa di 1942, ó ti dohun ìtàn. Àkókò oníyánpọnyánrin yẹn gan-an ni Jèhófà túmọ̀ ìran náà fáwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, kò túmọ̀ rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn tàbí lẹ́yìn náà! Ní Àpéjọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun ti Ìjọba Ọlọ́run, N. H. Knorr polongo pé “ẹranko ẹhànnà [náà] . . . kò sí” bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ. Lẹ́yìn náà ó béèrè pé, “Ǹjẹ́ ìmùlẹ̀ náà yóò máa wà nínú kòtò títí lọ?” Ó wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìṣípayá 17:8, ó sì dáhùn pé: “Àjọ àpapọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè náà yóò tún fara hàn.” Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn, èyí tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run kì í kùnà!
Bó Ṣe Jáde Látinú Ọ̀gbun Àìnísàlẹ̀
6. (a) Ìgbà wo ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jáde láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, orúkọ tuntun wo sì ni wọ́n fún un? (b) Kí nìdí tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi jẹ́ ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí?
6 Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ lóòótọ́. Ní June 26, 1945, afẹfẹyẹ̀yẹ̀ aláriwo ni àádọ́ta [50] orílẹ̀-èdè fi kéde ìbẹ̀rẹ̀ ìdìbò tí wọ́n fi fọwọ́ sí Ìwé Ìdásílẹ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní San Francisco, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ní ojúṣe àjọ náà ni “láti rí i pé mìmì kan ò mi àlàáfíà àti ààbò àgbáyé.” Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi jọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Láwọn ọ̀nà kan, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní . . . Ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n para pọ̀ dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ náà ló para pọ̀ dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀. Bíi ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìdí tí wọ́n fi dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ ni kó lè máa rí i pé àlàáfíà wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn ẹ̀ka pàtàkì-pàtàkì tí ń bẹ nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.” Nítorí náà, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà nínú àjọ yìí jẹ́ nǹkan bí igba ó dín mẹ́wàá [190], èyí tó pọ̀ fíìfíì ju orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] tó wà nínú Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè; yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ kó máa ṣe pọ̀ ju ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ.
7. (a) Ọ̀nà wo làwọn olùgbé ilẹ̀ ayé fi ṣe kàyéfì tí wọ́n sì kan sáárá sí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó sọ jí náà? (b) Kí ló jẹ́ àléèbá fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kí sì ni akọ̀wé àgbà àjọ yẹn tẹ́lẹ̀ rí sọ nípa èyí?
7 Nígbà tí wọ́n dá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, àwọn èèyàn sọ nǹkan ńláńlá tí wọ́n nírètí pé á gbé ṣe. Èyí mú ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì náà sọ ṣẹ, pé: “Nígbà tí wọ́n bá sì rí bí ẹranko ẹhànnà náà ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò sí, síbẹ̀ tí yóò tún wà, àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò ṣe kàyéfì lọ́nà ìkansáárá, ṣùgbọ́n a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:8b) Àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé kan sáárá sí àjọ ńlá tuntun yìí, tí wọ́n fi ilé gàgàrà gagara kan ṣe oríléeṣẹ́ rẹ̀ ní East River ní New York. Ṣùgbọ́n ohun àléèbá ni ojúlówó àlàáfíà àti ààbò jẹ́ fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè o. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ní ọ̀rúndún ogún, ìlànà ‘tó o bá ló o fẹ́ pa mí run, àá jọ para wa run ni’ [“mutual assured destruction” tí ìkékúrú rẹ̀ jẹ́ MAD] làwọn orílẹ̀-èdè alágbára fi ń halẹ̀ mọ́ ara wọn kí àlàáfíà lè wà láyé. Ìlànà MAD yìí ni pé bí orílẹ̀-èdè alágbára kan bá yin ohun ìjà runlé-rùnnà sí orílẹ̀-èdè kan, kí ó mọ̀ dájú pé àwọn ọ̀tà máa yin irú ẹ̀ padà sórílẹ̀-èdè tòun. Abájọ tí ṣíṣe ohun ìjà ogun fi ń pọ̀ sí i. Ní 1985, ìyẹn lẹ́yìn ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì [40] ọdún tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti ń gbìyànjú pé kí àlàáfíà wà láyé, Javier Pérez de Cuéllar tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àjọ náà nígbà yẹn, dárò pé: “Àkókò tá a wà yìí jẹ́ sànmánì àwọn oníwà ẹhànnà bíi tàwọn ìgbà kan, a ò sì mọ nǹkan tá a lè ṣe sí i.”
8, 9. (a) Kí nìdí tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò fi lè fòpin sí ìṣòro ayé, kí sì ni yóò ṣẹlẹ̀ sí i láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tí a kò fi kọ orúkọ àwọn tó ṣe ìdásílẹ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti orúkọ àwọn tó ń kan sáárá sí i sínú “àkájọ ìwé ìyè” Ọlọ́run? (d) Kí ni Ìjọba Jèhófà yóò ṣe láṣeyọrí?
8 Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò lè fòpin sí ìṣòro ayé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹni tó ṣẹ̀dá ọmọ aráyé kọ́ ló dá a sílẹ̀. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ò ní wà pẹ́, nítorí àṣẹ Ọlọ́run ni pé ‘yóò kọjá lọ sínú ìparun.’ Orúkọ àwọn tó dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ àti orúkọ àwọn tó ń kan sáárá sí i kò sí nínú ìwé ìyè Ọlọ́run. Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ná, báwo làwọn èèyàn wọ̀nyí, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àtẹni kíkú, tí ọ̀pọ̀ lára wọn sì ń pẹ̀gàn orúkọ Jèhófà, ṣe lè fi Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣàṣeyọrí ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun á ṣe láìpẹ́, àmọ́ pé òun ò ní tipasẹ̀ èèyàn ṣe é bí kò ṣe nípasẹ̀ Ìjọba Kristi Ọlọ́run?—Dáníẹ́lì 7:27; Ìṣípayá 11:15.
9 Ní tòdodo, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jẹ́ ayédèrú Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run. Nǹkan àbùkù ló sì jẹ́ sí Jésù Kristi Ọmọ Aládé Àlàáfíà tí Ọlọ́run fi jẹ ọba Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run yìí, tó jẹ́ pé ìjọba rẹ̀ ò ní dópin. (Aísáyà 9:6, 7) Bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè bá tiẹ̀ ṣètò àlàáfíà onígbà díẹ̀, kò ní pẹ́ tí ogun á tún fi rú yọ. Àwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ò lè ṣe kí wọ́n má jagun nítorí ó ti mọ́ wọn lára. Ìṣípayá sọ pé “a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” Ìjọba Jèhófà tí Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀ yóò mú àlàáfíà tí ò lópin wá sórí ilẹ̀ ayé, kì í wá ṣe ìyẹn nìkan, yóò tún jí àwọn òkú dìde lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, ìyẹn òkú àwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo tí wọ́n wà ní ìrántí Ọlọ́run. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Lára àwọn tó máa ní àjíǹde yìí ni gbogbo àwọn tó dúró gbọn-in nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìfi àtakò tí Sátánì àti irú-ọmọ rẹ̀ ṣe sí wọn pè, àtàwọn tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fi hàn bóyá wọ́n á jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run. Ó hàn gbangba pé orúkọ àwọn tí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní kúrò nínú Bábílónì Ńlá tàbí orúkọ ẹnikẹ́ni tí ò bá yéé jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà kò ní wọ ìwé ìyè Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 32:33; Sáàmù 86:8-10; Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 16:2; 17:5.
Àlàáfíà àti Ààbò—Ìrètí Asán
10, 11. (a) Kí ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè polongo ní 1986, kí sì làwọn orílẹ̀-èdè ṣe? (b) “Àwùjọ ìsìn” mélòó ló pé jọ sí Ásísì ní Ítálì láti gbàdúrà pé kí àlàáfíà wà, ṣé Ọlọ́run sì máa ń dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Ṣàlàyé.
10 Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbìyànjú láti mú kó túbọ̀ dá àwọn èèyàn lójú pé ìrètí ń bẹ, ó polongo pé 1986 jẹ́ “Ọdún Àlàáfíà Kárí Ayé,” ohun tó sì fi ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ ìpolongo rẹ̀ ni, “A Fẹ́ Rí I Pé Mìmì Kan Ò Mi Àlàáfíà àti Ọjọ́ Ọ̀la Ọmọ Aráyé.” Wọ́n sọ fáwọn orílẹ̀-èdè tó ń jagun pé kí wọ́n dáwọ́ ogun dúró, ó kéré tán fún ọdún kan. Kí làwọn orílẹ̀-èdè náà wá ṣe? Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àlàáfíà Àgbáyé ròyìn pé ní 1986 nìkan, ó tó mílíọ̀nù márùn-ún [5,000,000] èèyàn tí ogun pa! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe àkànṣe owó ẹyọ àti òǹtẹ̀ ìrántí ọdún àlàáfíà yìí, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè ò ṣe ohun tó máa mú kọ́wọ́ wọn tẹ àlàáfíà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọdún yẹn. Àmọ́, ńṣe làwọn ìsìn ayé bẹ̀rẹ̀ sí í polongo ọdún yẹn lóríṣiríṣi ọ̀nà, torí ohun táwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí kúkú ń wá ni bí àjọṣe á ṣe wà láàárín àwọn àti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ní January 1, 1986, Póòpù John Paul Kejì gbóṣùbà fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pé ó ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́, ó sì wá ya ọdún tuntun náà sọ́tọ̀ pé ó jẹ́ ọdún àlàáfíà. Lẹ́yìn náà, ní October 27, ó pe àwọn aṣáájú ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsìn ayé jọ sí Ásísì ní Ítálì, kí wọ́n lè gbàdúrà pé kí àlàáfíà wà.
11 Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Ó dáa, Ọlọ́run wo làwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn gbàdúrà sí? Bó o bá bi wọ́n léèrè, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan máa sọ. Ǹjẹ́ àgbájọ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọlọ́run kan wà tó lè gbọ́ onírúurú àdúrà tí wọ́n gbà lóríṣiríṣi ọ̀nà kó sì dáhùn rẹ̀? Mẹ́talọ́kan àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbàdúrà náà ń jọ́sìn.c Àwọn onísìn Búdà, Híńdù, àtàwọn míì gba onírúurú àdúrà sí ọ̀kẹ́ àìmọye ọlọ́run. Lápapọ̀, “àwùjọ ìsìn” méjìlá ló pé jọ, àwọn to sì ṣojú fún wọn ni àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn bíi Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Áńgílíkà ní Canterbury, Dalai Lama onísìn Búdà, Bíṣọ́ọ̀bù kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ojúbọ Ṣintó ní Tokyo, àwọn abọgibọ̀pẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà, àtàwọn Àmẹ́ríńdíà méjì tí wọ́n dé ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n fi ìyẹ́ ṣe sórí. Lọ́rọ̀ kan ṣá, àpéjọ yẹn jojú ní gbèsè ó sì mú kí tẹlifíṣọ̀n rí ìròyìn tó fakíki gbé jáde. Ọ̀kan lára àwọn àwùjọ náà gbàdúrà láìdákẹ́ fún wákàtí méjìlá. (Fi wé Lúùkù 20:45-47.) Síbẹ̀, ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú ọ̀pọ̀ àdúrà tí wọ́n gbà yẹn kọjá àwọsánmà? Rárá o. A óò rí ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ní ìpínrọ̀ tó kàn.
12. Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi dáhùn àdúrà àlàáfíà táwọn aṣáájú ìsìn ayé gbà?
12 Àwọn onísìn tí póòpù pè yẹn ò ṣe bíi tàwọn tó ń “rìn ní orúkọ Jèhófà,” ìkankan wọn ò gbàdúrà sí Jèhófà, Ọlọ́run alààyè tí orúkọ rẹ̀ fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Míkà 4:5; Aísáyà 42:8, 12)d Wọn ò para pọ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run lórúkọ Jésù, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ò tiẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. (Jòhánù 14:13; 15:16) Kò sí ọ̀kan nínú wọn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe lákòókò wa yìí, ìyẹn ni pé ká máa pòkìkí jákèjádò ayé pé Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀ ni ojúlówó ìrètí ayé, kì í ṣe pé ká máa pòkìkí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. (Mátíù 7:21-23; 24:14; Máàkù 13:10) Àní àwọn ìsìn ayé yìí lọ́wọ́ sí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ogun ọlọ́gbàrá ẹ̀jẹ̀, tó fi mọ́ ogun àgbáyé méjèèjì tó jà ní ọ̀rúndún ogún. Ohun tí Ọlọ́run sì sọ fún irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ ni pé: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.”—Aísáyà 1:15; 59:1-3.
13. (a) Kí ni dídarapọ̀ táwọn aṣáájú ìsìn ayé dara pọ̀ mọ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà fi hàn? (b) Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wo ni igbe fún àlàáfíà yóò jálẹ̀ sí?
13 Bákan náà, báwọn aṣáájú ìsìn ayé ṣe dara pọ̀ mọ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè láti bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà lákòókò yìí fi nǹkan kan hàn. Àwọn aṣáájú ìsìn náà yóò fẹ́ láti darí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún àǹfààní ara wọn, pàápàá lóde òní tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ wọn ń pa ìsìn tì. Bíi tàwọn aláìṣòótọ́ aṣáájú Ísírẹ́lì ayé àtijọ́, wọ́n ń kéde pé, “‘Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!’ nígbà tí kò sí àlàáfíà.” (Jeremáyà 6:14) Ó dájú pé igbe wọn fún àlàáfíà ò ní yéé dún, ńṣe ni yóò máa dún sókè sí i láti fi hàn pé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ yóò nímùúṣẹ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí obìnrin tí ó lóyún; wọn kì yóò sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 Tẹsalóníkà 5:2, 3.
14. Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe kí igbe “Àlàáfíà àti ààbò!” gbà dún, kí sì lẹnì kan lè ṣe tí ìyẹn ò fi ní tàn án jẹ?
14 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn olóṣèlú ti lo gbólóhùn náà, “àlàáfíà àti ààbò” láti fi ṣàpèjúwe oríṣiríṣi ohun tí àwọn ènìyàn ń gbèrò láti ṣe. Ǹjẹ́ akitiyan tí àwọn aṣáájú ayé ń ṣe yìí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmúṣẹ 1 Tẹsalóníkà 5:3? Àbí gbankọgbì ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa gbàfiyèsí gbogbo ayé ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lẹ́yìn tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì bá ṣẹ tán tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣẹ lọ́wọ́ la sábà máa ń lóye wọn ní kíkún, a ní láti ṣe sùúrù ká wo ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí. Àmọ́, ó dá àwọn Kristẹni lójú pé bí ayé tiẹ̀ ń sọ pé ọwọ́ àwọn tẹ àlàáfíà àti ààbò lọ́nà kan tàbí òmíràn, ohunkóhun ò ní yí padà. Ìdí ni pé, ìmọtara-ẹni-nìkan, ìkórìíra, ìwà ọ̀daràn, fífọ́ tí ìdílé ń fọ́, ìṣekúṣe, àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú á ṣì máa ṣẹlẹ̀. Ìdí nìyẹn tí kò fi yẹ kí igbe “àlàáfíà àti ààbò” kankan tan ìwọ jẹ tó o bá ń wà lójúfò láti mọ ìtumọ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé tó o sì ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Máàkù 13:32-37; Lúùkù 21:34-36.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a J. F. Rutherford kú ní January 8, 1942, N. H. Knorr sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Watch Tower Society.
b Ní November 20, 1940, Jámánì, Ítálì, Japan, àti Hungary fọwọ́ sí ìwé láti dá “Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tuntun” kan sílẹ̀. Ní ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà, Vatican kéde ìsìn Máàsì àti àdúrà fún àlàáfíà ìsìn àti fún ètò àwọn nǹkan tuntun. Àmọ́ “Ìmùlẹ̀ tuntun” yẹn ò fìdí múlẹ̀.
c Ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan wá láti Bábílónì ayé ọjọ́un tí wọ́n ti ń jọ́sìn ọlọ́run mẹ́ta alápapọ̀, ìyẹn, Shamash ọlọ́run oòrùn, Sin ọlọ́run òṣùpá, àti Ishtar ọlọ́run ìràwọ̀. Báwọn ará Íjíbítì náà ṣe ṣe nìyẹn, wọ́n jọ́sìn ọlọ́run Osiris, Isis, àti Horus. Orí mẹ́ta ni wọ́n fi hàn pé Asshur tó jẹ́ olú ọlọ́run orílẹ̀-èdè Ásíríà ní. Ohun táwọn Kátólíìkì náà sì ṣe nìyẹn, wọ́n gbé àwọn àwòrán tó fi Ọlọ́run hàn bí olórí mẹ́ta sínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn.
d Ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Third New International Dictionary ti ọdún 1993 sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ni “ẹni tá a mọ̀ sí Ọlọ́run gíga jù lọ, òun sì ni Ọlọ́run kan ṣoṣo tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jọ́sìn.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 250]
Òdì Kejì “Àlàáfíà”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún 1986 ni àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè polongo pé ó jẹ́ Ọdún Àlàáfíà Kárí Ayé, ńṣe ni ìdíje àwọn ohun ìjà apanirun peléke sí i. Ìwé World Military and Social Expenditures 1986 pèsè àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó gbàrònú wọ̀nyí:
Ní 1986 àwọn ìnáwó ológun kárí ayé tó bílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900,000,000,000] owó dọ́là.
Owó tí wọ́n ná sórí àwọn ológun kárí ayé ní wákàtí kan ṣoṣo ì bá ti tó láti fi pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára fún mílíọ̀nù mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500,000] tó ń kú lọ́dọọdún látàrí àrùn tí ń gbèèràn tí ì bá má ṣẹlẹ̀.
Kárí ayé, ẹnì kan nínú ẹni márùn-ún wà nínú ipò òṣì paraku. Gbogbo àwọn èèyàn tí ebi pa wọ̀nyẹn ni wọn ì bá ti fi owó tí ayé ná sórí àwọn ohun ìjà ní ọjọ́ méjì bọ́ fún ọdún kan.
Agbára ìbúgbàù tó wà nínú àpapọ̀ àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tí ayé ní fi ìlọ́po ọgọ́jọ mílíọ̀nù [160,000,000] ju ti ìbúgbàù iléeṣẹ́ ẹ̀rọ Chernobyl lọ.
Bọ́ǹbù runlé-rùnnà kan ṣoṣo tó ní agbára ìbúgbàù tó fi ìlọ́po ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ìgbà lágbára ju ti bọ́ǹbù tá a jù sí ìlú Hiroshima ní 1945 lọ ń bẹ lọ́wọ́ ọmọ aráyé.
Àkójọ àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tó wà lọ́wọ́ ní ohun tó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ irú àdó olóró tí wọ́n jù sí ìlú Hiroshima lọ. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ìgbà ni àpapọ̀ agbára ìbúgbàù wọn fi ju ti àwọn bọ́ǹbù tí wọ́n jù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tó pa mílíọ̀nù méjìdínlógójì [38] èèyàn.
Ogun ti túbọ̀ ń wáyé léraléra jù wọ́n sì ń gbẹ̀mí èèyàn jù. Díẹ̀ ni àròpọ̀ iye àwọn tí ogun pa fi dín ní mílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ó sì fi díẹ̀ dín ní mílíọ̀nù mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] láàárín ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún ogún. Láti ọ̀rúndún kejìdínlógún, àwọn tógun ń pa ti yára fi ìlọ́po mẹ́fà ju iye àwọn èèyàn tó wà láyé lọ. Ìlọ́po mẹ́wàá ni iye àwọn tí ń kú nínú ogun kọ̀ọ̀kan ní ọ̀rúndún yìí tá a bá fi wé ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 247]
Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà ṣe sọ, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àmọ́ ó sọ jí padà gẹ́gẹ́ bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 249]
Ní ìlú Ásísì lórílẹ̀-èdè Ítálì, àwọn aṣojú ìsìn ayé gba ọ̀pọ̀ àdúrà onídàrúdàpọ̀ láti ṣètìlẹyìn fún “Ọdún Àlàáfíà” àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, àmọ́ kò sí ọ̀kan nínú wọn tó gbàdúrà sí Jèhófà, Ọlọ́run alààyè
-
-
Pípa Bábílónì Ńlá RunÌṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
-
-
Orí 35
Pípa Bábílónì Ńlá Run
1. Báwo ni áńgẹ́lì náà ṣe ṣàlàyé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yẹn, irú ọgbọ́n wo la sì nílò láti lóye àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ inú Ìṣípayá?
ÁŃGẸ́LÌ náà tún ṣàlàyé síwájú sí i fún Jòhánù nípa ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí Ìṣípayá 17:3 sọ náà, ó ní: “Níhìn-ín ni ibi tí làákàyè tí ó ní ọgbọ́n ti wọlé: Orí méje náà túmọ̀ sí òkè ńlá méje, níbi tí obìnrin náà jókòó lé. Ọba méje ni ó sì ń bẹ: márùn-ún ti ṣubú, ọ̀kan wà, ọ̀kan tí ó kù kò tí ì dé, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dé, yóò dúró fún ìgbà kúkúrú.” (Ìṣípayá 17:9, 10) Ọgbọ́n tó wá látòkè ni áńgẹ́lì yìí ń sọ, ìyẹn ọgbọ́n kan ṣoṣo tó lè mú wa lóye àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ inú ìwé Ìṣípayá. (Jákọ́bù 3:17) Ọgbọ́n yìí ló ń mú kí ẹgbẹ́ Jòhánù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lóye bí àkókò tá à ń gbé yìí ti ṣe pàtàkì tó. Ó ń jẹ́ káwọn tó ń fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà mọrírì àwọn ìdájọ́ Jèhófà tó máa wáyé láìpẹ́, ó sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè bẹ̀rù Jèhófà lọ́nà tó yẹ. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 9:10 ṣe wí: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.” Kí ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣí payá fún wa nípa ẹranko ẹhànnà yìí?
2. Kí ni ìtumọ̀ orí méje ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, báwo ló sì ṣe jẹ́ pé “márùn-ún ti ṣubú, [tí] ọ̀kan [sì] wà”?
2 Orí méje ẹranko tó rorò yẹn túmọ̀ sí “òkè ńlá” méje, tàbí “ọba” méje. Ìwé Mímọ́ lo èdè méjèèjì náà láti tọ́ka sí agbára ìṣàkóso. (Jeremáyà 51:24, 25; Dáníẹ́lì 2:34, 35, 44, 45) Bíbélì mẹ́nu kan agbára ayé mẹ́fà tí wọ́n ti ní ipa kan tàbí òmíràn lórí ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn agbára ayé náà ni: Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, àti Róòmù. Lákòókò tí Jòhánù rí ìran Ìṣípayá yìí, márùn-ún lára àwọn agbára ayé náà ò sí mọ́, Róòmù ló wà nípò gẹ́gẹ́ bí agbára ayé nígbà náà. Èyí bá gbólóhùn náà mu pé, “márùn-ún ti ṣubú, ọ̀kan wà.” Ṣùgbọ́n èwo ni “ọ̀kan tí ó kù” tí ò tíì dé?
3. (a) Báwo ni Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣe pín sí méjì? (b) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé ní apá ti Ìwọ̀ Oòrùn? (d) Kí ló yẹ kó jẹ́ èrò wa nípa àgbègbè tí wọ́n ń pè ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́?
3 Ilẹ̀ Ọba Róòmù wà fúngbà pípẹ́, kódà ó tiẹ̀ tún gbòòrò sí i fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Jòhánù pàápàá. Lọ́dún 330 Sànmánì Kristẹni, Olú Ọba Kọnsitatáìnì sọ ìlú Bìsáńṣíọ̀mù di olú ìlú rẹ̀ dípò ìlú Róòmù, ó sì yí orúkọ ìlú yìí padà sí Kọnsitantinópù. Nígbà tó di ọdún 395 Sànmánì Kristẹni ilẹ̀ ọba Róòmù pín sí méjì, ó di Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìlà Oòrùn àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìwọ̀ Oòrùn. Ọba kan tó ń jẹ́ Alaric ṣẹ́gun ìlú Róòmù lọ́dún 410 Sànmánì Kristẹni. Alaric yìí jẹ́ ọba àwọn Visigoth tí í ṣe ẹ̀yà kan nílẹ̀ Jámánì tí wọ́n di ara ẹ̀ya ìsìn Kristẹni kan tí Arius dá sílẹ̀. Àwọn ẹ̀yà kan nílẹ̀ Jámánì táwọn náà jẹ́ “Kristẹni” ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè Sípéènì àti ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbègbè tí Róòmù ń ṣàkóso ní Àríwá Áfíríkà. Àwọn ọ̀rúndún kan wà tí nǹkan ò fara rọ nílẹ̀ Yúróòpù, tó jẹ́ pé rògbòdìyàn òun wàhálà ṣíṣe onírúurú àtúntò ni ṣáá. Àwọn olú ọba alágbára bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìwọ̀ Oòrùn, irú bíi Charlemagne tó bá Póòpù Leo Kẹta wọnú àdéhùn ní ọ̀rúndún kẹsàn-án àti Frederick Kejì tó ṣàkóso ní ọ̀rúndún kẹtàlá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ ni wọ́n ń pe àgbègbè tí wọ́n ṣàkóso lé lórí, síbẹ̀ ó kéré jọjọ bá a bá fi wé ibi tí ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti tẹ́lẹ̀ dé nígbà tó gbòòrò jù lọ. Àgbègbè tí wọn ṣàkóso lé lórí tí wọn pè ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ kì í ṣe ilẹ̀ ọba tuntun, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n kàn ṣàtúnṣe sí ilẹ̀ ọba ti tẹ́lẹ̀ tàbí bíi pé ilẹ̀ ọba ti tẹ́lẹ̀ náà ló ṣì wà.
4. Àwọn àṣeyọrí wo ni apá kan Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìlà Oòrùn ṣe, ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀ sí púpọ̀ lára àwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù ìgbàanì ní Àríwá Áfíríkà, Sípéènì, àti Síríà?
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wàhálà ń wáyé láàárín Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìlà Oòrùn tí ibùjókòó ìjọba rẹ̀ wà ní Kọnsitantinópù àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti Ìwọ Oòrùn, apá ti Ìlà Oòrùn ń bá ìṣàkóso rẹ̀ lọ. Ní ọ̀rúndún kẹfà, olú ọba ti Ìlà Oòrùn tó ń jẹ́ Justinian Kìíní ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ àgbègbè ní Àríwá Áfíríkà, ó sì tún dá sí ọ̀ràn orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Ítálì. Ní ọ̀rúndún keje, Justinian Kejì gba gbogbo ilẹ̀ tó wà ní Makedóníà padà èyí táwọn ẹ̀yà Slav tó ṣẹ́gun wọn tẹ́lẹ̀ gbà. Ṣùgbọ́n, nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹjọ, púpọ̀ lára ibi tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù ìgbàanì ní Àríwá Áfíríkà, Sípéènì, àti Síríà ti kúrò lábẹ́ Kọnsitantinópù àti Róòmù, ó sì ti di tàwọn ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàkóso.
5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́gun ìlú Róòmù lọ́dún 410 Sànmánì Kristẹni, báwo ló ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sí i kọjá kó tó di pé ọwọ́ àkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù kúrò láwùjọ pátápátá?
5 Ìlú Kọnsitantinópù ní tirẹ̀ wà bó ṣe wà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Lemọ́lemọ́ làwọn ará Páṣíà, Arébíà, Bulgaria, àti Rọ́ṣíà bá ìlú náà jà tí wọn ò borí ẹ̀ kí wọ́n tó wá ṣẹ́gun rẹ̀ lọ́dún 1203. Àmọ́ kì í ṣe àwọn Mùsùlùmí ló ṣẹ́gun rẹ̀, àwọn Ajagun ẹ̀sìn Kristẹni tó wá láti Ìwọ̀ Oòrùn nítorí àtigba Ilẹ̀ Mímọ́ padà ló ṣẹ́gun rẹ̀. Nígbà tó wá di ọdún 1453, Mehmed Kejì tó jẹ́ Mùsùlùmí tó ń ṣojú àwọn Ottoman ṣẹ́gun ìlú Kọnsitantinópù, kò sì pẹ́ tí ìlú náà fi di olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Ottoman, tàbí Turkey. Nípa báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́gun ìlú Róòmù lọ́dún 410 Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sí i ló kọjá kó tó di pé ọwọ́ àkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù kúrò láwùjọ pátápátá. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń kan ipa rẹ̀ lágbo ìsìn nípasẹ̀ àwọn póòpù tó ń ṣàkóso ní Róòmù àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn Ayé.
6. Àwọn orílẹ̀-èdè wo tó fẹ́ máa ṣàkóso gbogbo ayé ló bọ́ sójútáyé, èwo ló sì kẹ́sẹ járí jù lọ nínú wọn?
6 Ṣùgbọ́n, nígbà tó di ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún, àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà àtidá àwọn ilẹ̀ ọba tuntun sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara àwọn ibi tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ń ṣàkóso nígbà kan rí ni díẹ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ń gbèrò àtidi ilẹ̀ ọba wọ̀nyí, ìṣàkóso wọn yàtọ̀ sí ti Róòmù pátápátá. Ilẹ̀ Potogí, Sípéènì, Faransé àti Holland wá ń gbókèèrè ṣàkóso àwọn ilẹ̀ mìíràn. Ṣùgbọ́n Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló kẹ́sẹ járí jù lọ nítorí pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ń ṣàkóso lé lórí tó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ ọba gbígbòòrò kan tó jẹ́ pé bí oòrùn bá ṣe ń wọ̀ ní apá kan ilẹ̀ ọba rẹ̀ ni yóò máa yọ ní ibòmíràn. Díẹ̀díẹ̀ ni àkóso ilẹ̀ ọba yìí ń tàn títí tó fi dé ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti Àríwá, Áfíríkà, Íńdíà, àti Ìlà Oòrùn Éṣíà tó fi mọ́ àwọn Gúúsù Pàsífíìkì tó lọ salalu.
7. Báwo ló ṣe di pé orílẹ̀-èdè méjì para pọ̀ di agbára ayé, báwo sì ni Jòhánù ṣe sọ pé ‘orí’ keje, tàbí agbára ayé keje, ṣe máa pẹ́ tó?
7 Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kọkàndínlógún, díẹ̀ lára àwọn ibi tí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń gbókèèrè ṣàkóso lé lórí ní Amẹ́ríkà ti Àríwá ti kúrò lábẹ́ Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n sì para pọ̀ di Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ rògbòdìyàn òṣèlú ṣì ń bá a lọ láàárín orílẹ̀-èdè tuntun náà àti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣàkóso rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n Ogun Àgbáyé Kìíní jẹ́ kí orílẹ̀-èdè méjèèjì rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n jọ fìmọ̀ ṣọ̀kan, ni wọ́n bá jọ wọnú àjọṣe tó jinlẹ̀. Bí orílẹ̀-èdè méjèèjì, ìyẹn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó jẹ́ orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù lọ báyìí àti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣàkóso ibi tó pọ̀ jù lọ ṣe para pọ̀ di agbára ayé nìyẹn, tí wọ́n jọ ń ṣàkóso gbogbo ayé. Ìṣàkóso tá à ń sọ yìí ni ‘orí’ keje, tàbí agbára ayé keje, èyí tó ṣì wà lójú ọpọ́n ní àkókò òpin yìí, tó sì ń ṣàkóso àgbègbè táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní kọ́kọ́ fìdí múlẹ̀ sí. Bá a bá fi ìwọ̀n àkókò tí orí keje fi ṣàkóso wé èyí tí orí kẹfà fi ṣàkóso, “ìgbà kúkúrú” ni orí keje fi máa wà títí dìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run fi máa pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó kù run.
Ọba Kẹjọ Kẹ̀?
8, 9. Kí ni áńgẹ́lì náà pe ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò, ọ̀nà wo ló sì gbà jáde wá látinú àwọn méje náà?
8 Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé síwájú sí i fún Jòhánù pé: “Ẹranko ẹhànnà tí ó sì ti wà tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò sí, òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ni ọba kẹjọ, ṣùgbọ́n ó jáde wá láti inú àwọn méje náà, ó sì kọjá lọ sínú ìparun.” (Ìṣípayá 17:11) Ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò jẹ́ ère “ẹranko ẹhànnà” ìṣáájú tó gòkè wá “láti inú òkun.” Ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí “jáde wá láti inú” àwọn orí méje “ẹranko ẹhànnà” ìṣáájú náà, ìyẹn ni pé àwọn orí méje náà ló bí i, tàbí lédè mìíràn, àwọn ló jẹ́ kó wà. Ọ̀nà wo ló fi jáde wá látinú àwọn orí méje náà? Bó ṣe rí rèé: Lọ́dún 1919, Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ni agbára ayé tó ń ṣàkóso láàárín orí méje náà. Orí mẹ́fà tó ṣáájú ti subú, ipò agbára ayé sì ti bọ́ sọ́wọ́ orí méjì tó para pọ̀ yìí, òun ló sì ń ṣàkóso gbogbo ayé. Orí keje yìí, tó jẹ́ agbára ayé tó wà lójú ọpọ́n láàárín àwọn agbára ayé mẹ́fà tó ti wà tẹ́lẹ̀, ló fi Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ́lẹ̀, òun kan náà ló sì ń ṣe agbátẹrù Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó sì ń pèsè owó ìná fún un. Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, ìyẹn ọba kẹjọ tí í ṣe Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti lẹ́yìn náà, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, “jáde wá láti inú” orí méje àkọ́kọ́. Bá a bá wò ó lọ́nà yìí, gbólóhùn náà pé ó jáde wá látinú orí méje wà ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣípayá ìṣáájú tó sọ pé ẹranko ẹhànnà náà tó ní ìwo méjì bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn (ìyẹn agbára ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà, tí í ṣe orí keje ẹranko ẹhànnà ìṣáájú yẹn) ń ṣìpẹ̀ pé kí wọ́n ṣe ère náà, tó sì fún un ní ìyè.—Ìṣípayá 13:1, 11, 14, 15.
9 Láfikún, yàtọ̀ sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn orílẹ̀-èdè míì tó para pọ̀ dá àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ jẹ́ àwọn ìjọba tó ti ṣàkóso ní àwọn àgbègbè tí àwọn orí tàbí agbára ayé ti ìṣáájú wà tẹ́lẹ̀ rí, ìyẹn àwọn bíi Gíríìsì, orílẹ̀-èdè Iran (ìyẹn Páṣíà ayé ọjọ́un), àti Ítálì (ìyẹn agbára ayé Róòmù ayé ọjọ́un). Nígbà tó yá, àwọn orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba tó ń ṣàkóso àgbègbè tó wà lábẹ́ àwọn agbára ayé mẹ́fà ìṣáájú wá ń ṣètìlẹyìn fún ère ẹranko ẹhànnà náà. Lọ́nà yìí pẹ̀lú, a lè sọ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà jáde wá látinú àwọn agbára ayé méje náà.
10. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò “fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ni ọba kẹjọ”? (b) Báwo ni ọ̀kan lára àwọn aṣáájú Ìjọba Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí ṣe ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn?
10 Kíyè sí i pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí kan náà tún “ni ọba kẹjọ.” Nípa báyìí, ṣe ní wọ́n gbé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kalẹ̀ bí ìjọba tó ń ṣàkóso gbogbo ayé. Kódà nígbà mìíràn, ó máa ń ṣe bí ọba gbogbo ayé nípa bó ṣe máa ń rán àwọn ọmọ ogun lọ sójú ogun láti lọ pẹ̀tù sí ìjà àárín àwọn orílẹ̀-èdè, gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ní Kòríà, ní àgbègbè Sínáì tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí ká, láwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, àti ní Lẹ́bánónì. Ṣùgbọ́n ère ọba kan ló wulẹ̀ jẹ́. Bíi ti ère ìsìn, kò lè dá nǹkan gidi kan ṣe kò sì dá agbára kan ní yàtọ̀ sí èyí táwọn tó gbé e kalẹ̀ tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ bá fún un pé kó lò. Láwọn ìgbà míì, ó máa ń dà bíi pé ó rẹ ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ yìí; ṣùgbọ́n kò tíì sígbà kan táwọn orílẹ̀-èdè aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tó wà nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ pátápátá rí bí wọ́n ṣe kọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ tó fi lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. (Ìṣípayá 17:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn aṣáájú Ìjọba Soviet Union nígbà kan rí kò fara mọ́ èrò àwọn mìíràn lórí àwọn nǹkan kan, síbẹ̀ ní ọdún 1987, òun náà dara pọ̀ mọ́ àwọn póòpù Róòmù láti ṣètìlẹyìn fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Kódà ó ní “káwọn ṣètò ààbò tó máa délé dóko ní gbogbo ayé” káwọn sì fi sí ìkáwọ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Bí Jòhánù ṣe mọ̀ nígbà tó yá, ìgbà kan ń bọ̀ tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè á lo àṣẹ ńlá. Lẹ́yìn náà, òun fúnra ẹ̀ á “lọ sínú ìparun.”
Ọba Mẹ́wàá fún Wákàtí Kan
11. Kí ni áńgẹ́lì Jèhófà sọ nípa ìwo mẹ́wàá ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ náà tó ní àwọ̀ rírẹ̀dòdò?
11 Ní Ìṣípayá orí kẹrìndínlógún, áńgẹ́lì kẹfà àti ìkeje da àwọn àwokòtò ìbínú Ọlọ́run jáde. Èyí fi yé wa pé àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń kóra jọ sí ogun Ọlọ́run ní Amágẹ́dọ́nì àti pé ‘a óò rántí Bábílónì Ńlá níwájú Ọlọ́run.’ (Ìṣípayá 16:1, 14, 19) Ní báyìí, á fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ lé wọn lórí. Tún gbọ́ ohun tí áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Jòhánù. “Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí túmọ̀ sí ọba mẹ́wàá, tí kò tíì gba ìjọba, ṣùgbọ́n wọ́n gba ọlá àṣẹ bí ọba fún wákàtí kan pẹ̀lú ẹranko ẹhànnà náà. Àwọn wọ̀nyí ní ìrònú kan ṣoṣo, nítorí náà, wọ́n fún ẹranko ẹhànnà náà ní agbára àti ọlá àṣẹ wọn. Àwọn wọ̀nyí yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, ṣùgbọ́n, nítorí pé òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe bẹ́ẹ̀.”—Ìṣípayá 17:12-14.
12. (a) Kí ni ìwo mẹ́wàá náà túmọ̀ sí? (b) Ọ̀nà wo ni ìwo mẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ náà ò fi ‘tíì gba ìjọba’ ní ọ̀rúndún kìíní? (d) Báwo ni ìwo mẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe ní “ìjọba” kan nísinsìnyí, báwo ló sì ṣe máa pẹ́ tó?
12 Ìwo mẹ́wàá náà dúró fún gbogbo àwọn ìjọba tí wọ́n ń ṣàkóso báyìí lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n sì ń ṣètìlẹ́yìn fún ère ẹranko ẹhànnà náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lónìí ni ò sí nígbà ayé Jòhánù. Àwọn tó sì wà nígbà náà, irú bí Íjíbítì àti Páṣíà (tá a mọ̀ báyìí sí Iran), ní ètò ìjọba tó yàtọ̀ pátápátá lónìí. Fún ìdí yìí, ní ọ̀rúndún kìíní, ‘ìwo mẹ́wàá náà ò tíì gba ìjọba.’ Ṣùgbọ́n ní báyìí tá a ti wà ní ọjọ́ Olúwa, wọ́n ní “ìjọba” kan, tàbí agbára ìṣàkóso. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tuntun ló ti yọjú látàrí báwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá tí wọ́n jẹ́ agbókèèrè-ṣàkóso ṣe fọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n ti wà tipẹ́, ló máa bá ẹranko ẹhànnà náà ṣàkóso fún àkókò kúkúrú, ìyẹn “wákàtí kan” péré, kí Jèhófà tó mú òpin bá gbogbo ètò ìjọba ayé ní Amágẹ́dọ́nì.
13. Ọ̀nà wo ni ìwo mẹ́wàá náà gbà ní “ìrònú kan ṣoṣo,” kí sì ni èrò tí wọ́n ní yìí mú kó dájú pé wọ́n á ṣe sí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà?
13 Lónìí, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó lágbára jù lọ tó ń ti àwọn ìwo mẹ́wàá náà. Wọ́n ní “ìrònú kan ṣoṣo” ní ti pé dípò kí wọ́n tẹ́wọ́ gba Ìjọba Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n ń wá ọ̀nà bí àkóso tó wà níkàáwọ́ wọn ò ṣe ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Èyí ló mú kí wọ́n fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kí àlàáfíà lè wà kárí ayé, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn fúnra wọn á lè máa wà nìṣó. Irú èrò táwọn ìwo náà ní yìí ló jẹ́ kó dájú pé wọ́n á ta ko Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí í ṣe “Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba,” nítorí pé Jèhófà ti ṣètò bó ṣe máa mú kí Ìjọba rẹ̀ lábẹ́ Jésù Kristi rọ́pò gbogbo ìjọba wọ̀nyí láìpẹ́.—Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 24:30; 25:31-33, 46.
14. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fáwọn tó ń ṣàkóso ayé láti bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, kí ló sì máa yọrí sí?
14 Ó dájú pé kò sí nǹkan kan táwọn tó ń ṣàkóso ayé yìí lè fi Jésù ṣe. Wọ́n ò lè débi tó wà ní ọ̀run lọ́hùn-ún. Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin Jésù, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà, ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sì hàn gbangba pé, ọwọ́ rẹ̀ lè tó wọn. (Ìṣípayá 12:17) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwo náà ti ta kò wọ́n lọ́nà tó burú jáì, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun. (Mátíù 25:40, 45) Bó ti wù kó rí, kò ní pẹ́ tí àkókò fi máa tó fún Ìjọba Ọlọ́run láti “fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, [tí yóò] sì fi òpin sí gbogbo wọn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn ọba ilẹ̀ ayé á wá bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wọ̀yá ìjà, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láìpẹ́. (Ìṣípayá 19:11-21) Níbi tá a dé yìí, a ti kọ́ ohun tó pọ̀ tó láti mọ̀ pé àwọn orílẹ̀-èdè ò ní kẹ́sẹ járí. Àwọn àti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ìyẹn ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, ì bà á ní “ìrònú kan ṣoṣo” jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọn ò lè ṣẹ́gun “Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba,” bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò lè ṣẹ́gun “àwọn tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀,” tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé wà lára wọn. Àwọn náà á ti di aṣẹ́gun ní ti pé wọ́n á ti pa ìṣòtítọ́ wọn mọ́ láti fi hàn pé irọ́ làwọn ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Róòmù 8:37-39; Ìṣípayá 12:10, 11.
Bí Aṣẹ́wó Náà Ṣe Máa Pa Run
15. Kí ni áńgẹ́lì yẹn sọ nípa aṣẹ́wó náà, irú ẹ̀mí wo ló sọ pé ìwo mẹ́wàá àti ẹranko ẹhànnà náà máa ní sí i, kí ló sì sọ pé wọn máa ṣe fún un?
15 Àwọn èèyàn Ọlọ́run nìkan kọ́ ni ìwo mẹ́wàá náà máa bá ṣọ̀tá. Áńgẹ́lì náà wá dá Jòhánù padà sórí ọ̀rọ̀ aṣẹ́wó náà, ó ní: “Ó sì wí fún mi pé: ‘Àwọn omi tí ìwọ rí, níbi tí aṣẹ́wó náà jókòó, túmọ̀ sí àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n. Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí, àti ẹranko ẹhànnà náà, àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.’”—Ìṣípayá 17:15, 16.
16. Kí nìdí tí Bábílónì Ńlá ò fi ní lè gbójú lé àwọn omi rẹ̀ láti ṣètìlẹyìn fún un kí wọ́n sì dáàbò bò ó nígbà táwọn ìjọba ayé bá yíjú padà sí i lọ́nà rírorò?
16 Gẹ́lẹ́ bí Bábílónì ìgbàanì ṣe gbójú lé omi tó yí i ká gẹ́gẹ́ bí ààbò, bẹ́ẹ̀ náà ni Bábílónì Ńlá ṣe gbójú lé ọ̀kẹ́ àìmọye “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n” tí wọ́n wà nínú rẹ̀. Ó dáa tí áńgẹ́lì yìí kọ́kọ́ rán wá létí èyí, kó tó wá sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń múni gbọ̀n rìrì yìí, pé: Àwọn ìjọba òṣèlú ayé yìí á yíjú padà sí Bábílónì Ńlá lọ́nà rírorò. Kí ni gbogbo “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n” wọ̀nyẹn á wá rí ṣe sí i? Lọ́wọ́ tá a wà yìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń kìlọ̀ fún Bábílónì Ńlá pé omi odò Yúfírétì máa gbẹ. (Ìṣípayá 16:12) Omi wọ̀nyẹn ò ní sí mọ́ rárá. Wọn ò ní lè fún ohun ìríra àtayébáyé yẹn, ìyẹn aṣẹ́wó náà ní ìtìlẹyìn tó mọ́yán lórí ní wákàtí tó nílò ìrànlọ́wọ́ wọn.—Aísáyà 44:27; Jeremáyà 50:38; 51:36, 37.
17. (a) Kí nìdí tí ọlà Bábílónì Ńlá ò fi ní gbà á là? (b) Ọ̀nà wo ni òpin tó máa bá Bábílónì Ńlá fi máa jẹ́ ẹ̀tẹ́? (d) Yàtọ̀ sí ìwo mẹ́wàá náà, tàbí àwọn orílẹ̀-èdè, ohun mìíràn wo ló tún máa lọ́wọ́ sí ìparun Bábílónì Ńlá?
17 Ó dájú pé arabarìbì ọlà tí Bábílónì Ńlá ní ò ní lè gbà á là. Àfi tó bá tún máa mú kí ìparun ọ̀hún túbọ̀ yá torí ìran náà jẹ́ ká rí i pé nígbà tí wọ́n bá gbéjà kò ó lọ́nà rírorò nítorí kíkó tí wọ́n kórìíra rẹ̀, ṣe ni wọ́n á gba aṣọ ìgúnwà ayaba àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye tó wà lára ẹ̀. Wọn á kó ọlà rẹ̀ lọ. Wọ́n á ‘tú u sí . . . ìhòòhò,’ ní ti pé wọ́n á fi irú ẹni tó jẹ́ gan-an hàn. Ìparun yán-ányán-án yìí á mà ga o! Ẹ̀tẹ́ gbáà ni òpin rẹ̀ máa jẹ́. Wọ́n á ba tiẹ̀ jẹ́, wọ́n á “jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán,” wọ́n á sì sọ ọ́ di kìkì egungun aláìlẹ́mìí. Ní paríparí rẹ̀, wọ́n á “fi iná sun ún pátápátá.” Wọn ò ní sin ín nísin ẹ̀yẹ, ńṣe ni wọ́n á finá sun ún bí ìgbà téèyàn bá finá sun ẹran tó ní àjàkálẹ̀ àrùn lára kí àrùn náà má bàa ran èèyàn. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwo mẹ́wàá náà dúró fún nìkan kọ́ ló máa pa aṣẹ́wó ńlá náà run, ṣùgbọ́n “ẹranko ẹhànnà náà,” ìyẹn àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, pẹ̀lú máa dara pọ̀ mọ́ wọn láti pa á run. Ó máa fọwọ́ sí ìparun ìsìn èké. Kódà ṣáájú ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀ lára igba ó dín mẹ́wàá [190] orílẹ̀-èdè àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n wà nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti fi hàn nínú ìbò tí wọ́n dì pé àwọn kórìíra ìsìn, pàápàá ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.
18. (a) Kí ló ti jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe káwọn orílẹ̀-èdè gbéjà ko Bábílónì Ńlá? (b) Kí ló mú kí aṣẹ́wó ńlá náà kàgbákò tó burú bẹ́ẹ̀?
18 Kí ló jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè ṣe ohun tó burú bẹ́ẹ̀ sẹ́ni tó jẹ́ àlè wọn nígbà kan rí? Ohun tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí ti fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí Bábílónì Ńlá. Àtakò tí ìjọba ń ṣe sí ìsìn tí mú kí agbára tí ìsìn ní làwọn ilẹ̀ bí orílẹ̀-èdè Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí àti Ṣáínà dín kù gan-an. Láwọn ibi tí ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí kì í ṣe ara Kátólíìkì, pọ̀ sí ní Yúróòpù, ẹ̀mí àgunlá tó tàn kálẹ̀ àti iyè méjì táwọn èèyàn ní sí ìsìn ti sọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì dòfo, tó bẹ́ẹ̀ tí ìsìn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa rẹ́. Ọ̀tẹ̀ àti àìfohùnṣọ̀kan ti fọ́ ìsìn Kátólíìkì tó gbilẹ̀ rẹrẹẹrẹ, apá àwọn aṣáájú ìjọ náà ò sì ká a. Òtítọ́ kan la ò gbọ́dọ̀ gbójú fò dá, ìyẹn ni pé àgbákò ìkẹyìn tó máa bá Bábílónì Ńlá yìí ò ṣẹ̀yìn ìdájọ́ tí kò ṣeé yí padà tí Ọlọ́run mú wá sórí aṣẹ́wó ńlá náà.
Bí Ìrònú Ọlọ́run Ṣe Máa Ṣẹ
19. (a) Báwo la ṣe lè fi ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fún Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni ṣàlàyé irú ìdájọ́ tó máa ṣe fún aṣẹ́wó náà? (b) Kí ni Jerúsálẹ́mù tó dahoro, tí kò sí olùgbé kankan nínú rẹ̀ lẹ́yìn ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni ṣàpẹẹrẹ lákòókò tiwa yìí?
19 Báwo ni Jèhófà ṣe mú ìdájọ́ yìí ṣẹ? Ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì tó di apẹ̀yìndà lè jẹ́ ká lóye bó ṣe máa ṣe ti ọ̀tẹ̀ yìí, àwọn tó sọ nípa wọn pé: “Mo . . . ti rí àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ nínú àwọn wòlíì Jerúsálẹ́mù, ṣíṣe panṣágà àti rírìn nínú èké; wọ́n sì ti fún ọwọ́ àwọn aṣebi lókun kí olúkúlùkù wọn má bàa padà nínú ìwà búburú rẹ̀. Sí mi, gbogbo wọn dà bí Sódómù, àti àwọn olùgbé rẹ̀ bí Gòmórà.” (Jeremáyà 23:14) Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, Jèhófà lo Nebukadinésárì láti ‘bọ́ ẹ̀wù kúrò lọ́rùn’ ìlú panṣágà nípa tẹ̀mí yẹn ‘láti kó àwọn ohun èlò ẹlẹ́wà rẹ̀ lọ, àti láti fi í sílẹ̀ ní ìhòòhò àti ní ìhòòhò goloto.’ (Ìsíkíẹ́lì 23:4, 26, 29) Jerúsálẹ́mù ìgbà yẹn bá ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì òde òní mu, gẹ́gẹ́ bí ìran tí Jòhánù sì kọ́kọ́ rí, Jèhófà yóò fi irú ìyà kan náà jẹ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ìsìn èké yòókù. Bí Jerúsálẹ́mù ṣe dahoro tí ò sí olùgbé kankan nínú rẹ̀ lẹ́yìn ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni jẹ́ ká rí bí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe máa rí lẹ́yìn tí ọlà bá kúrò lára rẹ̀ tí àṣírí rẹ̀ sì wá tú lọ́nà tó máa tì í lójú. Bó sì ṣe máa rí fún ìyókù Bábílónì Ńlá náà nìyẹn.
20. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe fi hàn pé, lẹ́ẹ̀kan sí i Jèhófà yóò lo àwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso láti ṣèdájọ́? (b) Kí ni “ìrònú” Ọlọ́run? (d) Báwo làwọn orílẹ̀-èdè á ṣe mú “ìrònú kan ṣoṣo” tiwọn ṣẹ, ṣùgbọ́n ta lẹni náà gan-an tí wọ́n mú ìrònú rẹ̀ ṣẹ?
20 Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà yóò lo àwọn èèyàn tó jẹ́ olùṣàkóso láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. “Nítorí Ọlọ́run fi í sínú ọkàn-àyà wọn láti mú ìrònú òun ṣẹ, àní láti mú ìrònú kan ṣoṣo tiwọn ṣẹ nípa fífún ẹranko ẹhànnà náà ní ìjọba wọn, títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi di èyí tí a ṣe ní àṣeparí.” (Ìṣípayá 17:17) Kí ni “ìrònú” Ọlọ́run? Ìrònú Ọlọ́run ni láti ṣètò bí àwọn tó máa mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Bábílónì Ńlá ṣe máa para pọ̀, kí wọ́n lè pa á run pátápátá. Ó dájú pé ohun tó máa mú kí àwọn olùṣàkóso gbéjà kò ó ni láti mú “ìrònú kan ṣoṣo” tiwọn ṣẹ. Wọn á rò pé ire orílẹ̀-èdè àwọn làwọn ń wá báwọn ṣe gbéjà ko aṣẹ́wó ńlá náà. Wọ́n lè rò pé tí ìsìn kan tó wà lágbègbè àwọn bá ń wà nìṣó, á wu ìṣàkóso àwọn léwu. Ṣùgbọ́n Jèhófà gan-an lẹni tó máa mú káwọn alákòóso náà ṣe bẹ́ẹ̀; wọn á mú ìrònú Jèhófà ṣẹ ní ti pé wọ́n á pa ọ̀tá rẹ̀ tó jẹ́ panṣágà látọjọ́ tó ti pẹ́ run.—Fi wé Jeremáyà 7:8-11, 34.
21. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, ìyẹn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ló máa pa Bábílónì Ńlá run, kí ló hàn gbangba pé àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè?
21 Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn orílẹ̀-èdè máa lo ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà, ìyẹn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, láti pa Bábílónì Ńlá run. Kì í ṣe pé wọ́n ń ṣe ohun tó wù wọ́n, nítorí Jèhófà ló fi í sí wọn lọ́kàn “àní láti mú ìrònú kan ṣoṣo tiwọn ṣẹ nípa fífún ẹranko ẹhànnà náà ní ìjọba wọn.” Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn orílẹ̀-èdè á rí i kedere pé ó pọn dandan pé káwọn fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lókun. Wọn á fún un ní eyín, ká sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, nípa gbígbé àṣẹ àti agbára yòówù tí wọ́n ní fún un kó bàa lè yíjú padà sí ìsìn èké kó sì ṣẹ́gun rẹ̀ “títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi di èyí tí a ṣe ní àṣeparí.” Èyí ló máa sọ aṣẹ́wó àtayébáyé yìí di àwáàrí. À-kú-tún-kú ẹ̀ láé!
22. (a) Nínú Ìṣípayá 17:18, kí ni ọ̀nà tí áńgẹ́lì náà gbà parí gbólóhùn ẹ̀rí rẹ̀ fi hàn? (b) Ki làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nítorí rírí tá a rí ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ náà?
22 Bí ìgbà tí áńgẹ́lì náà fẹ́ tẹnu mọ́ bó ṣe dájú tó pé ìdájọ́ Jèhófà lórí gbogbo ìsìn èké àgbáyé máa ṣẹ ní kíkún, ó parí gbólóhùn ẹ̀rí rẹ̀ nípa wíwí pé: “Obìnrin tí ìwọ sì rí túmọ̀ sí ìlú ńlá títóbi tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:18) Bíi ti Bábílónì tó wà nígbà ayé Bẹliṣásárì, Ọlọ́run ti wọn Bábílónì Ńlá ‘wò lórí òṣùwọ̀n ó sì rí i pé kò kúnjú òṣùwọ̀n.’ (Dáníẹ́lì 5:27, The New English Bible) Ìdájọ́ ìkẹyìn tó máa wá sórí rẹ̀ máa yára kánkán. Ki làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nítorí rírí tá a rí ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ aṣẹ́wó ńlá àti ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà? À ń fi ìtara pòkìkí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà, a sì ń dá àwọn tó ń fi inú kan wá òtítọ́ kiri lóhùn “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.” (Kólósè 4:5, 6; Ìṣípayá 17:3, 7) Gẹ́gẹ́ bí orí tó tẹ̀ lé e ṣe máa jẹ́ ká mọ̀, gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ láti là á já nígbà tí Ọlọ́run bá ṣèdájọ́ aṣẹ́wó ńlá náà gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ní kíákíá!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 252]
Ìtòtẹ̀léra Àwọn Ọba Ayé Méje
ÍJÍBÍTÌ
ÁSÍRÍÀ
BÁBÍLÓNÌ
MÍDÍÀ ÀTI PÁṢÍÀ
GÍRÍÌSÌ
RÓÒMÙ
GẸ̀Ẹ́SÌ ÀTI AMẸ́RÍKÀ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 254]
“Òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ni ọba kẹjọ”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 255]
Wọ́n kẹ̀yìn sí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, “wọ́n fún ẹranko ẹhànnà náà ní agbára àti ọlá àṣẹ wọn”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 257]
Bí Jerúsálẹ́mù ìgbàanì ṣe pa run pátápátá ni ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ apá tó yọrí ọlá jù lọ nínú Bábílónì Ńlá náà ṣe máa pa run
-