Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 24, 2014.
- Kí ni Sátánì mú kí Éfà pọkàn pọ̀ lé lórí, kí sì ni bí Éfà ṣe jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà fi hàn? (Jẹ́n. 3:6) [Jan. 6, w11 5/15 ojú ìwé 16 sí 17 ìpínrọ̀ 5] 
- . Kí ló ṣeé ṣe kó ti mú kí Ébẹ́lì ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí sì ni àbájáde rẹ̀? (Jẹ́n. 4:4, 5; Héb. 11:4) [Jan. 6, w13 1/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4 sí 5] 
- Báwo làwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, tí kò fi ní máa wù wọ́n láti dà bí ‘àwọn alágbára ńlá’ àti “àwọn ọkùnrin olókìkí”? (Jẹ́n. 6:4) [Jan. 13, w13 4/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 2] 
- Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì àti ìyàwó rẹ̀ bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 19:14-17 àti 26? [Jan. 27, w03 1/1 ojú ìwé 16 sí 17 ìpínrọ̀ 20] 
- Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde àti nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe fún un pé irú ọmọ náà máa wá nípasẹ̀ Ísákì? (Jẹ́n. 22:1-18) [Feb. 3, w09 2/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 4] 
- Òótọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 25:23, tó sọ pé “ẹ̀gbọ́n ni yóò sì sin àbúrò”? [Feb. 10, w03 10/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2] 
- Kí ni ìtumọ̀ àlá tí Jékọ́bù lá tó ní ín ṣe pẹ̀lú àkàsọ̀, báwọn Bíbélì kan ṣe pè é? (Jẹ́n. 28:12, 13) [Feb. 10, w04 1/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 6] 
- Kí nìdí tí Jékọ́bù fi fẹ́ gba ère tẹ́ráfímù tí wọ́n jí náà pa dà? (Jẹ́n. 31:30-35) [Feb. 17, it-2-E ojú ìwé 186 ìpínrọ̀ 2] 
- Kí la kọ́ nínú ìdáhùn tí áńgẹ́lì kan fún Jékọ́bù bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 32:29? [Feb. 24, w13 8/1 ojú ìwé 10] 
- Kí ni ọ̀nà kan tá a lè gbà yẹra fún irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà? (Jẹ́n. 34:1, 2) [Feb. 24, w01 8/1 ojú ìwé 20 sí 21]