ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 124-ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 2
  • Ominira Lati Waasu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ominira Lati Waasu
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Wọ́n Pa Trujillo
  • Iṣẹ́ Ìwàásù Ń Tẹ̀ Síwájú
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 124-ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 2
Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 124

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Òmìnira Láti Wàásù

Wọ́n Pa Trujillo

Nígbà tó fi máa di ọdún 1960, àwọn tó ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba Trujillo lẹ́yìn odi àtàwọn tó ń ta kò ó lábẹ́lé túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Pẹ̀lú bí nǹkan ò ṣe fara rọ lórílẹ̀-èdè náà, Arákùnrin Milton Henschel wá síbẹ̀ láti oríléeṣẹ́ wa, ó sì bá wọn ṣe àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta ní oṣù January ọdún 1961. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún àti mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [957] làwọn tó gbọ́ àsọyé fún gbogbo èèyàn, àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] sì ṣèrìbọmi. Nígbà tí Arákùnrin Henschel fi wà níbẹ̀, ó bá àwọn ará ṣètò ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn àti bí wọ́n á ṣe tún máa bá iṣẹ́ náà lọ.

Graph tó wà ní ojú ìwé 124

Wọ́n yan alábòójútó àyíká méjì, ìyẹn Enrique Glass àti Julián López, pé kí wọ́n máa bẹ àwọn ìjọ wò. Julián sọ pé: “Méjì lára àwọn ìjọ tí mo máa ń bẹ̀ wò wà lápá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà àwọn yòókù sì wà ní àríwá. Àwọn ìjọ yòókù ní ìlà oòrùn àtàwọn tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè náà sì ni Enrique máa ń bẹ̀ wò.” Àwọn ìbẹ̀wò yẹn mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará túbọ̀ lágbára, ó sì mú kí àjọṣe tó wà láàárín àwọn ìjọ àti ètò Ọlọ́run pa dà bọ̀ sípò.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 127

Òkè: Ìgbà tí Salvino àti Helen Ferrari ń lọ sí Orílẹ̀-èdè Dominican lọ́dún 1961

Ní ọdún 1961, Salvino àti Helen Ferrari, tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejì ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì dé sí orílẹ̀-èdè náà. Ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Cuba wúlò gan-an fún iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí ńlá ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Nígbà tó yá, Arákùnrin Salvino di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè náà títí tó fi kú lọ́dún 1997. Helen sì ti lo èyí tó pọ̀ jù lára ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì.

Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn táwọn Ferrari dé ni àwọn alágbàpa fi òpin sí ìjọba Trujillo tó ń ni àwọn èèyàn lára nígbà tí wọ́n da ìbọn bo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì pa á ní ìpa ìkà ní alẹ́ May 30 ọdún 1961. Àmọ́ pípa tí wọ́n pa á kò mú kí nǹkan fara rọ lágbo òṣèlú orílẹ̀-èdè náà, torí náà, ogun abẹ́lé àti rògbòdìyàn òṣèlú ṣì ń han àwọn èèyàn léèmọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Iṣẹ́ Ìwàásù Ń Tẹ̀ Síwájú

Bí rògbòdìyàn náà ṣe ń lọ lọ́wọ́, àwọn míṣọ́nnárì púpọ̀ tún dé sí Orílẹ̀-èdè Dominican. Ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn tí wọ́n pa Trujillo ni wọ́n gbé William Dingman tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì àkọ́kọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, Estelle ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Thelma Critz àti Flossie Coroneos wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Puerto Rico. William sọ pé: “Rúkèrúdò ṣì wà lórílẹ̀-èdè náà nígbà tá a dé, àwọn sójà ṣì wà káàkiri. Wọ́n ń bẹ̀rù pé àwọn kan tún lè gbógun dìde, torí náà wọ́n ń yẹ ara gbogbo àwọn tó ń kọjá lójú pópó wò. Wọ́n dá wa dúró láwọn ibi mélòó kan tí wọ́n ti ń yẹ ọkọ̀ wò, wọ́n sì tú àwọn ẹrù wa lọ́kọ̀ọ̀kan. Gbogbo ẹrù wa pátá ni wọ́n kó jáde nínú báàgì.” Kò rọrùn rárá láti wàásù nílùú tí nǹkan ò ti fara rọ yìí.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 127

Ìsàlẹ̀: Thelma Critz pẹ̀lú Estelle àti William Dingman ṣì wà lórílẹ̀-èdè náà lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] tí wọ́n ti ń fìtara ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì

Arákùnrin William tún sọ pé: “Nígbà ìjọba apàṣẹwàá ti Trujillo, ohun tí wọ́n máa ń sọ fáwọn èèyàn ni pé ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Kọ́múníìsì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé èèyàn burúkú gbáà ni wá. . . . Àmọ́ a bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí wọ́n mú ẹ̀tanú yìí kúrò lọ́kàn wọn díẹ̀díẹ̀.” Bá a ṣe pa dà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wa lákọ̀tun yìí mú káwọn èèyàn púpọ̀ sí i tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí ọdún iṣẹ́ ìsìn 1961 fi máa parí, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] ló ti wà lórílẹ̀-èdè náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́