ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 145-ojú ìwé 149 ìpínrọ̀ 1
  • Wiwaasu Lede Creole Ti Haiti

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wiwaasu Lede Creole Ti Haiti
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Ìsọ̀rí
  • A Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Fi Èdè Creole ti Ilẹ̀ Haiti Wàásù
  • A Tún Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo Èdè Creole Ti Ilẹ̀ Haiti
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 145-ojú ìwé 149 ìpínrọ̀ 1
Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 148

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Wíwàásù Lédè Creole Ti Haiti

A Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Fi Èdè Creole ti Ilẹ̀ Haiti Wàásù

Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ gan-an láwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì. Àmọ́ bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, oríṣiríṣi èèyàn tí èdè wọn yàtọ̀ síra tún ń ṣí wá sí orílẹ̀-èdè náà, àwọn pẹ̀lú sì ń fetí sí ìhìn rere tó ń fún wọn nírètí. Lórílẹ̀-èdè Haiti tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Orílẹ̀-èdè Dominican, èdè Creole ti Haiti ni lájorí èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà kọ́ ni àjọṣe tó wà láàárín Orílẹ̀-èdè Dominican àti Haiti máa ń gún régé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ilẹ̀ Haiti ló ń ṣiṣẹ́ ní Orílẹ̀-èdè Dominican, iye wọn sì ti yára pọ̀ sí i lẹ́nu àìpẹ́ yìí.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì ni wọ́n máa ń ní kí àwọn ọmọ ilẹ̀ Haiti tó ń sọ èdè Creole dara pọ̀ mọ́ kí wọ́n lè rí ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí gbà. Àmọ́, kí wọ́n lè túbọ̀ ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, lọ́dún 1993, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní kí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní erékùṣù Guadeloupe rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe wá sí Orílẹ̀-èdè Dominican láwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti. Tọkọtaya Barnabé àti Germaine Biabiany wà lára àwọn tọkọtaya mẹ́ta tó yọ̀ǹda ara wọn láti lọ. Arákùnrin Barnabé sọ pé: “Ìwé pẹlẹbẹ méjì péré la kọ́kọ́ ní lédè Creole ti ilẹ̀ Haiti. Èdè Faransé làwọn ìwé yòókù. Torí náà, a tú gbogbo ìwé náà láti èdè Faransé sí èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti.”

Ní oṣù January ọdún 1996, akéde mẹ́sàn-án nílùú Higüey àtàwọn akéde mẹ́wàá míì nílùú Santo Domingo múra tán láti lọ ran àwùjọ tó ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti lọ́wọ́. Torí náà, wọ́n dá àwùjọ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ nílùú méjèèjì, kò sì pẹ́ tí àwùjọ méjèèjì fi di ìjọ. Àmọ́ àwọn ìjọ náà tú ká torí pé ọ̀pọ̀ ọmọ ilẹ̀ Haiti ló fẹ́ kọ́ èdè Sípáníìṣì, torí náà, wọ́n yàn láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì. Arákùnrin Barnabé sọ pé: “Lẹ́yìn tá a bá àwọn arákùnrin tó wá láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn sọ̀rọ̀, ó jọ pé ó bọ́gbọ́n mu ká dáwọ́ iṣẹ́ dúró fún ìgbà díẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n ti ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti.”

A Tún Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo Èdè Creole Ti Ilẹ̀ Haiti

Ní ọdún 2003, Ìgbìmọ̀ Olùdarí yan tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì, ìyẹn Dong àti Gladys Bark pé kí wọ́n lọ sìn láwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Ọdún méjì ni wọ́n fi ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó wà nílùú Higüey, iṣẹ́ wọn sì sèso rere. Ní June 1, ọdún 2005, wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ tó ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti. Arákùnrin Dong Bark, Barnabé Biabiany àti míṣọ́nnárì míì tó ń jẹ́ Steven Rogers lọ káàkiri orílẹ̀-èdè náà láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbèrú láwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 148

Iṣẹ́ náà tẹ̀ síwájú dáadáa, èyí sì mú kí wọ́n dá àwọn ìjọ míì sílẹ̀. Ní September 1, ọdún 2006, wọ́n dá àyíká àkọ́kọ́ tó ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti sílẹ̀. Ìjọ méje àti àwùjọ méjì ló wà ní àyíká náà, Arákùnrin Barnabé Biabiany sì ni alábòójútó àyíká wọn.

Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n tún rán àwọn míṣọ́nnárì míì pé kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ láwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Bákan náà, àwọn míì tó yọ̀ǹda ara wọn tún dé láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Kánádà àti ilẹ̀ Yúróòpù àtàwọn ibòmíì láti wa ran àwọn ará lọ́wọ́. Wọ́n yan àwọn arákùnrin mélòó kan tó kúnjú ìwọ̀n láti ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kọ́ àwọn ará tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè náà àtàwọn tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè ní èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti.

Tí àwọn èèyàn bá rí ẹni tí kì í ṣe ọmọ ilẹ̀ Haiti tó ń sọ èdè náà, wọ́n máa rò pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni

Bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Dominican ṣe ń ṣakitiyan láti kọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti ṣe àwọn èèyàn náà láǹfààní gan-an ni. Ní báyìí, bí akéde kan tó jẹ́ ọmọ Orílẹ̀-èdè Dominican bá ń fi èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́, ara àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ máa ń balẹ̀, wọ́n á sì túbọ̀ tẹ́tí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti kọ́ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti débi pé tí àwọn èèyàn bá rí ẹni tí kì í ṣe ọmọ ilẹ̀ Haiti tó ń sọ èdè náà, wọ́n máa rò pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.

Ìrírí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó jẹ́ ọmọ Orílẹ̀-èdè Dominican tó kọ́ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa máa jẹ wá lógún. Nígbà tí arábìnrin yìí wà lóde ẹ̀rí, ó pàdé tọkọtaya kan tó ń sọ èdè Haiti, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó pa dà bẹ̀ wọ́n wò láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin náà sọ pé: “Nígbà tí mo débẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn obìnrin ní Orílẹ̀-èdè Dominican, mo fẹnu ko ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìyàwó rẹ̀. Obìnrin náà bá bú sẹ́kún. Mo wá bi í pé, ‘Ṣé kò sí o?’ Ó fèsì pé, ‘Látọjọ́ tí mo ti wà lórílẹ̀-èdè yìí, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tẹ́ni tó ń kí mi máa fẹnu kò mí ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.’”

Bí Jèhófà ṣe ń fi ìbùkún rẹ̀ sórí iṣẹ́ àṣekára àwọn ará tó ń fi èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti wàásù ti mú ìbísí tó kàmàmà wá. Wọ́n dá àyíká míì tó ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti sílẹ̀ ní September 1, ọdún 2009, torí wọ́n ti ní ìjọ mẹ́tàlélógún [23] àti ogún [20] àwùjọ. Iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2011 fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí ìbísí wáyé lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, inú àwọn akéde mọ́kànlá tó wà nílùú kékeré kan tó ń jẹ́ Río Limpio dùn nígbà tí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [594] èèyàn pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Nígbà tí wọ́n sì ṣètò Ìrántí Ikú Kristi sí ìlú Las Yayas de Viajama níbi tí kò ti sí akéde kankan, àádọ́sàn-án [170] èèyàn ló pésẹ̀ síbẹ̀. Nígbà tó fi máa di oṣù September ọdún 2011, ìjọ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] àti àwùjọ mọ́kànlélógún [21] ló ti ń sọ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti. Torí náà, wọ́n dá àyíká míì sílẹ̀ lọ́dún 2012.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì Orílẹ̀-èdè Dominican àti ti ilẹ̀ Haiti pawọ́ pọ̀ láti máa dá àwọn arákùnrin tó wá láti orílẹ̀-èdè méjèèjì lẹ́kọ̀ọ́. Èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti ni wọ́n fi ṣe kíláàsì márùn-ún ti Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n àti kíláàsì mẹ́rin ti Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 148

Wọ́n ń kọ́ èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti

Ìbísí Láwọn Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Èdè Creole ti Ilẹ̀ Haiti

Láti ọdún 2005 sí 2014

  • 2005

    Ìjọ 1

    Àwùjọ 6

    Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 149
  • 2014

    Ìjọ 57

    Àwùjọ 29

    Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 149
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́