ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb16 ojú ìwé 130
  • Àádọ́ta Ọdún Lẹ́nu Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Àkànṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àádọ́ta Ọdún Lẹ́nu Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Àkànṣe
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Wo Ni Aṣáájú-Ọ̀nà?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Ṣíṣiṣẹ́sìn Pẹ̀lú Òye Ìmọ̀lára Ìjẹ́kánjúkánjú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Ń Fìbùkún Jíǹkí Ẹni Wọ́n Sì Ń Rí I Gbà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
yb16 ojú ìwé 130

INDONÉṢÍÀ

Àádọ́ta Ọdún Lẹ́nu Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Àkànṣe

Alisten Lumare

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1927

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1962

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀gá ọlọ́pàá ni tẹ́lẹ̀ kó tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ohun tó lé ní àádọ́ta [50] ọdún.

Alisten Lumare

LỌ́DÚN 1964, ètò Ọlọ́run rán mi lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìjọ kékeré kan tó wà ní Manokwari nílùú West Papua. Ojú ń pọ́n àwọn ará tó wà níjọ yẹn torí àwọn olórí ẹ̀sìn ibẹ̀ ń fínná mọ́ wọn gan an. Kò pẹ́ tí mo dé sílùú náà ni àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan já wọlé mi.

Ó ń sọ̀rọ̀ fitafita pé: “Wòó, màá wó ilé yìí kanlẹ̀, máà sí rí i pé kò sí Ajẹ́rìí Jèhófà kankan nílùú Manokwari ńbí.”

Torí pé mo ti ṣe iṣẹ́ ọlọ́pàá rí, gìràgìrà rẹ̀ ò dẹ́rù bà mí. Dípò kí n bú mọ́ ọn, ṣe ni mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀, ló bá yí pa dà, ó sì lọ wọ́ọ́rọ́wọ́.​—1 Pét. 3:⁠15.

Nígbà yẹn, akéde mẹ́jọ péré ló wà ní gbogbo Manokwari. Àmọ́ lónìí, ìyẹn lẹ́yìn àádọ́ta [50] ọdún, ìjọ méje ló wà níbẹ̀ báyìí. Àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè tá a ṣe níbẹ̀ lọ́dún 2014 sì ju ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méjì [1,200] lọ. Tí ń bá wo gbogbo ohun tí Jèhófà ti mu ká gbéṣe ní ibi àdádó yìí, inú mi máa ń dùn gan-an.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́