ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 25
  • Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé àwọn èèyàn máa lè tún ayé yìí ṣe?
  • Ìdí tá a fi ní ìrètí
  • Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé
    Jí!—2023
  • Ẹ̀bùn Tó Máa Wà Títí Láé Tí Ẹlẹ́dàá Fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 25
Ọ̀dọ́mọbìnrin kan ń bomi rin òdòdó. Àwọn ilé iṣẹ́ ń ba àyíká jẹ́ lọ́ọ̀ọ́kán.

Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?

Inú ọ̀pọ̀ ò dùn torí báwọn èèyàn ṣe ń ba ayé yìí jẹ́ àti bí wọ́n ṣe ń ṣèpalára fáwọn ẹ̀dá alààyè tó wà nínú rẹ̀. Àwọn onímọ̀ nípa àyíká sọ pé àwọn nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe lónìí lè mú kí onírúurú ẹ̀dá alààyè pòórá pátápátá láyé, ó sì ń ṣèpalára fún àyíká àtàwọn ẹranko ju ti ìgbàkígbà rí lọ.

Ṣé àwọn èèyàn máa pa ayé yìí run? Àbí wọ́n á lè máa ṣe nǹkan lọ́nà tí wọn ò fi ní ba àwọn ohun tó wà láyé jẹ́?

Ṣé àwọn èèyàn máa lè tún ayé yìí ṣe?

Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé àwọn èèyàn máa lè tún ayé yìí ṣe. Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ pé káwọn èèyàn tó lè tún ayé yìí ṣe, àwọn ìyípadà kan gbọ́dọ̀ wáyé, àwọn ìyípadà náà sì gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Lára àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ ni:

  • Káwọn èèyàn túbọ̀ máa fọwọ́ pàtàkì mú bí wọ́n ṣe ń bójú tó ilẹ̀, igbó, àwọn ilẹ̀ olómi àti òkun.

  • Kí wọ́n máa ṣọ̀gbìn kí wọ́n sì máa pèsè ohun àmúṣagbára lónírúurú ọ̀nà.

  • Kí ìyípadà dé bá ìpèsè oúnjẹ àti bó ṣe ń dé ọ̀dọ̀ aráàlú káwọn èèyàn lè máa jẹ ohun tó ń wá látara ewéko pẹ̀lú ẹran àti ẹja tó mọ níwọ̀n, kí wọ́n má jẹ àjẹjù kí wọ́n má sì fi oúnjẹ ṣòfò.

  • Kí wọ́n gbà pé kíkó ohun ìní tara jọ ṣáá kọ́ ló ń mú kéèyàn gbé ìgbé ayé tó dáa.

Kí lèrò rẹ? Ṣó yẹ ká ronú pé ìjọba, àwọn ilé iṣẹ́ àtàwọn èèyàn máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú kí nǹkan túbọ̀ dáa? Àbí o rò pé kò ní lè ṣeé ṣe torí olójúkòkòrò, onímọtara-ẹni-nìkan àti ẹni tí kìí ronú nípa ọjọ́ iwájú lọ̀pọ̀ lára wọn?—2 Tímótì 3:1-5.

Ìdí tá a fi ní ìrètí

Bíbélì fi dá wa lójú pé ayé yìí ò ní parun. Ó ṣàlàyé ìdí táwọn èèyàn ò fi ní lè tún ayé yìí ṣe, ó sì jẹ́ ká mọ ìjọba tó máa tún ayé yìí ṣe àti bí àyípadà náà ṣe máa wáyé.

Ìdí táwọn èèyàn ò fi ní lè tún ayé ṣe. Jèhófàa Ọlọ́run ló dá ayé, ó sì ní kí àwọn èèyàn máa bójú tó o. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15) Kí wọ́n tó lè ṣàṣeyọrí, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọlọ́run máa tọ́ wọn sọ́nà, kí wọ́n sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (Òwe 20:24) Àmọ́ dípò tí wọ́n máa fi ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n kọ Jèhófà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dá tara wọn ṣe. (Oníwàásù 7:29) Àwọn èèyàn ò lágbára láti tún ayé yìí ṣe, kò sí bí wọ́n ṣe lè sapá tó, pàbó náà ni gbogbo ẹ̀ máa já sí.—Òwe 21:30; Jeremáyà 10:23.

Ohun tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀. Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn tó ń ba ayé jẹ́ run. (Ìfihàn 11:18) Kò ní bá ìjọba àtàwọn èèyàn tó ń pa ayé run tún ayé ṣe; ṣe ló máa fi ìjọba míì rọ́pò tiwọn. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìfihàn 21:5.

Bí ìyípadà náà ṣe máa wáyé. Jèhófà máa fi ìjọba rẹ̀ rọ́pọ̀ ìjọba èèyàn. Jésù Kristi ló máa jẹ́ ọba ìjọba náà, ó sì máa ṣàkóso ayé.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10.

Ìjọba Ọlọ́run máa kọ́ àwọn èèyàn ní ìlànà òdodo Ọlọ́run kí wọ́n lè máa fi ṣèwà hù. Táwọn èèyàn bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, wọ́n á máa ṣe nǹkan lọ́nà tí wọn ò fi ní ba àwọn ohun tó wà láyé jẹ́. (Àìsáyà 11:9) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run àwọn èèyàn máa gbádùn ìgbésí ayé tó dáa, ẹnikẹ́ni ò sì ní ba ayé jẹ́. Àwọn ohun tá a máa gbádùn rèé:

  • Oúnjẹ á wà fún gbogbo èèyàn.—Sáàmù 72:16.

  • Àwọn ohun àdáyébá á padà bọ̀ sípò.—Àìsáyà 35:1, 2, 6, 7.

  • Àlàáfíà máa wà láàárín àwọn èèyàn àti ẹranko.—Àìsáyà 11:6-8; Hósíà 2:18.

  • Á fòpin sí àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká.—Máàkù 4:37-41.

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó ṣe àwọn ìyípadà yìí. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?”

a Jèhófa ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.

Kí la lè ṣe báyìí láti fi hàn pé a moyì ayé yìí?

Òótọ́ ni pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè tún ayé yìí ṣe, síbẹ̀ ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tọ́jú àyíká wa. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká máa fi nǹkan ṣòfò, ó sì yẹ ká máa ṣègbọràn sí òfin tí ìjọba ṣe nípa bá a ṣe lè tún àwọn nǹkan lò.—Jòhánù 6:12, 13; Róòmù 13:1, 5.

  • Brett.

    Olùgbaninímọ̀ràn nípa àyíká tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ni Brett. Ìmọ̀ tó ní nípa ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀ mú kó gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó máa tún ayé ṣe. Ka ìtàn rẹ̀.

  • Àwọn òṣìṣẹ́ méjì ń wo àwọn ilé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sí Oríléeṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

    Ọ̀nà kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbà fi ọ̀wọ̀ hàn fún Ẹlẹ́dàá wa ni pé tá a bá ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé ńlá, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa ba àyíká jẹ́. Tó o bá fẹ́ mọ ohun tá a ti ṣe, wo fídíò Ilé Tí Kò Pa Àyíká Lára Fi Ògo fún Jèhófà.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ayé

Jẹ́nẹ́sísì 2:15: “Jèhófà Ọlọ́run mú ọkùnrin náà, ó sì fi sínú ọgbà Édẹ́nì kó lè máa ro ó, kó sì máa tọ́jú rẹ̀.”

Ìtumọ̀: Ọlọ́run ní kí àwa èèyàn máa bójú tó ayé yìí.

Jẹ́nẹ́sísì 1:28: “Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ máa jọba lórí àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run àti lórí gbogbo ohun alààyè tó ń rìn lórí ilẹ̀.’”

Ìtumọ̀: Ọlọ́run sọ pé kí àwa èèyàn máa tọ́jú àwọn ẹranko.

Àìsáyà 45:18: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni tó dá ayé, Aṣẹ̀dá rẹ̀ tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in, ẹni tí kò kàn dá a lásán, àmọ́ tó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀: ‘Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.’ ”

Ìtumọ̀: Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé kò tíì yí pa dà. Àwọn tó bá ń ṣe ohun tó fẹ́ ló sì máa jogún rẹ̀.

Sáàmù 37:29: “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”

Ìtumọ̀: Àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run máa ní àǹfààní láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé.

Sáàmù 98:6-8: “Ẹ kígbe ìṣẹ́gun níwájú Ọba náà, Jèhófà. Kí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dún bí ààrá, ayé àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀. Kí àwọn odò pàtẹ́wọ́; kí àwọn òkè kígbe ayọ̀ pa pọ̀.”

Ìtumọ̀: Ìṣàkóso Ọlọ́run máa sọ àyíká wa dọ̀tun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́