Lẹ́yìn Tí Jésù Jíǹde, Ṣé Ara Èèyàn Ló Ṣì Ní àbí Ó Ti Di Ẹ̀dá Ẹ̀mí?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì sọ pé wọ́n pa Jésù ‘nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n a sọ ọ́ di ààyè [jí i dìde] nínú ẹ̀mí.”—1 Pétérù 3:18; Ìṣe 13:34; 1 Kọ́ríńtì 15:45; 2 Kọ́ríńtì 5:16.
Ohun tí Jésù fúnra rẹ̀ sọ fi hàn pé ẹran ara kọ́ ló máa ní tó bá jíǹde. Ó ní òun máa ‘fi ẹran ara òun fúnni nítorí ìyè ayé,’ kó lè ra aráyé pa dà. (Jòhánù 6:51; Mátíù 20:28) Ká ní ẹran ara yẹn ló tún ní nígbà tó jíǹde ni, kò bá má lè rà wá pa dà. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ kọ́ nìyẹn, torí Bíbélì sọ pé ó fi ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rúbọ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.”—Hébérù 9:11, 12.
Tó bá jẹ́ pé ẹ̀dá ẹ̀mí ni Jésù nígbà tó jíǹde, báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe wá rí i?
- Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí lè fara hàn bí èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn áńgẹ́lì kan ṣe bẹ́ẹ̀ láyé àtijọ́, wọ́n tiẹ̀ tún bá àwọn èèyàn jẹun. (Jẹ́nẹ́sísì 18:1-8; 19:1-3) Àmọ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ṣì ni wọ́n, wọ́n sì lè pòórá.—Àwọn Onídàájọ́ 13:15-21. 
- Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, òun náà fara hàn bí èèyàn fúngbà díẹ̀, bí àwọn áńgẹ́lì ṣe máa ń ṣe. Torí pé ẹ̀dá ẹ̀mí ni, ó lè dédé yọ sí àwọn èèyàn tàbí kó pòórá lójijì. (Lúùkù 24:31; Jòhánù 20:19, 26) Ara tí Jésù máa ń ní láwọn ìgbà tó yọ sí àwọn èèyàn máa ń yàtọ̀ síra. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ Jésù tímọ́tímọ́ gan-an ò tètè dá a mọ̀, ohun tó sọ tàbí ohun tó ṣe ni wọ́n fi dá a mọ̀.—Lúùkù 24:30, 31, 35; Jòhánù 20:14-16; 21:6, 7. 
- Ara tó ní àpá ọgbẹ́ ni Jésù fi fara han àpọ́sítélì Tọ́másì. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè mú kí ìgbàgbọ́ Tọ́másì lágbára, torí Tọ́másì ò tètè gbà pé Jésù ti jíǹde.—Jòhánù 20:24-29.