12 Torí Dáníẹ́lì, ẹni tí ọba pè ní Bẹtiṣásárì,+ ní ẹ̀mí tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye láti túmọ̀ àwọn àlá, láti ṣàlàyé àwọn àlọ́, kó sì wá ojútùú sí ohun tó bá lọ́jú pọ̀.*+ Jẹ́ kí wọ́n pe Dáníẹ́lì wá, ó sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”
9 Àwọn olórí ìdílé náà jowú Jósẹ́fù,+ wọ́n sì tà á sí Íjíbítì.+ Àmọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀,+10 ó gbà á nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀, ó ṣe ojúure sí i, ó sì fún un ní ọgbọ́n níwájú Fáráò ọba Íjíbítì. Ó yàn án láti ṣàkóso Íjíbítì àti gbogbo ilé rẹ̀.+