-
Jẹ́nẹ́sísì 41:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Màlúù méje tó rẹwà tó sì sanra ń jáde bọ̀ látinú odò náà, wọ́n sì ń jẹ koríko+ tó wà ní odò Náílì. 3 Lẹ́yìn náà, màlúù méje míì tí kò lẹ́wà, tó sì rù ń jáde bọ̀ látinú odò Náílì, wọ́n dúró létí odò Náílì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn màlúù tó sanra. 4 Àwọn màlúù tí kò lẹ́wà, tó sì rù wá jẹ àwọn màlúù méje tó rẹwà, tó sì sanra ní àjẹrun. Ni Fáráò bá jí.
-