-
Jẹ́nẹ́sísì 48:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé bàbá òun ò gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kò dùn mọ́ ọn nínú, ó sì gbìyànjú láti mú ọwọ́ bàbá rẹ̀ kúrò lórí Éfúrémù, kó sì gbé e sórí Mánásè.
-
-
Nọ́ńbà 1:32, 33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù nípasẹ̀ Éfúrémù.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 33 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Éfúrémù jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500).
-