27 Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká tà á + fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, ẹ má sì jẹ́ ká fọwọ́ kàn án. Ó ṣe tán, àbúrò wa ni, ara kan náà ni wá.” Wọ́n sì gbọ́ ohun tí arákùnrin wọn sọ.
35 Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń gbìyànjú láti tù ú nínú, àmọ́ kò gbà, ó ń sọ pé: “Màá ṣọ̀fọ̀ ọmọ mi wọnú Isà Òkú!”*+ Bàbá rẹ̀ sì ń sunkún torí rẹ̀.
20 A sì sọ fún ọ̀gá mi pé, ‘A ní bàbá tó ti darúgbó, ó sì bí ọmọ kan ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, òun ló kéré jù.+ Àmọ́ ẹ̀gbọ́n ọmọ náà ti kú,+ torí náà, òun ló ṣẹ́ kù nínú àwọn ọmọ ìyá+ rẹ̀, bàbá rẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’