Jẹ́nẹ́sísì 42:38 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 38 Àmọ́ ó sọ pé: “Ọmọ mi ò ní bá yín lọ, torí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ló sì ṣẹ́ kù.+ Bí jàǹbá bá lọ ṣe é ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, ó dájú pé ẹ ó mú kí n ṣọ̀fọ̀+ wọnú Isà Òkú*+ pẹ̀lú ewú orí mi.” Jẹ́nẹ́sísì 44:29 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 29 Tí ẹ bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ mi, tí jàǹbá sì lọ ṣe é, ó dájú pé ẹ máa mú ewú orí mi lọ sínú Isà Òkú*+ tòun ti àjálù.’+ Sáàmù 89:48 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 48 Ta ló wà láàyè tí kò ní kú?+ Ṣé ó lè gba ara* rẹ̀ lọ́wọ́ agbára Isà Òkú ni?* (Sélà) Oníwàásù 9:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú,*+ ibi tí ìwọ ń lọ. Hósíà 13:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Màá rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ agbára Isà Òkú;*Màá gbà wọ́n pa dà lọ́wọ́ ikú.+ Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?+ Ìwọ Isà Òkú, ìpanirun rẹ dà?+ Síbẹ̀, mi ò ní fojú àánú wò wọ́n.* Ìṣe 2:27 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 27 torí o ò ní fi mí* sílẹ̀ nínú Isà Òkú,* bẹ́ẹ̀ ni o ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.+ Ìfihàn 20:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú* yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn, a sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+
38 Àmọ́ ó sọ pé: “Ọmọ mi ò ní bá yín lọ, torí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ló sì ṣẹ́ kù.+ Bí jàǹbá bá lọ ṣe é ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, ó dájú pé ẹ ó mú kí n ṣọ̀fọ̀+ wọnú Isà Òkú*+ pẹ̀lú ewú orí mi.”
29 Tí ẹ bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ mi, tí jàǹbá sì lọ ṣe é, ó dájú pé ẹ máa mú ewú orí mi lọ sínú Isà Òkú*+ tòun ti àjálù.’+
10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú,*+ ibi tí ìwọ ń lọ.
14 Màá rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ agbára Isà Òkú;*Màá gbà wọ́n pa dà lọ́wọ́ ikú.+ Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?+ Ìwọ Isà Òkú, ìpanirun rẹ dà?+ Síbẹ̀, mi ò ní fojú àánú wò wọ́n.*
13 Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú* yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn, a sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+