-
Jẹ́nẹ́sísì 43:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Júdà wá rọ Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí ọmọ náà bá mi lọ,+ sì jẹ́ ká máa lọ ká lè wà láàyè, ká má bàa kú,+ àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ+ wa. 9 Mo fi dá ọ lójú pé kò sóhun tó máa ṣe ọmọ náà.*+ Ọwọ́ mi ni kí o ti béèrè rẹ̀. Tí mi ò bá mú un pa dà wá bá ọ, kí n sì fà á lé ọ lọ́wọ́, a jẹ́ pé mo ti ṣẹ̀ ọ́ títí láé nìyẹn.
-
-
Jẹ́nẹ́sísì 44:32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Ẹrú rẹ fi dá bàbá mi lójú nípa ọmọ náà pé, ‘Tí mi ò bá mú un pa dà wá bá ọ, á jẹ́ pé mo ti ṣẹ bàbá mi títí láé.’+
-