-
Jẹ́nẹ́sísì 47:29, 30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Nígbà tí àkókò tí Ísírẹ́lì máa kú+ sún mọ́ tòsí, ó pe Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Tí mo bá rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́ fi ọwọ́ rẹ sábẹ́ itan mi, kí o fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi, kí o sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi. Jọ̀ọ́, má sin mí sí Íjíbítì.+ 30 Tí mo bá kú,* kí o gbé mi kúrò ní Íjíbítì, kí o sì lọ sin mí sí sàréè àwọn baba ńlá+ mi.” Jósẹ́fù fèsì pé: “Màá ṣe ohun tí o sọ.”
-
-
Jẹ́nẹ́sísì 50:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì sin ín sínú ihò tó wà ní ilẹ̀ Mákípẹ́là, ilẹ̀ tó wà níwájú Mámúrè tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú.+
-