39 Ni Fáráò bá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló jẹ́ kí o mọ gbogbo èyí, kò sí ẹni tó lóye, tó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n bíi tìẹ. 40 Ìwọ ni màá fi ṣe olórí ilé mi, gbogbo àwọn èèyàn mi yóò sì máa ṣègbọràn sí ọ délẹ̀délẹ̀.+ Ipò ọba mi nìkan ni màá fi jù ọ́ lọ.”