17 Fáráò wá sọ fún Jósẹ́fù pé: “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ẹ di ẹrù lé àwọn ẹran tí ẹ fi ń kẹ́rù, kí ẹ lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, 18 kí ẹ sì mú bàbá yín àti agbo ilé yín wá sọ́dọ̀ mi níbí. Màá fún yín ní àwọn ohun rere ilẹ̀ Íjíbítì, ẹ ó sì jẹ ohun tó dára jù ní ilẹ̀ yìí.’+