4 Ẹ̀yà méjì ni wọ́n ka àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù sí,+ ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù;+ wọn ò pín lára ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Léfì, àfi àwọn ìlú+ tí wọ́n á máa gbé àti ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn wọn á ti máa jẹko, tí ohun ìní wọn sì máa wà.+
5Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì,+ àkọ́bí Ísírẹ́lì nìyí. Òun ni àkọ́bí, àmọ́ torí pé ó kó ẹ̀gàn bá ibùsùn bàbá rẹ̀,*+ ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí ni a fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù+ ọmọ Ísírẹ́lì, torí náà, wọn ò kọ orúkọ rẹ̀ sínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn pé òun ni àkọ́bí.