-
Nọ́ńbà 2:18-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Éfúrémù wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní àwùjọ-àwùjọ;* Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù ni ìjòyè àwọn ọmọ Éfúrémù. 19 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500).+ 20 Kí ẹ̀yà Mánásè+ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì ni ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè. 21 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n ó lé igba (32,200).+
-