18 Ó sọ nípa Sébúlúnì pé:+
“Ìwọ Sébúlúnì, máa yọ̀ bí o ṣe ń jáde lọ,
Àti ìwọ Ísákà, nínú àwọn àgọ́ rẹ.+
19 Wọ́n á pe àwọn èèyàn wá sórí òkè.
Ibẹ̀ ni wọ́n á ti rú àwọn ẹbọ òdodo.
Torí wọ́n á kó látinú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọrọ̀ inú òkun,
Àti àwọn ohun tó fara pa mọ́ sínú iyẹ̀pẹ̀.”