ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 6:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ìtàn Nóà nìyí.

      Olódodo ni Nóà.+ Ó fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi* láàárín àwọn tí wọ́n jọ gbé láyé.* Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn.

  • Hébérù 10:38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 “Àmọ́ ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo mi wà láàyè”+ àti pé “tó bá fà sẹ́yìn, inú mi* ò ní dùn sí i.”+

  • Hébérù 11:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ìgbàgbọ́ mú kí Nóà  + fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, lẹ́yìn tó gba ìkìlọ̀ láti ọ̀run nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí,+ ó kan ọkọ̀ áàkì+ kí agbo ilé rẹ̀ lè rí ìgbàlà; ó dá ayé lẹ́bi nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí,+ ó sì di ajogún òdodo irú èyí tí ìgbàgbọ́ ń mú wá.

  • 1 Pétérù 3:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Nítorí ojú Jèhófà* wà lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn;+ àmọ́ Jèhófà* kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú.”+

  • 2 Pétérù 2:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Kò sì fawọ́ sẹ́yìn láti fìyà jẹ ayé ìgbàanì,+ àmọ́ ó dá ẹ̀mí Nóà, oníwàásù òdodo sí+ pẹ̀lú àwọn méje míì  + nígbà tó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+

  • 2 Pétérù 2:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Torí náà, Jèhófà* mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò,+ síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ìparun* ní ọjọ́ ìdájọ́,+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́