22 Jèhófà Ọlọ́run wá sọ pé: “Ọkùnrin náà ti dà bí ọ̀kan lára wa, ó ti mọ rere àti búburú.+ Ní báyìí, kó má bàa na ọwọ́ rẹ̀, kó sì tún mú èso igi ìyè,+ kó jẹ ẹ́, kó sì wà láàyè títí láé,*—”
24 Torí náà, ó lé ọkùnrin náà jáde, ó sì fi àwọn kérúbù+ àti idà oníná tó ń yí láìdáwọ́ dúró sí ìlà oòrùn ọgbà Édẹ́nì, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ọ̀nà tó lọ síbi igi ìyè náà.