16 “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí o jókòó sórí ìtẹ́ lókè* àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ lórí gbogbo ìjọba ayé. Ìwọ lo dá ọ̀run àti ayé.
4 Ògo Jèhófà+ gbéra láti orí àwọn kérúbù wá sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, ìkùukùu sì bẹ̀rẹ̀ sí í kún inú ilé náà díẹ̀díẹ̀,+ ògo Jèhófà sì mọ́lẹ̀ yòò ní gbogbo àgbàlá náà.