17Nígbà tí Ábúrámù pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99), Jèhófà fara han Ábúrámù, ó sì sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè. Máa bá mi rìn,* kí o sì fi hàn pé o jẹ́ aláìlẹ́bi.*
8 Màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ ní ilẹ̀ tí o gbé nígbà tí o jẹ́ àjèjì,+ ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Kénáánì, yóò jẹ́ ohun ìní wọn títí láé, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run+ wọn.”
9 Ìgbàgbọ́ mú kó máa gbé bí àjèjì ní ilẹ̀ ìlérí, bíi pé ó jẹ́ ilẹ̀ àjèjì,+ ó ń gbé inú àgọ́ + pẹ̀lú Ísákì àti Jékọ́bù, àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ajogún ìlérí kan náà.+
13 Gbogbo àwọn yìí ní ìgbàgbọ́ títí wọ́n fi kú, bí wọn ò tiẹ̀ rí àwọn ohun tí ó ṣèlérí náà gbà; + àmọ́ wọ́n rí i láti òkèèrè,+ wọ́n tẹ́wọ́ gbà á, wọ́n sì kéde ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀* ní ilẹ̀ náà.