21Jèhófà rántí Sérà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, Jèhófà sì ṣe ohun tó ṣèlérí+ fún Sérà. 2 Sérà lóyún,+ ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ní àkókò tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un.+
19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò yẹ̀, ó ro ti ara rẹ̀ tó ti di òkú tán (torí ó ti tó nǹkan bí ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún),+ ó tún ro ti ilé ọlẹ̀ Sérà tó ti kú.*+
11 Ìgbàgbọ́ mú kí Sérà náà gba agbára láti lóyún ọmọ,* kódà nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti kọjá ti ẹni tó lè bímọ,+ torí ó ka Ẹni tó ṣe ìlérí náà sí olóòótọ́.*