-
Jẹ́nẹ́sísì 24:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Ó wá sọ pé: “Ìránṣẹ́+ Ábúráhámù ni mí.
-
-
Jẹ́nẹ́sísì 24:37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 Torí náà, ọ̀gá mi mú kí n búra, ó sọ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó fún ọmọ mi láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tí mò ń gbé+ ní ilẹ̀ wọn.
-
-
Ẹ́kísódù 34:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú, torí tí wọ́n bá ń bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹnì kan yóò pè ọ́ wá, wàá sì jẹ nínú ẹbọ rẹ̀.+ 16 Ó sì dájú pé ẹ máa mú lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,+ àwọn ọmọbìnrin wọn máa bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n á sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe.+
-
-
1 Àwọn Ọba 11:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin ilẹ̀ àjèjì,+ yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò,+ àwọn tó tún nífẹ̀ẹ́ ni: àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Móábù,+ ọmọ Ámónì,+ ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì+ àti ọmọ Hétì.+ 2 Wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lọ sí àárín wọn,* wọn ò sì gbọ́dọ̀ wá sí àárín yín, torí ó dájú pé wọ́n á mú kí ọkàn yín fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run wọn.”+ Àmọ́ ọkàn Sólómọ́nì kò kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. 3 Ó ní ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọba àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì,* ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó rẹ̀ yí i lọ́kàn pa dà.*
-