-
Jẹ́nẹ́sísì 26:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jèhófà fara hàn án ní òru, ó sì sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù+ bàbá rẹ. Má bẹ̀rù,+ torí mo wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò bù kún ọ, màá sì mú kí ọmọ* rẹ pọ̀ torí Ábúráhámù ìránṣẹ́+ mi.” 25 Torí náà, ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì ké pe orúkọ Jèhófà.+ Ísákì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀,+ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan síbẹ̀.
-