32 Wọ́n sin àwọn egungun Jósẹ́fù,+ èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó kúrò ní Íjíbítì sí Ṣékémù lórí ilẹ̀ tí Jékọ́bù fi ọgọ́rùn-ún (100) ẹyọ owó+ rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì,+ bàbá Ṣékémù; ó sì di ogún àwọn ọmọ Jósẹ́fù.+
15 Jékọ́bù lọ sí Íjíbítì,+ ó sì kú síbẹ̀,+ ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn baba ńlá wa.+16 Wọ́n gbé wọn lọ sí Ṣékémù, wọ́n sì tẹ́ wọn sínú ibojì tí Ábúráhámù fi owó fàdákà rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì ní Ṣékémù.+