8 Torí náà, ẹ̀yin kọ́ lẹ rán mi wá síbí, Ọlọ́run tòótọ́ ni, torí kó lè fi mí ṣe olórí agbani-nímọ̀ràn* fún Fáráò, kó sì fi mí ṣe olúwa lórí gbogbo ilé rẹ̀ àti olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+
26 Àwọn ìbùkún bàbá rẹ yóò ga ju àwọn ìbùkún òkè ayérayé lọ, yóò ga ju àwọn ohun tó wuni lórí àwọn òkè tó ti wà tipẹ́.+ Wọn yóò máa wà ní orí Jósẹ́fù, ní àtàrí ẹni tí Ọlọ́run yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀.+