ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 26:1-6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “Kí o mú aṣọ mẹ́wàá tí wọ́n fi ń pa àgọ́, kí o sì fi ṣe àgọ́ ìjọsìn.+ Kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa, pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò. Kí o kó iṣẹ́ sí wọn lára, kí iṣẹ́ náà+ jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+ 2 Kí gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlọ́gbọ̀n (28), kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Kí ìwọ̀n gbogbo aṣọ àgọ́ náà dọ́gba.+ 3 Kí o so aṣọ àgọ́ márùn-ún pọ̀ mọ́ra, kó jẹ́ ọ̀wọ́ kan, kí o sì so aṣọ àgọ́ márùn-ún yòókù pọ̀, kó jẹ́ ọ̀wọ́ kan. 4 Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe àwọn ihò sí etí aṣọ àgọ́ tó kẹ́yìn lára ọ̀wọ́ náà, kí o sì ṣe ohun kan náà sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ìkángun ọ̀wọ́ kejì níbi tí yóò ti so pọ̀ mọ́ ti àkọ́kọ́. 5 Kí o lu àádọ́ta (50) ihò sí aṣọ àgọ́ kan, kí o sì lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ kejì kí wọ́n lè kọjú síra níbi tí wọ́n á ti so pọ̀ mọ́ra. 6 Kí o fi wúrà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́, kí o sì fi àwọn ìkọ́ náà so àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀, kí àgọ́ ìjọsìn náà lè di odindi.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́