-
Ẹ́kísódù 26:19-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 “Kí o fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò+ sábẹ́ ogún (20) férémù náà: ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ férémù kan, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀, kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sì wà lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀.+ 20 Kí o ṣe ogún (20) férémù sí ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà, ní apá àríwá, 21 kí o sì fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò fún wọn. Kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò wà lábẹ́ férémù kan, kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò wà lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù.
-