-
Ẹ́kísódù 36:24-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ó wá fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò sábẹ́ ogún (20) férémù náà, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ férémù kan kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀, ó sì ṣe ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀.+ 25 Ó ṣe ogún (20) férémù sí ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà, ní apá àríwá, 26 ó sì fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò fún wọn, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò lábẹ́ férémù kan àti ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù.
-