-
Ẹ́kísódù 26:19-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 “Kí o fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò+ sábẹ́ ogún (20) férémù náà: ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ férémù kan, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀, kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sì wà lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀.+ 20 Kí o ṣe ogún (20) férémù sí ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà, ní apá àríwá, 21 kí o sì fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò fún wọn. Kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò wà lábẹ́ férémù kan, kí ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò wà lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù.
-
-
Ẹ́kísódù 26:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Ó máa jẹ́ férémù mẹ́jọ àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rìndínlógún (16) tí wọ́n fi fàdákà ṣe, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò máa wà lábẹ́ férémù kan, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sì máa wà lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù.
-
-
Ẹ́kísódù 26:32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Kí o gbé e kọ́ sára òpó igi bọn-ọ̀n-ní mẹ́rin tí wọ́n fi wúrà bò. Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìkọ́ wọn. Kí àwọn òpó náà wà lórí ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ní ihò tí wọ́n fi fàdákà ṣe.
-