-
Ẹ́kísódù 13:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Kí ẹ sì sọ fún ọmọ yín ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Torí ohun tí Jèhófà ṣe fún mi nígbà tí mo kúrò ní Íjíbítì ni.’+
-
-
Diutarónómì 6:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “Lọ́jọ́ iwájú, tí ọmọ rẹ bá bi ọ́ pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ àwọn ìránnilétí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run wa pa láṣẹ fún yín?’ 21 kí o sọ fún ọmọ rẹ pé, ‘A di ẹrú Fáráò ní Íjíbítì, àmọ́ Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa jáde ní Íjíbítì. 22 Ojú wa ni Jèhófà ṣe ń fi àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tó lágbára tó sì ń ṣọṣẹ́ kọ lu Íjíbítì,+ Fáráò àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.+
-
-
Sáàmù 44:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
44 Ọlọ́run, a ti fi etí wa gbọ́,
Àwọn baba ńlá wa ti ròyìn fún wa,+
Àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,
Ní àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́.
-