-
Ẹ́kísódù 8:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Àmọ́ tí o ò bá jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ, màá mú kí eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ bo ìwọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn èèyàn rẹ, wọ́n á sì wọnú àwọn ilé rẹ; eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ yóò kún àwọn ilé Íjíbítì, wọ́n á sì bo ilẹ̀ tí wọ́n* dúró sí. 22 Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé màá ya ilẹ̀ Góṣénì sọ́tọ̀, níbi tí àwọn èèyàn mi ń gbé. Eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ kankan ò ní sí níbẹ̀;+ èyí á sì jẹ́ kí o mọ̀ pé èmi Jèhófà wà ní ilẹ̀ yìí.+
-
-
Ẹ́kísódù 9:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ kejì, gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ará Íjíbítì lóríṣiríṣi sì bẹ̀rẹ̀ sí í kú,+ àmọ́ ìkankan nínú ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò kú.
-
-
Ẹ́kísódù 9:26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ilẹ̀ Góṣénì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nìkan ni yìnyín náà ò dé.+
-
-
Ẹ́kísódù 12:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ẹ̀jẹ̀ náà yóò jẹ́ àmì yín lára àwọn ilé tí ẹ wà; èmi yóò rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò sì ré yín kọjá, ìyọnu náà ò sì ní pa yín run nígbà tí mo bá kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+
-