6 Ṣùgbọ́n ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà ni kí o ti ṣe é. Kí o fi ẹran Ìrékọjá náà rúbọ ní ìrọ̀lẹ́, gbàrà tí oòrùn bá wọ̀,+ ní déédéé àkókò tí o jáde kúrò ní Íjíbítì. 7 Kí o sè é, kí o sì jẹ ẹ́+ ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn,+ kí o wá pa dà sí àgọ́ rẹ tí ilẹ̀ bá mọ́.