3 Mósè wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ máa rántí ọjọ́ yìí tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ ní ilé ẹrú, torí ọwọ́ agbára ni Jèhófà fi mú yín kúrò níbí.+ Torí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà.
3 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà pẹ̀lú rẹ̀;+ ọjọ́ méje ni kí o fi jẹ búrẹ́dì aláìwú, ó jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, torí pé ẹ kánjú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Máa ṣe èyí ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè kí o lè máa rántí ọjọ́ tí o kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
8 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe àjọyọ̀,+ kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú, àmọ́ ká ṣe é pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú ti òótọ́ inú àti ti òtítọ́.