2 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ lójú ìran ní òru, ó ní: “Jékọ́bù, Jékọ́bù!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí!” 3 Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run bàbá+ rẹ. Má bẹ̀rù láti lọ sí Íjíbítì, torí ibẹ̀ ni màá ti sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.+
17 Ọlọ́run àwọn èèyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba ńlá wa, ó gbé àwọn èèyàn náà ga nígbà tí wọ́n jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì fi ọwọ́ agbára* mú wọn jáde kúrò níbẹ̀.+