ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 16:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sọ fún wọn pé: “Jèhófà ì bá ti kúkú pa wá nílẹ̀ Íjíbítì nígbà tí a jókòó ti ìkòkò ẹran,+ tí à ń jẹun ní àjẹtẹ́rùn. Ẹ wá mú wa wá sínú aginjù yìí kí ebi lè pa gbogbo ìjọ yìí kú.”+

  • Ẹ́kísódù 17:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ àwọn èèyàn náà gan-an níbẹ̀, wọ́n sì ń kùn sí Mósè ṣáá,+ wọ́n ń sọ pé: “Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì kí o lè fi òùngbẹ pa àwa àti àwọn ọmọ wa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa?”

  • Nọ́ńbà 14:2-4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì,+ gbogbo àpéjọ náà sì ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wọn pé: “Ó sàn ká ti kú sí ilẹ̀ Íjíbítì tàbí ká tiẹ̀ ti kú sínú aginjù yìí! 3 Kí ló dé tí Jèhófà fẹ́ mú wa wá sí ilẹ̀ yìí kí wọ́n lè fi idà+ pa wá? Wọ́n á kó+ àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní dáa ká pa dà sí Íjíbítì?”+ 4 Wọ́n tiẹ̀ ń sọ fún ara wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká yan ẹnì kan ṣe olórí wa, ká sì pa dà sí Íjíbítì!”+

  • Sáàmù 106:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Àwọn baba ńlá wa ní Íjíbítì kò mọyì* àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.

      Wọn ò rántí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tó pọ̀ gidigidi,

      Wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ní òkun, létí Òkun Pupa.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́