11 Wọ́n sọ fún Mósè pé: “Ṣé torí kò sí ibi ìsìnkú ní Íjíbítì lo ṣe mú wa wá sínú aginjù ká lè kú síbí?+ Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì? 12 Ṣebí ohun tí a sọ fún ọ ní Íjíbítì ni pé, ‘Fi wá sílẹ̀, ká lè máa sin àwọn ará Íjíbítì’? Torí ó sàn ká máa sin àwọn ará Íjíbítì ju ká wá kú sí aginjù.”+