-
Ẹ́kísódù 15:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Alagbalúgbú omi bò wọ́n; wọ́n rì sí ìsàlẹ̀ ibú omi bí òkúta.+
-
-
Ẹ́kísódù 15:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 O fẹ́ èémí rẹ jáde, òkun sì bò wọ́n;+
Wọ́n rì sínú alagbalúgbú omi bí òjé.
-
-
Diutarónómì 11:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Wọn ò rí àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti àwọn ohun tó ṣe ní Íjíbítì sí Fáráò ọba Íjíbítì àti sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀;+ 4 bẹ́ẹ̀ ni wọn ò rí ohun tó ṣe sí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì, sí àwọn ẹṣin Fáráò àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, èyí tí omi Òkun Pupa bò mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń lé yín, tí Jèhófà sì pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.*+
-
-
Jóṣúà 24:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Nígbà tí mo mú àwọn bàbá yín kúrò ní Íjíbítì,+ tí ẹ sì dé òkun, àwọn ará Íjíbítì ń fi àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn agẹṣin lé àwọn bàbá yín títí dé Òkun Pupa.+ 7 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà,+ ó wá fi òkùnkùn sáàárín ẹ̀yin àti àwọn ará Íjíbítì, ó mú kí òkun ya wá sórí wọn, ó bò wọ́n mọ́lẹ̀,+ ẹ sì fi ojú ara yín rí ohun tí mo ṣe ní Íjíbítì.+ Ọ̀pọ̀ ọdún* lẹ fi wà ní aginjù.+
-
-
Nehemáyà 9:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 O wá ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu láti fìyà jẹ Fáráò àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ rẹ̀,+ torí o mọ̀ pé wọ́n ti kọjá àyè wọn+ sí àwọn èèyàn rẹ. O ṣe orúkọ fún ara rẹ, orúkọ náà sì wà títí dòní.+ 11 O pín òkun sí méjì níwájú wọn, kí wọ́n lè gba àárín òkun kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ,+ o fi àwọn tó ń lépa wọn sọ̀kò sínú ibú bí òkúta tí a jù sínú omi tó ń ru gùdù.+
-