21 Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun;+ Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn líle fẹ́ wá láti ìlà oòrùn ní gbogbo òru yẹn, ó sì bi òkun náà sẹ́yìn. Ó mú kí ìsàlẹ̀ òkun di ilẹ̀ gbígbẹ,+ omi náà sì pínyà.+
28 Omi náà rọ́ pa dà, ó sì bo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn agẹṣin àti gbogbo ọmọ ogun Fáráò tó lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú òkun.+ Kò sí ìkankan nínú wọn tó yè é.+