3 Torí náà, ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, ó jẹ́ kí ebi pa ọ́,+ ó sì fi mánà bọ́ ọ,+ oúnjẹ tí o kò mọ̀, tí àwọn bàbá rẹ ò sì mọ̀, kí o lè mọ̀ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.+
15 O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run nígbà tí ebi ń pa wọ́n,+ o fún wọn ní omi látinú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n,+ o sì ní kí wọ́n wọ ilẹ̀ tí o búra* pé wàá fún wọn, kí wọ́n sì gbà á.