-
Diutarónómì 27:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Kí ẹ tún mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, òkúta ni kí ẹ fi mọ ọ́n. Ẹ má fi irin gbẹ́ ẹ.+
-
-
Jóṣúà 8:30, 31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Ìgbà yẹn ni Jóṣúà mọ pẹpẹ kan sí Òkè Ébálì+ fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, 31 bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bó sì ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Òfin+ Mósè pé kó jẹ́: “Pẹpẹ tí wọ́n fi àwọn odindi òkúta ṣe, tí wọn ò fi irinṣẹ́ èyíkéyìí gbẹ́.”+ Wọ́n rú àwọn ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lórí rẹ̀ sí Jèhófà.+
-