25 Lónìí yìí, màá mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo èèyàn tó wà lábẹ́ ọ̀run tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn nípa yín. Ọkàn wọn kò ní balẹ̀, jìnnìjìnnì á sì bò wọ́n* torí yín.’+
9 Ó sì sọ fún wọn pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà máa fún yín ní ilẹ̀ yìí+ àti pé ẹ̀rù yín ti ń bà wá.+ Ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí sì ti domi nítorí yín,+